إِنَّآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ لِلنَّاسِ بِٱلۡحَقِّۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٍ 41
Dajudaju Awa ni a sọkalẹ fun ọ - irẹ ojisẹ - Alukuraani fun awọn eniyan pẹlu ododo ki o le maa se ikilọ fun wọn, ẹniti o ba mọ ọna, dajudaju anfaani imọna rẹ nbẹ fun, imọna rẹ ko le se Allah ni anfaani; nitori O rọrọ kuro nibẹ, ẹniti o ba sọnu dajudaju inira isọnu rẹ nbẹ fun, isina rẹ ko le ko inira ba Allah ti mimọ nbẹ fun, iwọ ko la bọrun lati jẹ wọn nipa lori imọna, ko si nkankan lori rẹ ju fifi to wọn leti ohun ti wọn pa ọ lasẹ wipe ki o mu de ogongo rẹ lọ.
ٱللَّهُ يَتَوَفَّى ٱلۡأَنفُسَ حِينَ مَوۡتِهَا وَٱلَّتِي لَمۡ تَمُتۡ فِي مَنَامِهَاۖ فَيُمۡسِكُ ٱلَّتِي قَضَىٰ عَلَيۡهَا ٱلۡمَوۡتَ وَيُرۡسِلُ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمًّىۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 42
Allah eyiti o gba awọn ẹmin nigbati asiko rẹ ba tan, o si ngba awọn ẹmin ti asiko rẹ ko tii tan nigba oorun, yoo si mu duro eyiti o ti dajọ iku le lori, yoo si tu silẹ eyiti ko dajọ rẹ le lori titi di asiko ti o ni aala ninu imọ rẹ ti mimọ nbẹ fun, dajudaju nibi gbigba mu ati titu u silẹ ati pipa a ati tita a ji jẹ awọn ẹri fun ijọ ti o nronu lori ẹniti o se eleyi wipe alagbara lati ta ọmọniyan ji lẹyin iku wọn fun isiro ati ẹsan nii se.
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُفَعَآءَۚ قُلۡ أَوَلَوۡ كَانُواْ لَا يَمۡلِكُونَ شَيۡٔٗا وَلَا يَعۡقِلُونَ 43
Paapaa awọn ẹlẹbọ ti mu awọn olusepẹ ninu awọn oosa wọn ti wọn nrankan anfaani lọdọ wọn yatọ si Allah sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: se ẹ mu wọn ni olusipẹ koda bi wọn ko nikapa rẹ fun yin, ti wọn ko si ni nkankan fun ẹmin ara wọn, ti wọn ko si le se laakaye; wọn jẹ ọbọrọgidi aditi ti ko le sọrọ, ti ko si le gbọ, ti ko si le ri, ti ko le se anfaani, ti ko si le mu inira wa?!
قُل لِّلَّهِ ٱلشَّفَٰعَةُ جَمِيعٗاۖ لَّهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 44
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi: ti Allah nikan soso ni ipẹ lapapọ, ẹnikankan ko le sipẹ lọdọ Rẹ ayaafi pẹlu iyọnda Rẹ, ko si le sipẹ ayaafi ẹniti o ba yọnu si, tirẹ nikan ni ikapa gbogbo sanmọ ati ikapa ilẹ, lẹyin naa ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o sẹri si ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan, yoo wa san yin lẹsan lori awọn isẹ yin.
وَإِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُ ٱشۡمَأَزَّتۡ قُلُوبُ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِۖ وَإِذَا ذُكِرَ ٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦٓ إِذَا هُمۡ يَسۡتَبۡشِرُونَ 45
Ti wọn ba darukọ Alllah nikan soso, ẹmin awọn ẹlẹbọ yoo salọ, awọn ti ko nigbagbọ nipa ọrun ati igbedide, isiro ati ẹsan ti o wa nibẹ, sugbọn ti wọn ba darukọ awọn oosa ti wọn nsin yatọ si Allah, nigbanaa wọn yoo jẹ idunnu alayọ.
قُلِ ٱللَّهُمَّ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ عَٰلِمَ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ أَنتَ تَحۡكُمُ بَيۡنَ عِبَادِكَ فِي مَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ 46
Sọ - irẹ ojisẹ -: iwọ Ọlọhun Asẹd agbogbo sanmọ ati ilẹ laisi apejuwe kan siwaju, onimimọ nipa ohun ti o pamọ ati ohun ti o wa, nkankan ko pamọ fun ọ ninu eleyi, Iwọ nikan ni O si se alaye ohun ti wọn nse iyapa si ni ile aye laarin awọn ẹru Rẹ ni ọjọ igbende, olododo yoo wa han bẹẹni onibajẹ ati oloriire ati olori buruku.
وَلَوۡ أَنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا وَمِثۡلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفۡتَدَوۡاْ بِهِۦ مِن سُوٓءِ ٱلۡعَذَابِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَبَدَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مَا لَمۡ يَكُونُواْ يَحۡتَسِبُونَ 47
Ti o ba jasipe gbogbo ohun ti o wa ninu ilẹ ninu awọn ohun ti o niye lori ati awọn dukia jẹ ti awọn ti o swe abosi ẹmin ara wọn pẹlu ẹbọ sise ati awọn ẹsẹ; wọn ko ba fi di iya ti o le koko eyiti wọn nri lẹyin igbende wọn, sugbọn kii se ti wọn, ti a ba ka a kun ti wọn, wọn ko nii gba a lọwọ wọn, awọn oniranran iya yoo tun fojuhan si wọn lọdọ Allah eyiti wọn ko rankan rẹ.
Oorun ati itaji jẹ ẹkọ ojumọ meji lati se alaye iku ati igbende.
Ti wọn ba darukọ Allah nikan soso lọdọ awọn keferi, ifulẹmọ ati ibanujẹ yoo ba wọn; nitoripe wọn yoo ma ranti ohun ti wọn pa wọn lasẹ ati ohun ti wọn kọ fun wọn, ti wọn si waa jẹ olubori kuro nibẹ patapata.
Keferi yoo ma rankan fifi ẹmin ararẹ di gbogbo ohun ti o nikapa ni ọjọ igbende, ti o si se ahun pẹlu rẹ ni ile aye, bẹẹni wọn ko nii gba a lọwọ rẹ.