وَءَايَةٞ لَّهُمۡ أَنَّا حَمَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ 41
O tun jẹ amin fun wọn lori ijọkan soso Allah ati idẹkun Rẹ lori awọn ẹru Rẹ, awa ni a gbe ẹniti o la ninu okun tuufaanu ninu awọn arọmọdọmọ Adamọ ni asiko Nuha si inu ọkọ oju omin ti o kun fun awọn ẹda Allah, paapaa Allah gbe gbogbo iran lakọ labo si inu rẹ.
وَخَلَقۡنَا لَهُم مِّن مِّثۡلِهِۦ مَا يَرۡكَبُونَ 42
O tun jẹ amin fun wọn lori ijọkan soso Rẹ ati isedẹkun Rẹ lori awọn ẹru Rẹ lori wipe awa ni a da iru apejuwe ọkọ oju omin Nuha ni nkan igun fun wọn.
وَإِن نَّشَأۡ نُغۡرِقۡهُمۡ فَلَا صَرِيخَ لَهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنقَذُونَ 43
Ti a ba gbero lati tẹ wọn ri, a ko ba tẹ wọn ri, ko si oluranlọwọ kan ti yoo ran wọn lọwọ ti a ba gbero itẹri fun wọn, oluyọni kankan ko le yọ wọn ti wọn ba tẹri lati ibi asẹ Wa ati akọsilẹ Wa.
إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ 44
Ayaafi ki a kẹ wọn pẹlu lila wọn kuro nibi itẹri naa, ki a si sẹri wọn sibi ki wọn gbadun titi di asiko ti o ni aala, ti wọn ko nii kọja ẹnu aala rẹ, o seese fun wọn ki wọn woye, ki wọn si nigbagbọ.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُواْ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيكُمۡ وَمَا خَلۡفَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 45
Ti wọn ba sọ fun awọn ẹlẹbọ olugunri yii kuro nibi igbagbọ: ẹ sọra fun ohun ti ẹ nti siwaju nitori ọrọ ọrun ati ilekoko bẹ, ki ẹ si sọra fun aye eyiti o ma npada ni irankan ki Allah le se idẹkun Rẹ le yin lori; sugbọn wọn mu eleyi sẹ bikosepe wọn gunri kuro nibẹ laibikita pẹlu rẹ.
وَمَا تَأۡتِيهِم مِّنۡ ءَايَةٖ مِّنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِمۡ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ 46
Gbogbo igbati amin Allah ba de waa ba awọn ẹlẹbọ olorikunkun yii eyiti o ntọka si ọkansoso rẹ ati ohun ti o fi lẹtọ si mimu laaso nibi ijọsin, wọn yoo gunri kuro nibẹ, ti wọn ko nii ka a kun.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ أَنفِقُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنُطۡعِمُ مَن لَّوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ أَطۡعَمَهُۥٓ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 47
Ti wọn ba sọ fun awọn olugunri yii wipe: ẹ se iranlọwọ fun awọn olosi ati alaini ninu dukia eyiti Allah rọ yin lọrọ rẹ, wọn yoo fesi pada niti itako ni ẹniti o nsọ fun awọn olugbagbọ ododo: se a o maa fun ni ounjẹ ẹniti o ja si wipe ti Allah ba fẹ fun ni ounjẹ Yoo fun ni ounjẹ?! Awa ko nii yapa ohun ti O fẹ, ẹyin ko jẹ nkankan - ẹyin olugbagbọ ododo - ayaafi ibi asise ti o fi oju han ati ijina si ododo ni ẹ wa.
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 48
Awọn keferi ti wọn taku igbedide yoo maa sọrọ, ti wọn si pe e nirọ, ti wọn mu ni ohun ti ko le see se: igba wo ni igbende yii yoo jẹ ti ẹ ba jẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - sootọ sootọ nibi ohun ti ẹ npe apemọra wipe yoo sẹlẹ?!
مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ تَأۡخُذُهُمۡ وَهُمۡ يَخِصِّمُونَ 49
Awọn olupe ọjọ igbende nirọ yii, ti wọn mi ni ohun ti ko le see se, ko reti nkankan ju fere alakọkọ lọ nigbati wọn fan an si inu iwo, igbe yii yoo ba wọn lojiji nigbati wọn ba wa ni airoju ile aye gẹgẹ bi tita rira, fifu lomin, dida ẹran ati nkan miran ninu awọn airoju ile aye.
فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ تَوۡصِيَةٗ وَلَآ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ يَرۡجِعُونَ 50
Wọn ko nii lagbara lati sọ asọtẹlẹ apakan wọn fun apakan nigbati igbe yii ba ba wọn lojiji, wọn ko si nii lagbara lati sẹri lọ si inu ile wọn ati awọn ara ile wọn bikosepe wọn yoo maa ku nibi ti wọn ti nko airoju yii.
وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يَنسِلُونَ 51
Wọn tun fan fere si inu iwo ni fere ẹlẹẹkeji fun ajinde, lojiji ni wọn yoo maa jade lapapọ kuro ninu awọn saare wọn lọsi ọdọ Ọlọhun wọn, wọn yoo yara gaga fun isiro ati ẹsan.
قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا مَنۢ بَعَثَنَا مِن مَّرۡقَدِنَاۜۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَصَدَقَ ٱلۡمُرۡسَلُونَ 52
Awọn keferi olupe igbende nirọ yii yoo maa sọ niti olukabamọ: irẹ ofo wa o, taani o gbe wa dide ninu awọn saare wa?! Wọn yoo maa dahun ibeere wọn: eleyi ni Allah se ni adehun dajudaju ko si iyemeji yoo sẹlẹ, awọn ojisẹ si sọ ododo ni ohun ti wọn mu de opin lati ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ninu eleyi.
إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ 53
Ọrọ ijinde lati inu saare ko jẹ nkankan ayaafi oripa kan nipa fere ẹlẹẹkeji si inu iwo lojiji ni gbogbo awọn ẹda yoo peju ni ọdọ Wa fun isiro.
فَٱلۡيَوۡمَ لَا تُظۡلَمُ نَفۡسٞ شَيۡٔٗا وَلَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 54
Idajọ yoo jẹ deede ni ọjọ yii, wọn ko se abosi -ẹyin ẹrusin- kankan pẹlu sise alekun asise yin tabi didin awọn daadaa yin ku bikosepe wọn yoo pe ẹsan ohun ti ẹ se ni isẹmin aye.
Ninu awọn ojupọnna ti Allah ma nfi se ireni fun awọn ẹru Rẹ ni ki o fi awọn aayah eyiti o ntọka lori ohun ti o le se wọn lanfaani ninu ẹsin wọn tabi ile aye wọn si iwaju wọn.
Allah ti O ga gba awọn ẹru Rẹ laaye, o si fun wọn ni agbara eyiti wọn le fi se ohun ti O pa wọn lasẹ ati ijinna si ohun ti o kọ, ti wọn ba wa gbe ohun ti o pa wọn lasẹ ju silẹ eleyi jẹ ẹsa lati ọdọ wọn ni.