إِنَّ يَوۡمَ ٱلۡفَصۡلِ مِيقَٰتُهُمۡ أَجۡمَعِينَ 40
Dajudaju ọjọ igbende ti Allah yoo se atunse laarin awọn ẹru jẹ adehun fun awọn ẹda Rẹ lapapọ, ti Allah yoo ko wọn jọ nibẹ.
يَوۡمَ لَا يُغۡنِي مَوۡلًى عَن مَّوۡلٗى شَيۡٔٗا وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ 41
Ọjọ ti alasunmọ ko nii se anfaani fun alasunmọ rẹ, bẹẹni ọrẹ ko nii se anfaani fun ọrẹ rẹ, bẹẹni wọn ko nii kọ di wọn kuro nibi iya Allah; nitoripe dajudaju ọla yoo jẹ ti Allah ni ọjọ naa, ko si ẹnikankan ti o le pe apemọra rẹ.
إِلَّا مَن رَّحِمَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 42
Ayaafi ẹniti Allah ba kẹ ninu awọn eniyan toripe oun ni yoo se anfaani pẹlu ohun ti o ti siwaju ninu isẹ rere, dajudaju Allah ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, Onikẹ fun ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ.
Nigbati Allah sọ igbende, O tun sọ onipnya awọn eniyan nibẹ ni ibamun si ẹsan, O wa sọpe:
إِنَّ شَجَرَتَ ٱلزَّقُّومِ 43
Dajudaju igi sakuumu eyiti Allah mu hun ni isalẹ ina jahiimu.
طَعَامُ ٱلۡأَثِيمِ 44
Ounjẹ awọn ẹlẹsẹ ti o tobi, ẹni naa ni keferi ti yoo maa jẹ ninu eso ibajẹ rẹ.
كَٱلۡمُهۡلِ يَغۡلِي فِي ٱلۡبُطُونِ 45
Eso yii da gẹgẹ bi ororo dudu, yoo maa ho ni inu wọn nitori lilekoko igbona rẹ.
كَغَلۡيِ ٱلۡحَمِيمِ 46
Gẹgẹ bi omin ti o ho tan yan an yan se ma ngbona.
خُذُوهُ فَٱعۡتِلُوهُ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ 47
Wọn yoo maa sọ fun awọn alamojuto ina: ẹ gba mu, ẹ si wọ pẹlu inira ati ilekoko lọ si aarin ina jahimu.
ثُمَّ صُبُّواْ فَوۡقَ رَأۡسِهِۦ مِنۡ عَذَابِ ٱلۡحَمِيمِ 48
Lẹyin naa, ẹ da onim gbigbona si oke ori ẹni iya yii, ki iya ma fi silẹ rara.
ذُقۡ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡكَرِيمُ 49
Wọn yoo maa sọ fun niti yẹyẹ: maa tọ iya inira yii wo; dajudaju iwọ ni alagbara eyiti ẹnikankan ko le bori abala apọnle Rẹ ninu awọn ijọ rẹ.
إِنَّ هَٰذَا مَا كُنتُم بِهِۦ تَمۡتَرُونَ 50
Dajudaju iya yii ni ẹ ke gbajari sisẹlẹ rẹ ni ọjọ igbende, paapaa riri rẹ ti mu iyemeji kuro fun yin.
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي مَقَامٍ أَمِينٖ 51
Dajudaju awọn ti wọn npaya Ọlọhun wọn lati ibi mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ yoo wa ni aaye ifọkanbọlẹ kuro nibi ohun ti ọkan kọ ti o le sẹlẹ si wọn.
فِي جَنَّٰتٖ وَعُيُونٖ 52
Ninu awọn ọgba ati odo ti nsan.
يَلۡبَسُونَ مِن سُندُسٖ وَإِسۡتَبۡرَقٖ مُّتَقَٰبِلِينَ 53
Wọn yoo maa wọ asọ alaran ti o nipọn, ti o wẹ ni ọgba idẹra naa, ti apakan yoo maa kọju si apakan, ẹnikan wọn ko nii wo ipakọ ẹlomiran.
كَذَٰلِكَ وَزَوَّجۡنَٰهُم بِحُورٍ عِينٖ 54
Gẹgẹ bi a se pọn wọn le pẹlu awọn ohun ti a sọ yii, a o tun fẹ awọn obinrin ti o dara, ti oju wọn gbaaye pẹlu fifunfun ti gboo rẹ ati didudu kirikiri rẹ fun wọn ninu ọgba idẹra naa.
يَدۡعُونَ فِيهَا بِكُلِّ فَٰكِهَةٍ ءَامِنِينَ 55
Wọn yoo maa pe awọn olusisẹ si wọn nibẹ ki o le mu gbogbo ipapanu ti wọn ba nfẹ wa fun wọn ni ẹniti yoo fi ọkan balẹ nibi jija rẹ ati inira rẹ.
لَا يَذُوقُونَ فِيهَا ٱلۡمَوۡتَ إِلَّا ٱلۡمَوۡتَةَ ٱلۡأُولَىٰۖ وَوَقَىٰهُمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ 56
Wọn yoo maa wa nibẹ gbere, wọn ko nii tọ iku wo nibẹ ayaafi iku alakọkọ ni isẹmin aye, Ọlọhun wọn yoo si tun la wọn kuro nibi iya ina.
فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكَۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 57
Niti sise ọla ati daadaa sise lati ọdọ Ọlọhun rẹ si wọn, eleyi ti a sọ yii - nipa mimu wọn wọ ọgba idẹra naa ati lila wọn kuro nibi ina - jẹ erenjẹ ti o tobi eyiti erenjẹ kankan ko sun mọ.
فَإِنَّمَا يَسَّرۡنَٰهُ بِلِسَانِكَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ 58
Dajudaju a rọ Alukuraani yii, a si se sisọkalẹ rẹ nirọrun pẹlu ede rẹ tii se larubawa - irẹ ojisẹ - ki wọn le gba isiti.
فَٱرۡتَقِبۡ إِنَّهُم مُّرۡتَقِبُونَ 59
Ki o maa reti aransẹ rẹ ati iparun wọn, dajudaju wọn nreti iparun rẹ.
Pipa iya ara ati ẹmin pọ fun keferi.
Erenjẹ ti o tobi ju ni lila kuro nibi ina ati wiwọ ọgba idẹra naa.
Rirọ ti allah rọ gbolohun Alukuraani ati awọn itumọ rẹ fun awọn ẹru Rẹ.