وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا ثُمَّ يَقُولُ لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ أَهَٰٓؤُلَآءِ إِيَّاكُمۡ كَانُواْ يَعۡبُدُونَ 40
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ọjọ Allah yoo kọ wọn jẹ lapapọ, lẹyin naa Oun ti mimọ nbẹ yoo sọ fun awọn Malaika niti idẹruba fun awọn ẹlẹbọ ati eebu fun wọn: se awọn wọnyi ni wọn nsin yin ni isẹmin aye yatọ si Allah?
قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ أَنتَ وَلِيُّنَا مِن دُونِهِمۖ بَلۡ كَانُواْ يَعۡبُدُونَ ٱلۡجِنَّۖ أَكۡثَرُهُم بِهِم مُّؤۡمِنُونَ 41
Awọn Malaika yoo sọpe: mimọ kanga Rẹ ati sise afọmọ Rẹ! Iwọ ni alatilẹyin wa yatọ si wọn, ko si alafẹyinti kankan laarin wa ati wọn, bikosepe awọn ẹlẹbọ yii nsin awọn esu; wọn nse afihan fun wọn wipe Malaika ni awọn, bayi ni wọn se nsin wọn yatọ si Allah, bẹẹni ọpọ wọn ni o jẹ olugbagbọ si wọn.
فَٱلۡيَوۡمَ لَا يَمۡلِكُ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٖ نَّفۡعٗا وَلَا ضَرّٗا وَنَقُولُ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّتِي كُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ 42
Ọjọ akojọ ati isiro, awọn ti wọn nsin ko nikapa anfaani kankan fun ẹniti o nsin wọn ni ile aye yatọ si Allah, bẹẹni wọn ko nikapa inira fun wọn, wọn yoo wa maa sọ fun awọn ti o se abosi ẹmin ara wọn lati ibi sise keferi ati awọn ẹsẹ: ẹ maa tọ iya ina eyiti ẹ npe nirọ ni ile aye wo.
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّا رَجُلٞ يُرِيدُ أَن يَصُدَّكُمۡ عَمَّا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُكُمۡ وَقَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّآ إِفۡكٞ مُّفۡتَرٗىۚ وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ 43
Ti o ba nka awọn aayah Wa ti A sọkalẹ fun ojisẹ Wa ni ohun ti o fi oju han, ti ko si iruju nibẹ fun awọn ẹlẹbọ opurọ wọnyi, wọn yoo sọpe: taani arakunrin ti o mu eleyi wa bikosepe arakunrin ti o gbero lati yi yin kuro nibi ohun ti awọn baba yin wa lọ, wọn wa sọpe: Alukuraani ko jẹ nkankan ju irọ ti wọn hun jọ mọ Allah lọ, awọn ti o se keferi si Allah nigbati Alukuraani de wa ba wọn lati ọdọ Allah yoo sọ fun Alukuraani: eleyi ko jẹ nkankan ju idan ti o hande lọ; ki o le fi se onpinya laarin ọmọniyan ati iyawo rẹ ati ọmọ ati baba rẹ.
وَمَآ ءَاتَيۡنَٰهُم مِّن كُتُبٖ يَدۡرُسُونَهَاۖ وَمَآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمۡ قَبۡلَكَ مِن نَّذِيرٖ 44
A ko fun wọn ni awọn iwe ti wọn nka ti yoo fi wa tọka fun wọn wipe Alukuraani yii jẹ irọ ti Muhammad hun, bẹẹni a ko ransẹ si siwaju ki a to ran ọ nisẹ - irẹ ojisẹ - ninu ojisẹ kankan ti yoo ma daẹru ba wọn kuro nibi iya Allah.
وَكَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ وَمَا بَلَغُواْ مِعۡشَارَ مَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ فَكَذَّبُواْ رُسُلِيۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ 45
Wọn pe awọn ijọ ti o siwaju nirọ gẹgẹ bi hadi, samuudu ati ijọ luuth, bẹẹni awọn ẹlẹbọ inu ijọ rẹ ko to idakan idamẹwa ohun ti awọn ijọ ti o ti siwaju to ninu agbara ati idaabobo ati dukia ati onka, gbogbo wọn ni wọn pe ojisẹ Rẹ nirọ, dukia ti wọn fun wọn ati agbara ati onka ko se wọn lanfaani, iya Mi si sẹlẹ si wọn, ki o woye - irẹ ojisẹ - bi ikorira wọn Mi se ri ati bi iya Mi se ri fun wọn.
۞قُلۡ إِنَّمَآ أَعِظُكُم بِوَٰحِدَةٍۖ أَن تَقُومُواْ لِلَّهِ مَثۡنَىٰ وَفُرَٰدَىٰ ثُمَّ تَتَفَكَّرُواْۚ مَا بِصَاحِبِكُم مِّن جِنَّةٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا نَذِيرٞ لَّكُم بَيۡنَ يَدَيۡ عَذَابٖ شَدِيدٖ 46
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi, dajudaju mo ntọka fun yin, mo si nse isiti fun yin lori ẹwa kan soso; ohun ki ẹ bọpa bọsẹ kuro nibi ifẹ inu fun Allah ti mimọ nbẹ fun ni meji meji tabi ni ẹyọ ẹyọ, lẹyin ki ẹ ronu si itan ẹni yin ati ohun ti ẹ ma nipa laakaye rẹ ati ododo rẹ ati ifọkantan rẹ; ki ẹ le mọ amọdaju wipe oun ti ikẹ ati ọla nbẹ fun kii se were, ko jẹ nkankan ayaafi olusekilẹ fun yin nibi iya ti o le koko, ti ẹ ko ba ronu piwada lọsi ọdọ Allah kuro nibi sise ẹbọ pẹlu.
قُلۡ مَا سَأَلۡتُكُم مِّنۡ أَجۡرٖ فَهُوَ لَكُمۡۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٞ 47
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ opurọ yii: nko beere ẹsan tabi owo ọya lori imọna ti ẹ mu wa ati rere - lori sise odiwọn ati ọrẹnta Rẹ -, o wa fun yin ni, ẹsan mi ko si lọdọ ẹnikẹni ayaafi Allah nikan soso, Oun ti mimọ nbẹ fun si jẹ ẹlẹri lori gbogbo nkan, Oun ni yoo jẹri lori wipe mo mu detigbọ yin, yoo si jẹri lori isẹ yin, yoo si san yin lẹsan rẹ.
Nigbati Oun ti mimọ nbẹ fun salaye awọn awijare lori awọn ẹni ibajẹ ati ẹbọ, o tun salaye wipe eleyi jẹ isesi Rẹ, O wa sọpe:
قُلۡ إِنَّ رَبِّي يَقۡذِفُ بِٱلۡحَقِّ عَلَّٰمُ ٱلۡغُيُوبِ 48
Sọ - irẹ ojisẹ -: dajudaju Ọlọhun Ọba mi yoo fi ododo jẹ gaba lori ibajẹ, yoo si ba a jẹ, Oun ni olumọ kọkọ, nkankan ko pamọ fun Un ni sanmọ, bẹẹni ni ilẹ, bẹẹni awọn isẹ ẹru Rẹ ko si pamọ fun Un.
Ikọse afọju fun awọn baba ma nyini kuro ni ọnaamọ.
Rironu pẹlu bibọpa bọsẹ kuro nibi ifẹẹnu jẹ itẹgun lati le de ibi ipinnu ti o lalaafia ati ironu ti o dọgba.
Ẹniti o npepe si ọdọ Allah kii reti ẹsan ni ọdọ eniyan bikosepe yoo maa reti rẹ ni ọdọ Ọlọhun awọn eniyan.