لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ ٱلسَّحَرَةَ إِن كَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ 40
Ti ireti ki a maa ba tẹle onidan nibi ẹsin wọn ti ibori ba jẹ ti wọn lori Musa.
فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالُواْ لِفِرۡعَوۡنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجۡرًا إِن كُنَّا نَحۡنُ ٱلۡغَٰلِبِينَ 41
Nigbati awọn onidan de ọdọ fir'aona lati bori Musa, wọn sọ fun wipe: njẹ ẹsan ifojuri ati aifojuri nbẹ fun wa ti ibori ba jẹ ti wa lori Musa?
قَالَ نَعَمۡ وَإِنَّكُمۡ إِذٗا لَّمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ 42
Fir'aona sọ fun wọn: bẹẹ ni ẹsan bẹ fun yin; bakanna dajudaju nigbati ẹ ba bori rẹ, ẹ o pada jẹ ẹni asunmọ ni ọdọ mi pẹlu fifun yin ni awọn ipo ti o ga.
قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلۡقُواْ مَآ أَنتُم مُّلۡقُونَ 43
Musa sọ fun wọn ni ẹniti o gbe ẹmin le aranse Allah, o si tun salaye wipe dajudaju ohun ti o bẹ ni ọdọ rẹ kii se idan: ẹ ju nkan ti ẹ fẹẹ ju silẹ ninu okun yin ati ọpa yin.
فَأَلۡقَوۡاْ حِبَالَهُمۡ وَعِصِيَّهُمۡ وَقَالُواْ بِعِزَّةِ فِرۡعَوۡنَ إِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡغَٰلِبُونَ 44
Wọn si ju okun wọn ati ọpa wọn; wọn si sọ njgbati wọn juu silẹ: pẹlu titobi fir'aona dajudaju awa ni olubori, bẹẹ ni Musa ni ẹniti a o bori.
فَأَلۡقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلۡقَفُ مَا يَأۡفِكُونَ 45
Musa waa ju ọpa rẹ, o si yi pada di ejo, lojiji ni o mion ohun ti wọn nse idandan rẹ fun awọn neniyan ni idan.
فَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سَٰجِدِينَ 46
Nigbati awọn pidan pidan ri ọpa Musa ti o min ohun ti wọn ju silẹ ninu idan wọn, wọn subu lulẹ ni ẹniti o fi ori kanlẹ.
قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 47
Wọn sọ wipe: a nigbagbọ si Ọlọhun Ọba gbogbo ẹda lapapọ.
رَبِّ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ 48
Ọlọhun Musa ati Ọlọhun Haruna ẹniti ọla nbẹ fun.
قَالَ ءَامَنتُمۡ لَهُۥ قَبۡلَ أَنۡ ءَاذَنَ لَكُمۡۖ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِي عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحۡرَ فَلَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَۚ لَأُقَطِّعَنَّ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَرۡجُلَكُم مِّنۡ خِلَٰفٖ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمۡ أَجۡمَعِينَ 49
Fir'aona sọ ni ẹniti ntako igbagbọ awọn onidan: se ẹ nigbagbọ si Musa siwaju ki emi to yọnda fun yin lori rẹ ni?! Dajudaju Musa jẹ agbalagba inu yin ti o kọ yin ni idan, paapaa ẹ si ti jọ gbimọran lapapọ lati mu awọn ara misirọ kuro nibẹ, ẹ o si pada mọ ohun ti o mu yin ko si ninu iya, bẹẹ ni paapaa maa ma ge ẹsẹ ẹni kọọkan yin ati ọwọ rẹ ni ohun ti yoo yapa si ara wọn pẹlu gige ẹsẹ ọtun pẹlu ọwọ osi, tabi idakeji rẹ, bẹẹ ni paapaa maa maa kan yin lapapọ mọ igi ọpẹ ti emi ko si nii sẹ ẹnikankan ku ninu yin.
قَالُواْ لَا ضَيۡرَۖ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ 50
Awọn pidanpidan sọ fun fir'aona: ko si inira kankan ninu ohun ti o fi nda ẹru ba wa nibi gige tabi kikanni mọ igi ni ile aye, iya rẹ yoo yẹ kuro, awa yoo si sẹri si ọdọ Ọlọhun Ọba wa, bẹẹni Yoo si fi wa wọ inu ikẹ Rẹ lailai.
إِنَّا نَطۡمَعُ أَن يَغۡفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَٰيَٰنَآ أَن كُنَّآ أَوَّلَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 51
Dajudaju awa nrankan ki Allah pa awọn asise wa ti a se siwaju rẹ, eyiti a gunle nirori wipe a jẹ ọkan ninu ẹniti o kọkọ gba Musa gbọ, ti o si gba lododo.
۞وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَسۡرِ بِعِبَادِيٓ إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ 52
A si ransẹ si Musa ni ẹniti o npaa lasẹ ki o mu awọn ọmọ isirẹli rin irin oru, dajudaju fir'aona awọn ti o wa pẹlu rẹ jẹ ẹniti o ntẹẹle wọn lati sẹ wọn lori.
فَأَرۡسَلَ فِرۡعَوۡنُ فِي ٱلۡمَدَآئِنِ حَٰشِرِينَ 53
Fir'aona gbe apakan awọn ọmọ ogun rẹ dide si inu ilu ni ẹniti o nkojọ, ti wọn si nko awọn ọmọ ogun jọ lati sẹ awọn ọmọ isirẹla lori nigbati o mọ irin wọn lati misirọ.
إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَشِرۡذِمَةٞ قَلِيلُونَ 54
Fir'aona sọ ni ẹniti o nkere isesi awọn ọmọ isirẹli: dajudaju awọn wọnyi jẹ ijọ kekere.
وَإِنَّهُمۡ لَنَا لَغَآئِظُونَ 55
Bẹẹni dajudaju wọn yoo se ohun ti yoo bi wa ninu si wọn.
وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَٰذِرُونَ 56
Bẹẹni dajudaju awa jẹ ẹniti o mu ra silẹ de wọn ni ojukoroju.
فَأَخۡرَجۡنَٰهُم مِّن جَنَّٰتٖ وَعُيُونٖ 57
A mu fir'aona ati awọn ọmọ ogun rẹ jade kuro ni ilẹ misirọ, ti o ni awọn ọgba ti o nkọrin ati awọn isẹlẹru ti omin nsan nibẹ.
وَكُنُوزٖ وَمَقَامٖ كَرِيمٖ 58
Ati eyiti o ni awọn pẹpẹ ọrọ dukia ati ibugbe ti o dara.
كَذَٰلِكَۖ وَأَوۡرَثۡنَٰهَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 59
Gẹgẹ bi a se tun mu fir'aona ati awọn ọmọ ijọ rẹ jade kuro ninu idẹkun yii, a sọ iran idẹkun yii di ti awọn ọmọ isirẹli ni ilu saamu lẹyin ti wọn.
فَأَتۡبَعُوهُم مُّشۡرِقِينَ 60
Fir'aona ati awọn ijọ rẹ nlọ ni ibi oripa awọn ọmọ isirẹli ni asiko yiyọ oorun.
Isepọ ti nbẹ laarin onibajẹ ohun ni awọn anfaani ifojuri.
Igbẹkẹle Musa ninu aranse lori awọn pidan pidan jẹ gbigbe adehun Ọlọhun Ọba rẹ lododo.
Igbagbọ awọn pidan pidan jẹ awijare lori wipe dajudaju Ọlọhun Ọba ni Oluyi awọn ọkan pada si bi o ba ti wu U.
Ikọja ẹnu aala ati abosi jẹ awọn okunfa yiyẹ ọla.