ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ شَآقُّواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۖ وَمَن يُشَآقِّ ٱللَّهَ فَإِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ 4
Eyiti o sẹlẹ si wọn yii sẹlẹ nitoripe wọn nba Allah sọta, wọn si nba ojisẹ Rẹ naa sọta lati ibi keferi wọn ati jija adehun wọn, ẹniti o ba si ba Allah se ọta, dajudaju Allah jẹ oniya lile, iya lile Rẹ yoo si to o lọwọ.
مَا قَطَعۡتُم مِّن لِّينَةٍ أَوۡ تَرَكۡتُمُوهَا قَآئِمَةً عَلَىٰٓ أُصُولِهَا فَبِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَلِيُخۡزِيَ ٱلۡفَٰسِقِينَ 5
Ohun ti ẹ ba ge - ẹyin awujọ olugbagbọ ododo - ninu ọpẹ lati mu awọn ọta Allah binu nibi ogun awọn arọmọdọmọ nadiiru tabi ẹ ba gbe e ju silẹ, yoo maa wa lori egbo rẹ, ki ẹle se anfaani pẹlu rẹ- o wa pẹlu asẹ Allah, ko si ninu ibajẹ lorilẹ gẹgẹ bi wọn se pinnu ati ki Allah le mu iyẹpẹrẹ ba ẹniti o jade kuro nibi itẹle tiRẹ ninu awọn yahuudi ti wọn ja adehun, ti wọn si sa oju ọna ijanba ni aayo lori ọna adehun pipe.
وَمَآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ مِنۡهُمۡ فَمَآ أَوۡجَفۡتُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ خَيۡلٖ وَلَا رِكَابٖ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يُسَلِّطُ رُسُلَهُۥ عَلَىٰ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 6
Eyiti Allah ba da bada fun ojisẹ Rẹ ninu awọn dukia arọmọdọmọ nadiiru, eyiti ẹ ba nyara nibi wiwa a ninu awọn ohun ti ẹ ngun gẹgẹ bi ẹsin tabi rakunmi, ti idaamun ko si ma sẹlẹ si yin nibẹ sugbọn dajudaju Allah ma nfi awọn ojisẹ Rẹ jẹ gaba lori awọn ẹniti o ba wu U, paapaa O si ti fi ojisẹ Rẹ jẹ gaba lori arọmọdọmọ nadiiru, O si ilu wọn laisi ipaniyan, Allah jẹ alagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A.
مَّآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡقُرَىٰ فَلِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ كَيۡ لَا يَكُونَ دُولَةَۢ بَيۡنَ ٱلۡأَغۡنِيَآءِ مِنكُمۡۚ وَمَآ ءَاتَىٰكُمُ ٱلرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَىٰكُمۡ عَنۡهُ فَٱنتَهُواْۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ 7
Ohun ti Allah ba se ni idẹkun fun ojisẹ Rẹ ninu awọn dukia ara awọn abule laisi ipaniyan nibẹ jẹ ti Allah, O ma nse fun ẹniti o ba wu U, O si se inikapa fun ojisẹ naa ati fun awọn alasunmọ Rẹ ninu awọn arọmọdọmọ hasimu ati arọmọdọmọ Mutọlibu; ki o le jẹ irọpopada fun wọn nibi itọrẹ ti wọn kọ fun wọn ati fun awọn ọmọ orukan ati awọn alaini, ati fun awọn ajoji eyiti inawo wọn tan; ki wọn ma baa se onidinwọn kekere nibi titẹwọn lọwọ dukia lori awọn ọlọrọ yatọ si awọn alaini, ohun ti ojisẹ naa ba fun yin ninu awọn dukia oju ogun, ki ẹ ya gba a - ẹyin olugbagbọ ododo - ohun ti wọn ba si kọ fun yin kuro nibẹ ki ẹ jawọ kuro, ki ẹpaya Allah pẹlu mimu sẹ awọn ohun ti o pa lasẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, dajudaju Allah jẹ oniya lile, ki ẹ sọra fun iya Rẹ.
لِلۡفُقَرَآءِ ٱلۡمُهَٰجِرِينَ ٱلَّذِينَ أُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَأَمۡوَٰلِهِمۡ يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٗا وَيَنصُرُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّٰدِقُونَ 8
Ki wọn si na abala kan ninu dukia yii fun awọn alaini oluserin ajo si oju ọna Allah, awọn ti wọn jẹnipa lati gbe gbogbo dukia wọn ati awọn ọmọ wọn ju silẹ, wọn nrankan ki Allah se ọla arisiki fun wọn ni ile aye ati iyọnu ni ọrun, wọn nse aranse fun Allah, wọn si nse aranse fun ojisẹ Rẹ pẹlu sise igbiyanju si oju ọna Allah, awọn wọnyi ni a fi awọn iryin wọnyi royin, awọn si ni ẹniti o rinlẹ nibi igbagbọ lododo.
Nigbati Allah sọ awọn oluse irin ajo, ti O si yin wọn, O tun sọ awọn alaranse, O si yin wọn bakanna, Oun ti mimọ nbẹ fun si sọpe:
وَٱلَّذِينَ تَبَوَّءُو ٱلدَّارَ وَٱلۡإِيمَٰنَ مِن قَبۡلِهِمۡ يُحِبُّونَ مَنۡ هَاجَرَ إِلَيۡهِمۡ وَلَا يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمۡ حَاجَةٗ مِّمَّآ أُوتُواْ وَيُؤۡثِرُونَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ وَلَوۡ كَانَ بِهِمۡ خَصَاصَةٞۚ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفۡسِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ 9
Awọn alaranse ti wọn sọkalẹ si ilu Madinah siwaju awọn onirin ajo, wọn si sẹsa igbagbọ si Allah ati si ojisẹ Rẹ, wọn nifẹ si awọn ti o se irin ajo wa ba wọn lati ilu Mẹkka, ẹ ko nii ri ibinu tabi keeta ninu ọkan wọn si awọn onirin ajo ni oju ọna Allah nigbati wọn ba fun wọn ni nkankan ninu ere ogun, ti wọn ko si fun awọn, wọn yoo si maa ti awọn onirin ajo siwaju ara wọn nibi awọn ipin aye, koda bi wọn jẹ ẹni ti a fi osi tabi bukaata nini royin, ẹniti Allah ba sọ nibi oju kokoro ẹmin rẹ si owo, ti o si na an si oju ọna Rẹ, awọn wọnyi ni ẹniti yoo jere lile ba ohun ti wọn nrankan ati lila kuro nibi ohun ti wọn nbẹru rẹ.
Sise ohun ti wọn nlero wipe o jẹ ibajẹ lati le ri amusẹ ba anfaani ti o tobi, ko si ninu ojupọnna ibajẹ si orilẹ.
Ninu awọn ẹwa ẹsin alaafia ni kikiyesi ẹni ti o ba ni bukaata si owo, ki wọn si na ere ogun fun wọn dipo awọn ọlọrọ ti wọn ti to pẹlu ohun ti nbẹ lọdọ wọn.
Gbigbọla lori ara ẹni jẹ ipo kan ti o tobi ninu awọn ipo ẹsin alaafia, ti o si han lọdọ awọn alarnse ni hihan daadaa.