وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنَّكَ تَرَى ٱلۡأَرۡضَ خَٰشِعَةٗ فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡۚ إِنَّ ٱلَّذِيٓ أَحۡيَاهَا لَمُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 39
Atipe ninu awọn amin Rẹ eyiti o ntọka si titobi Rẹ ati ijọkan soso Rẹ ati si agbara Rẹ lori ajinde nipa wipe iwọ nri ilẹ ti ko si irugbin nibẹ, nigbati a ba wa sọ omin ojo kalẹ le lori yoo para da, ki idagbasoke le ba ohun ti a fi pamọ sinu rẹ ninu awọn irugbin, yoo wa yọ soke, dajudaju ẹniti o ta ilẹ ti o ti ku ji pẹlu awọn irugbin, paapaa Oun ni oluji awọn oku, olugbewọn dide fun isiro ati ẹsan, dajudaju Oun jẹ Alagbara lori gbogbo nkan, tita ilẹ ji lẹyin iku rẹ ko le ko agara ba A, bẹẹ naa ni tita awọn oku ji ati gbigbe wọn dide kuro ninu saare wọn.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا لَا يَخۡفَوۡنَ عَلَيۡنَآۗ أَفَمَن يُلۡقَىٰ فِي ٱلنَّارِ خَيۡرٌ أَم مَّن يَأۡتِيٓ ءَامِنٗا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ٱعۡمَلُواْ مَا شِئۡتُمۡ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ 40
Dajudaju awọn ti wọn nyẹ kuro nibi awọn aayah Allah lati ma se dọgba nitori titako o ati pipe e nirọ ati yiyi i pada, isesi wọn ko pamọ fun Wa, Awa mọ wọn, se ẹniti wọn ju sinu ina ni o lọla ju ni tabi ẹniti o de ni ọjọ igbende ni olufọkan balẹ kuro nibi iya naa? ẹ maa sisẹ - ẹyin eniyan - ti o wu yin ninu rere tabi aburu, paapaa a ti salaye rere ati aburu fun yin, dajudaju Allah jẹ oluri ohun ti nse ninu mejeeji, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ yin.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلذِّكۡرِ لَمَّا جَآءَهُمۡۖ وَإِنَّهُۥ لَكِتَٰبٌ عَزِيزٞ 41
Dajudaju awọn ti wọn se keferi si Alukuraani nigbati o de wa ba wọn lati ọdọ Allah, paapaa wọn yoo jẹ ẹni ijẹya ni ọjọ igbende, dajudaju bi ọrọ se ri nipe o jẹ iwe abiyi ti o nkọ aidara, oluyi nkan pada ko lagbara lati yi i pada, olujiirọ kan ko le kiirọ rẹ.
لَّا يَأۡتِيهِ ٱلۡبَٰطِلُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَلَا مِنۡ خَلۡفِهِۦۖ تَنزِيلٞ مِّنۡ حَكِيمٍ حَمِيدٖ 42
Ibajẹ kankan ko le waa ba ni iwaji bẹẹni lati ẹyin nipa adinku tabi alekun tabi iyipada tabi ipalofo, o jẹ nkan isọkalẹ lati ọdọ ọlọgbọn nipa isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati isofin Rẹ, Ẹni ẹyin lori gbogbo isesi.
Nigbati Allah sọ isesi awọn olupe tira naa nirọ, O fun ojisẹ Rẹ ni suuru, O si fun ni itutu ẹmin pẹlu ohun ti awọn ọmọ iya rẹ ninu awọn ojisẹ nba pade siwaju rẹ gẹgẹ bi ipeninirọ, ifiniseyẹyẹ ati idadaparọmọni, O wa sọpe:
مَّا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدۡ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِن قَبۡلِكَۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغۡفِرَةٖ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٖ 43
Nkan ti wọn wi fun ọ - irẹ ojisẹ - gẹgẹbi ipeni nirọ ko jẹ nkankan ayaafi ohun ti wọn ti wi fun awọn ojisẹ ti o siwaju rẹ, ki o ya se suuru, dajudaju Ọlọhun rẹ jẹ alaforijin fun ẹniti o ba sẹri lọsi ọdọ Rẹ ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ onijiya ti O le fun ẹniti o ba taku lori ẹsẹ rẹ ti ko sẹri pada.
وَلَوۡ جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَانًا أَعۡجَمِيّٗا لَّقَالُواْ لَوۡلَا فُصِّلَتۡ ءَايَٰتُهُۥٓۖ ءَا۬عۡجَمِيّٞ وَعَرَبِيّٞۗ قُلۡ هُوَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ هُدٗى وَشِفَآءٞۚ وَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ فِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٞ وَهُوَ عَلَيۡهِمۡ عَمًىۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُنَادَوۡنَ مِن مَّكَانِۢ بَعِيدٖ 44
Ti o ba jasi wipe A sọ Alukuraani yii kalẹ pẹlu ede ti kii se larubawa, awọn keferi inu wọn ki ba sọpe: ti wọn ba salaye awọn aayah rẹ ni, a ba gbọye, se Alukuraani yoo jẹ ede miran ni, ti ẹniti o mu wa si jẹ larubawa? Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn eniyan wọnyi: alukurani yii jẹ - fun awọn ti o nigbagbọ ninmu Allah, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ lododo - imọna kuro nibi anu ati iwosan fun aimọkan ati ohun ti o tẹle, ti o wa ninu igbaaya, awọn ti wọn ko nigbagbọ ninu Allah, edidi wa ninu awọn eti wọn, o si jẹ ohun ti wọn ko le ri, bẹẹni wọn ko le gbọ ọ ye, awọn ti a fi awọn iroyin yii royin da gẹgẹ bi ẹniti wọn npe ni aaye ti o jin, bawo ni wọn se wa fẹ gbọ ohun olupepe!
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ 45
Paapaa a si ti fun Musa ni taoreeta, wọn si yapa si i; o wa ninu wọn ẹniti o gba a gbọ, o si wa ninu ẹniti o se keferi si i, ti kii ba se adehun lati ọdọ Allah lati yanju ọrọ laarin awọn ẹru ni ọjọ igbende alukiyaamọ nibi ohun ti wọn nyapa si, ki ba dajọ laarin awọn oluyapa ninu taoreeta, ẹniti o tọ ki ba hande kuro nibi onibajẹ, ẹniti o tọ ki ba ri apọnle, bẹẹni onibajẹ ki ba yẹpẹrẹ, atipe dajudaju awọn keferi wa ninu iyemeji oniroyiroyi nibi ọrọ Alukuraani.
مَّنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ 46
Ẹniti o ba sisẹ rere, anfaani isẹ rere yoo sẹri lọ si ọdọ rẹ, Allah jẹ ẹniti isẹ rere ẹnikankan ko le se Allah ni anfaani, ẹni o ba se buburu, inira eleyi yoo sẹri lọọ ba, Alah jẹ ẹniti asise ẹnikẹni ninu awọn ẹda Allah ko le ko inira ba A, yoo si san onikaluku ni ẹsan ohun ti o ba tọ si, bẹẹni Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - kii se alabosi si ẹru Rẹ, ko nii din daadaa wọn ku, bẹẹni ko nii se alakun asise.
Allah daabobo Alukuraani kuro nibi ijirọ ati iyipada, Oun ti mimọ nbẹ fun si la isọ naa bọrun yatọ si awọn iwe ti o ti siwaju fun un.
Mimu awijare ti o tan wa lori awọn ẹlẹbọ larubawa pẹlu sisọkalẹ Alukuraani ni ede wọn.
Mimu abosi sise jinna si Allah ati fifi deedee sise rinlẹ fun Un.