هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَكُمۡ خَلَٰٓئِفَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ فَمَن كَفَرَ فَعَلَيۡهِ كُفۡرُهُۥۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ كُفۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ إِلَّا مَقۡتٗاۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ كُفۡرُهُمۡ إِلَّا خَسَارٗا 39
Oun ni O se apakan yin ni - ẹyin eniyan - ẹniti o nrole ẹlomiran lori ilẹ, ki O le dan yin wo bawo ni ẹ o se se, ẹniti o ba se keferi si Allah ati ohun ti awọn ojisẹ mu wa fun un, ẹsẹ keferi rẹ ati jiya rẹ yoo sẹri lọ ba, keferi rẹ ko le ko inira ba Ọlọhun Ọba rẹ, keferi awọn keferi ko le le nkankan kun lọdọ Ọlọhun Ọba wọn ti mimọ nbẹ fun ayaafi ikorira ti o le, keferi awọn alaimoore ko le le nkankan kun fun wọn ju ofo lọ nitori wọn yoo sofo ohun ti Allah pese fun wọn ni ọgba idẹra ti wọn ba ni igbagbọ.
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ شُرَكَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا فَهُمۡ عَلَىٰ بَيِّنَتٖ مِّنۡهُۚ بَلۡ إِن يَعِدُ ٱلظَّٰلِمُونَ بَعۡضُهُم بَعۡضًا إِلَّا غُرُورًا 40
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi: ẹ fun mi niro nipa awọn akẹgbẹ yin eyiti ẹ njọsin fun yatọ si Allah, kinni wọn da ni ilẹ? Se wọn da oke rẹ ni? Tabi wọn da awọn odo rẹ? Tabi wọn da awọn ẹran ko rẹ? Tabi wọn ba Allah kẹgbẹ nibi dida gbogbo sanmọ? Tabi a fun wọn ni iwe kan ti ẹri nbẹ ninu rẹ, ti o ntọka lori lilalaafia ijọsin wọn fun awọn ẹlẹbọ wọn? Ikankan ko sẹlẹ nibi eleyi bikosepe awọn alabosi ko se adehun nkankan fun ẹmin ara wọn lori keferi ati awọn ẹsẹ ni apakan wọn si apakan ju itanjẹ lọ.
۞إِنَّ ٱللَّهَ يُمۡسِكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ أَن تَزُولَاۚ وَلَئِن زَالَتَآ إِنۡ أَمۡسَكَهُمَا مِنۡ أَحَدٖ مِّنۢ بَعۡدِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورٗا 41
Dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun gba gbogbo sanmọ ati ilẹ mu, ti o nkọ lati yẹ mejeeji, ti mejeeji ba ti ẹ yẹ - ni ojupọnna gbigbe yẹwo - ẹnikankan ko le gbamu lati ma yẹ lẹyin Oun naa ti mimọ nbẹ fun, dajudaju o jẹ alatẹmọra ti kii kanju ifiyajẹni, oluforijin gbogbo ẹsẹ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ.
وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَئِن جَآءَهُمۡ نَذِيرٞ لَّيَكُونُنَّ أَهۡدَىٰ مِنۡ إِحۡدَى ٱلۡأُمَمِۖ فَلَمَّا جَآءَهُمۡ نَذِيرٞ مَّا زَادَهُمۡ إِلَّا نُفُورًا 42
Awọn keferi opurọ yii nbura ni ibura ikanpamọ ti o le: ti ojisẹ ba wa lati ọdọ Allah, ti o si se ikilọ fun wọn kuro nibi iya rẹ ni, idurosinsin wọn ki ba pọ, bẹẹni itẹle ododo wọn naa ju yahuudi ati nasaarọ lọ ati ẹlomiran wọn, sugbọn nigbati Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun wa ba wọn, ti a ran an lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, ti o fi iya Allah da ẹru ba wọn, wiwa rẹ ko le nkankan kun fun wọn ayaafi jijinna si ododo ati sisorọ mọ ibajẹ, wọn ko mu adehun ohun ti wọn bura le lori niti kikanpa mọ sẹ lori wipe awọn yoo jẹ ẹni imọna ju ẹniti o ti siwaju wọn lọ.
ٱسۡتِكۡبَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَكۡرَ ٱلسَّيِّيِٕۚ وَلَا يَحِيقُ ٱلۡمَكۡرُ ٱلسَّيِّئُ إِلَّا بِأَهۡلِهِۦۚ فَهَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا سُنَّتَ ٱلۡأَوَّلِينَۚ فَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلٗاۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَحۡوِيلًا 43
Fifi Allah bura wọn lori ohun ti wọn fi bura yii kii se erongba ti o dara ati adisọkan ti o mọ bikojẹ isegberaga lorilẹ ati itaniyan jẹ, bẹẹni ete aburu ko nii ba ẹnikẹni ayaafi awọn ẹni elete, njẹ awọn olusegberaga elete yii nreti nkankan bi ayaafi isesi Allah ti o rinlẹ; ohun si ni pipa wọn run gẹgẹ bi o se pa awọn ẹni isaaju wọn run?! Iwọ ko le ri iyipada fun isesi Ọlọhun Ọba nibi ki pipa awọn olusegberaga run ma sẹlẹ, bẹẹni ko nii si yiyi pada si ki o sẹlẹ ẹniti o yatọ si wọn; nitoripe o jẹ isesi Ọlọhun Ọba ti o rinlẹ.
أَوَ لَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ وَكَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعۡجِزَهُۥ مِن شَيۡءٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَلِيمٗا قَدِيرٗا 44
Se awọn ti o npe ọ nirọ ninu Quraysh ko wa rin lori ilẹ ni ki wọn fi le ronu si bi igbẹyin awọn ti o parọ ninu ijọ ti o siwaju wọn se ri? Kii wa se wipe igbẹyin wọn jẹ aburu nitori pipa run ti Allah pa wọn run, wọn si jẹ ẹniti o lagbara gidigidi ju Quraysh lọ?! Nkankan ko si le bọ mọ Allah lọwọ ninu gbogbo sanmọ, bẹẹni ni inu ilẹ, dajudaju o jẹ onimimọ nipa gbogbo isẹ awọn olupurọ, nkankan ko pamọ fun un ninu isẹ wọn, bẹẹni ko le bọ mọ lọwọ, O jẹ alagbara lati le pa wọn run nigba kiigba ti o ba wu U.
Keferi sise jẹ okunfa ibinu Allah ati ọna ofo ati oriburuku.
Awọn ẹlẹbọ ko si ẹri fun wọn lori ẹbọ wọn lati bi laakaye tabi ẹgbawa.
Piparun alabosi nibi idari ni aye ni kiakia tabi nipipẹ.