وَقَٰرُونَ وَفِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَۖ وَلَقَدۡ جَآءَهُم مُّوسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كَانُواْ سَٰبِقِينَ 39
A tun pa Qọruna run –nigbati o kọja ẹnu aala si ijọ Musa- pẹlu titẹ ẹ ri ati ile rẹ, bẹẹni a pa fir'aona ati asoju rẹ hamana run pẹlu itẹri si inu odo, paapaa Musa si ti mu awọn amin ti o fi oju han wa ba wọn eyiti o ntọka si ododo rẹ, wọn si se igberaga lori ilẹ misirọ kuro nibi igbagbọ si Allah, wọn ko le jẹ ẹniti o la kuro nibi iya Wa pẹlu bibọ wọn mọ Wa lọwọ.
فَكُلًّا أَخَذۡنَا بِذَنۢبِهِۦۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِ حَاصِبٗا وَمِنۡهُم مَّنۡ أَخَذَتۡهُ ٱلصَّيۡحَةُ وَمِنۡهُم مَّنۡ خَسَفۡنَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ وَمِنۡهُم مَّنۡ أَغۡرَقۡنَاۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 40
A gba ikini keji ninu awọn ti a darukọ siwaju mu pẹlu iya Wa eyiti o npani run, o wa ninu ijọ Lutu awọn ti a ran okuta ina sijiili ti a tẹ si, o si wa ninu ijọ Sọlihu ati ijọ Shuaibu awọn ti a fi igbe jija gba mu, bẹẹ ni o wa ninu wọn Qọruna eyiti a lilanu ile gbemi ati ile rẹ, o si tun wa ninu ijọ fir'aona ati hamana awọn ti a parun pẹlu itẹri, Allah ko jẹ ẹniti O se abosi si wọn nibi pipawọn run laini ẹsẹ sugbọn wọn jẹ ẹniti o se abosi ẹmin ara wọn nibi dida awọn ẹsẹ, wọn si lẹtọ si iya naa.
مَثَلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡلِيَآءَ كَمَثَلِ ٱلۡعَنكَبُوتِ ٱتَّخَذَتۡ بَيۡتٗاۖ وَإِنَّ أَوۡهَنَ ٱلۡبُيُوتِ لَبَيۡتُ ٱلۡعَنكَبُوتِۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ 41
Apejuwe awọn ẹlẹbọ ti wọn nmu nkan mi yatọ si Allah yatọ si oosa ti wọn nsin ni ireti anfaani wọn tabi isipẹ wọn da gẹgẹ bi apejuwe alantaakun ti o kọ ile niti idaabobo kuro nibi ibasọta, bẹẹ si ni dajudaju ile ti o lẹ ju ni ile alantaakun, ko le ti ọta da nu fun un, bẹẹ gẹgẹ ni awọn oosa wọn ti ko le se anfaani, ko le munira, bẹẹ ni ko le sipẹ, ti o ba ja sipe awọn ẹlẹbọ mọ eleyi ni, wọn ko ba mu wọn oosa ti wọn nsin yatọ si Allah.
إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 42
Dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun mọ ohun ti ẹ nsin yatọ si I, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi, Oun ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori, ọjọgbọn nibi isẹda, ipebubu ati idari Rẹ.
وَتِلۡكَ ٱلۡأَمۡثَٰلُ نَضۡرِبُهَا لِلنَّاسِۖ وَمَا يَعۡقِلُهَآ إِلَّا ٱلۡعَٰلِمُونَ 43
Awọn apejuwe wọnyi eyiti a fi lelẹ fun awọn eniyan ki o le ta wọn ji ati ki o le mu wọn ri ododo, ki o si le tọ wọn si oju ọna rẹ eyiti yoo mu wọn lepa ba ojupọnna ohun ti wọn nwa gan ayaafi awọn onimimọ nipa ofin Allah ati ọgbọn Rẹ.
خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ 44
Allah ti mimọ nbẹ fun da awọn sanmọ ati ilẹ pẹlu ododo, ko si da a niti ibajẹ, bẹẹni ko da a niti ere, dajudaju nibi sisẹda yii jẹ itọka ti o fi oju han lori agbara Allah fun awọn olugbagbọ ododo; nitoripe awọn ni wọn fi sisẹda Allah tọka lori Adani ti mimọ nbẹ fun, sugbọn awọn keferi ma nrekọja nibi awọn amin ti nbẹ ni oferefe ati awọn ẹmin laini ta wọn ji sibi titobi Adani ati agbara Rẹ ti mimọ nbẹ fun.
ٱتۡلُ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَۖ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ تَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِۗ وَلَذِكۡرُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تَصۡنَعُونَ 45
Ka - irẹ ojisẹ - fun awọn eniyan ohun ti Allah fi ransẹ si ọ ninu Alukuraani, ki o si mu irun wa ni ojupọnna pipe, dajudaju irun ti a ki pẹlu iroyin rẹ ti o pe yoo kọ fun ẹniirẹ kuro nibi awọn ẹsẹ ati awọn nkan ikorira; nitori imọlẹ inu ọkan eyiti yoo da silẹ, ti yoo waa maa fi kọ nibi gigunle ẹsẹ, yoo si maa tọka lọ si ibi awọn isẹ rere, iranti Allah ni ohun ti o tobi ju, bẹẹni o se pataki ju gbogbo nkan lọ, bakanna ni Allah mọ ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ yin, yoo si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin, ti o ba jẹ rere, ẹsan yoo jẹ rere, ti o ba si jẹ aburu, ẹsan naa yoo jẹ aburu.
Pataki fifi apejuwe lelẹ: “gẹgẹ bi alantaakun”.
Nini onka oniranran onka ni ile aye.
Mimọ kanga Allah kuro nibi abosi.
Sisopọ mọ ohun ti o yatọ si Allah jẹ sisopọmọ ohun ti o lẹ ju ninu awọn okunfa.
Pataki irun kiki nibi fifi tun iwa olugbagbọ ododo se.