وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡحَسۡرَةِ إِذۡ قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ وَهُمۡ فِي غَفۡلَةٖ وَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ 39
Ki o si se ikilọ - irẹ ojisẹ - fun awọn eniyan ni ọjọ abamọ nigbati alasise yoo maa kabamọ lori asise rẹ, ti oluse rere yoo maa kabamọ lori aipọ ni isẹ itẹlasẹ ni igbati wọn ti pa iwe ẹru de, ti wọn si ti se tan nibi isiro wọn, ti ẹnikọọkan si ti lọsi ibi ohun ti o ti siwaju, ti wọn si jẹ ẹniti o gba itanjẹ ninu isẹmin aye wọn pẹlu rẹ, ti wọn si ti gbagbe ọjọ ikẹyin, wọn ko ni igbagbọ ninu ọjọ igbende.
إِنَّا نَحۡنُ نَرِثُ ٱلۡأَرۡضَ وَمَنۡ عَلَيۡهَا وَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ 40
Dajudaju Awa ni a o sẹku nigbati gbogbo ẹda ba tan, a o jogun ilẹ, A o si tun jogun awọn ti o wa lori rẹ nitori titan ti wọn ati siẹku tiWa, A o se ọla le wọn lori, A o si se bi o se wu Wa le wọn lori, ọdọ Wa nikan ni wọn yoo si sẹri si ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِبۡرَٰهِيمَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صِدِّيقٗا نَّبِيًّا 41
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ iro Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun, dajudaju o jẹ ọlọpọlọpọ ododo ati ẹniti o ma ngba awọn amin Allah gbọ, o si tun jẹ Anọbi lati ọdọ Allah.
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ يَٰٓأَبَتِ لِمَ تَعۡبُدُ مَا لَا يَسۡمَعُ وَلَا يُبۡصِرُ وَلَا يُغۡنِي عَنكَ شَيۡٔٗا 42
Nigbati o sọ fun baba rẹ Aṣara: irẹ baba mi; kilo de ti o fi nsin ohun ti o yatọ si Allah gẹgẹ bi oosa, ti ko le gbọ adua rẹ nigbati o ba pe e, ko si le ri ijọsin rẹ nigbati o ba nsin in, ko si le mu inira kuro fun ọ, bẹẹni ko le mu anfaani kankan wa fun ọ?!
يَٰٓأَبَتِ إِنِّي قَدۡ جَآءَنِي مِنَ ٱلۡعِلۡمِ مَا لَمۡ يَأۡتِكَ فَٱتَّبِعۡنِيٓ أَهۡدِكَ صِرَٰطٗا سَوِيّٗا 43
Irẹ baba mi paapaa imọ ti waa ba mi ni ojupọnna imisi ti ko waa ba ọ, tẹle mi ki ntọ ẹ si oju ọna ti o duro tọ.
يَٰٓأَبَتِ لَا تَعۡبُدِ ٱلشَّيۡطَٰنَۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ عَصِيّٗا 44
Irẹ baba mi,. ase sin esu nibi mima tẹle asẹ rẹ nitoripe esu jẹ ẹlẹsẹ si ọba ajọkẹ aye nigbati o pa a lasẹ ki o fi ori balẹ fun Aadamọ ti ko si fi ori balẹ.
يَٰٓأَبَتِ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يَمَسَّكَ عَذَابٞ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ فَتَكُونَ لِلشَّيۡطَٰنِ وَلِيّٗا 45
Irẹ baba mi, emi npaya ki iya ma waa ba ọ lati ọdọ Ọba Ajọkẹ aye ti o ba ku lori keferi rẹ, ki o ma baa di alasunmọ fun esu nibi iya nitori mimu u lọrẹ.
قَالَ أَرَاغِبٌ أَنتَ عَنۡ ءَالِهَتِي يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُۖ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ لَأَرۡجُمَنَّكَۖ وَٱهۡجُرۡنِي مَلِيّٗا 46
Aṣara sọ fun ọmọ rẹ Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun: se iwọ yoo gunri kuro nibi awọn oosa mi eyiti mo nsin irẹ Ibrahim?! ti o ba jawọ kuro nibi didu awọn oosa mi, emi yoo ju okuta mọ ọ, ki o si pin ya kuro ni ọdọ mi fun asiko ti o gun, ki o ma ba mi sọrọ, ki o si ma wa pẹlu mi.
قَالَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكَۖ سَأَسۡتَغۡفِرُ لَكَ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ بِي حَفِيّٗا 47
Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun baba rẹ: alaafia Ọlọhun Ọba ki o maa bẹ fun ọ lati ọdọ mi, ohun ti o korira lọdọ mi ko nii ba ọ, emi yoo wa aforijin ati imọna fun ọ ni ọdọ Ọlọhun Ọba mi, dajudaju Oun jẹ ẹniti mimọ nbẹ fun, O si jẹ ẹniti aanu Rẹ pọ si mi.
وَأَعۡتَزِلُكُمۡ وَمَا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَأَدۡعُواْ رَبِّي عَسَىٰٓ أَلَّآ أَكُونَ بِدُعَآءِ رَبِّي شَقِيّٗا 48
Emi yoo pinya pẹlu yin, emi yoo si tun pinya pẹlu nkan ijọsin yin ti ẹ nsin yatọ si Allah, maa maa pe Ọlọhun Ọba mi nikan soso, o seesee ki O ma kọ fun mi nigbati mo ba pe E, ki nma ba jẹ oloriibu pẹlu pipe E.
فَلَمَّا ٱعۡتَزَلَهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۖ وَكُلّٗا جَعَلۡنَا نَبِيّٗا 49
Nigbati o gbe wọn ju silẹ, ti o si tun gbe ọlọhun wọn ti wọn nsin yatọ si Allah, A jiirọ fun nipa pipadanu ara ile rẹ, a si ta a lọrẹ ọmọ Ishaaq, A si tun fun ni arọmọdọmọ ya'quub, bẹẹni ikini keji ninu wọn ni a se ni Anọbi.
وَوَهَبۡنَا لَهُم مِّن رَّحۡمَتِنَا وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ لِسَانَ صِدۡقٍ عَلِيّٗا 50
A fun wọn ni oore ti o pọ lati inu ikẹ wa pẹlu jijẹ Anọbi, a si se ẹyin daradara ti yoo maa lọ lori ahọn awọn ẹru fun wọn.
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مُوسَىٰٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ مُخۡلَصٗا وَكَانَ رَسُولٗا نَّبِيّٗا 51
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun iro Musa ẹniti ọla nbẹ fun, dajudaju o jẹ ẹni ẹsa, ẹni afọmọ, o si jẹ ojisẹ ati anọbi.
Nigbati yiyẹra Ibrahim fun awọn ijọ rẹ jẹ ajọsepọ pẹlu Saarata, o se deede didarukọ ọrẹnta ti awọn mejeeji papọ nibẹ ati arọmọdọmọ wọn, lẹyin naa ni iranti Ismaheel wa lọtọ pẹlu wipe Ọlọhun Ọba fi ta lọrẹ siwaju Ishaaq.
Iwuwa ẹkọ, aanu ati pẹlẹpẹlẹ wa nibi iba awọn obi mejeeji sọrọ ati sise ẹsa eyiti o lọla ju nibi pipe orukọ awọn mejeeji.
Awọn ẹsẹ ma nkọ fun ẹru kuro nibi ikẹ Allah, wọn si ma nti awọn ilẹkun Rẹ mọ wọn gẹgẹ bi itẹle asẹ se jẹ okunfa ti o tobi julọ lati ri ikẹ Rẹ.
Ọlọhun Ọba Allah se adehun fun gbogbo oluse daadaa lati fan ẹyin ododo Rẹ ka ni ibamun si daadaa Rẹ, bẹẹni Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun ati arọmọdọmọ rẹ wa ninu awọn asiwaju oluse daadaa.