ذَٰلِكَ مِمَّآ أَوۡحَىٰٓ إِلَيۡكَ رَبُّكَ مِنَ ٱلۡحِكۡمَةِۗ وَلَا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتُلۡقَىٰ فِي جَهَنَّمَ مَلُومٗا مَّدۡحُورًا 39
Eyiti A salaye ninu awọn asẹ ati ikọfunni ati awọn idajọ wa ninu ounti Ọlọhun Ọba rẹ fi ransẹ si ọ ninu imisi, mase mu olujọsin miran mọ Allah - irẹ ọmọniyan - ki o ma baa ju ọ si inu ina Jahannamọ ni ọjọ igbende ni ẹni eebu ti iwọ yoo maa bu ara rẹ, ti awọn eniyan naa yoo si maa bu ọ, ti iwọ yoo si di ẹni ilejina kuro nibi rere.
أَفَأَصۡفَىٰكُمۡ رَبُّكُم بِٱلۡبَنِينَ وَٱتَّخَذَ مِنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنَٰثًاۚ إِنَّكُمۡ لَتَقُولُونَ قَوۡلًا عَظِيمٗا 40
Mo pe irẹ ti o nsọpe awọn Malaika jẹ ọmọbinrin Allah, se Ọlọhun Ọba yin ni O sa yin lẹsa - ẹyin ẹlẹbọ - pẹlu akọ ninu awọn ọmọ, ti wọn waa sa awọn Malaika lẹsa ọmọbinrin fun ara Rẹ? Giga Allah kuro nibi ohun ti ẹ nsọ, dajudaju ohun ti ẹ nsọ nipa Allah ti mimọ nbẹ fun jẹ ọrọ ti o ga ninu aburu nibi sise afiti ọmọ si lọdọ, ti ẹ si nlero wipe O ni awọn ọmọbinrin niti imọọmọ sise keferi si I.
وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِيَذَّكَّرُواْ وَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا نُفُورٗا 41
Paapaa a ti se alaye ninu Alukuraani ati awọn isiti ati awọn apejuwe ki awọn eniyan le gba isiti, ki wọn si le ba tọ ohun ti yoo se wọn ni anfaani, ki wọn si gbe ohun ti yoo konira ba wọn ju silẹ, isesi wọn nipe dajudaju apakan wọn jẹ ẹniti adamọ rẹ ti yi pada, eyi ko le nkankan kun fun ju ijina si ododo lọ ati ikorira rẹ.
قُل لَّوۡ كَانَ مَعَهُۥٓ ءَالِهَةٞ كَمَا يَقُولُونَ إِذٗا لَّٱبۡتَغَوۡاْ إِلَىٰ ذِي ٱلۡعَرۡشِ سَبِيلٗا 42
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi ti o ba jasi wipe awọn ti a njọsin kan ba wa pẹlu Allah ti O ga gẹgẹ bi wọn se nsọ niti apemṣ ati irọ, awọn ẹniti a njọsin fun ti wọn lero yii ki ba wa ọna de ọdọ Ọlọhun Allah ti O ni aga laarasi lati jẹ gaba lori ọla rẹ ati biba se ifanfa nibẹ.
سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يَقُولُونَ عُلُوّٗا كَبِيرٗا 43
Ọlọhun Allah ti mimọ nbẹ fun mọ kanga, bẹẹni O tun kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ fi nroyin rẹ, O si ga ju nkan ti wọn sọ lọ ni giga ti o tobi.
تُسَبِّحُ لَهُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ ٱلسَّبۡعُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهِنَّۚ وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا يُسَبِّحُ بِحَمۡدِهِۦ وَلَٰكِن لَّا تَفۡقَهُونَ تَسۡبِيحَهُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورٗا 44
Sanmọ nse afọmọ fun Allah bẹẹni ilẹ naa nse afọmọ fun Un, gbogbo ẹniti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ ninu awọn ohun ti A da nse afọmọ fun Allah, ko si ohunkihun ayafi ki o se afọmọ Rẹ, ti wọn si nda ẹyin mọ afọmọ rẹ sugbọn ẹ ko gbọ agbọye bi wọn se nse afọmọ fun Un, ẹyin ko le gbọye ayafi afọmọ ti ẹniti nse afọmọ pẹlu ahọn yin nse, dajudaju Oun ti O ga ju ni O jẹ alatẹmọra, kii kanju pẹlu iya, alaforijin fun ẹniti o ba sẹri pada si ọdọ Rẹ.
وَإِذَا قَرَأۡتَ ٱلۡقُرۡءَانَ جَعَلۡنَا بَيۡنَكَ وَبَيۡنَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ حِجَابٗا مَّسۡتُورٗا 45
Nigbati o ba ka - irẹ ojisẹ - Alukuraani, ti wọn si gbọ ijagbemọ ati isiti ti o wa nibẹ, a se gaga ati idaabobo si aarin rẹ ati aarin awọn ti ko nigbagbọ ninu ọjọ igbende, ti yoo kọ fun wọn kuro nibi gbigbọ Alukuraani ye, ki o le jẹ ijiya fun wọn lori igunri wọn.
وَجَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۚ وَإِذَا ذَكَرۡتَ رَبَّكَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِ وَحۡدَهُۥ وَلَّوۡاْ عَلَىٰٓ أَدۡبَٰرِهِمۡ نُفُورٗا 46
A si tun se ebibi si ori ọkan wọn ki wọn ba le gbọ Alukuraani ye, a si tun se ẹru wiwo si awọn inu iho eti wọn ki wọn ma baa gbọ niti gbigbọ sise anfaani nigbati o ba darukọ Ọlọhun Ọba rẹ ninu Alukuraani ni Oun nikan soso, ti o ko darukọ awọn ọlọhun wọn ti wọn nlero, wọn yoo sẹri pada si ẹyin wọn ni ẹniti yoo takete si isafọmọ ọkan soso fun Allah.
نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَسۡتَمِعُونَ بِهِۦٓ إِذۡ يَسۡتَمِعُونَ إِلَيۡكَ وَإِذۡ هُمۡ نَجۡوَىٰٓ إِذۡ يَقُولُ ٱلظَّٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلٗا مَّسۡحُورًا 47
Awa ni a mọ ojupọnna itẹtigbọ awọn olori wọn fun Alukuraani, wọn ko ni gbero imọna pẹlu rẹ, bikosepe wọn yoo maa gbero imuni fifuyẹ ati ere nigbati o ba nka a, awa ni a si mọ ọrọ kẹlẹkẹlẹ ti wọn nsọ ninu irọ ati igunri kuro nibẹ nigbati awọn alabosi yii ba nsọ ọrọ keferi yii fun ẹmin ara wọn: ẹ mase tẹle -ẹyin eniyan - ju ọkunrin kan ti idan ti mu, ti laakaye rẹ si ti lu pọ.
ٱنظُرۡ كَيۡفَ ضَرَبُواْ لَكَ ٱلۡأَمۡثَالَ فَضَلُّواْ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ سَبِيلٗا 48
Woye - irẹ ojisẹ - ki o le se eemọ ninu awọn ohun ti wọn fi nroyin rẹ ninu awọn iroyin eebu eyiti o yatọ si ara wọn, wọn ti gunri kuro nibi ododo, wọn si ndaamu, wọn ko mọ ọna ododo.
وَقَالُوٓاْ أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمٗا وَرُفَٰتًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ خَلۡقٗا جَدِيدٗا 49
Awọn ẹlẹbọ nsọ niti titako igbende: ti a ba ku, ti a si di eegun, ti ẹran ara wa si ti jẹ, se wọn yoo gbe wa ni igbedide titun bi?! Dajudaju eleyi ko le see se.
Ipinnu wipe awọn Malaika jẹ ọmọbinrin Allah jẹ adapa irọ ti o tobi ati ọrọ ẹsẹ ti o tobi ni ọdọ Allah ti mimọ nbẹ fun.
Ọpọ ninu awọn eniyan, awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah kii lekun fun wọn ju ijina lọ; nitori ikorira wọn si ododo ati ifẹ ti wọn ni si ibajẹ ti wọn wa lori rẹ.
Ko si ẹniti a da kan ninu sanmọ tabi ilẹ ayafi ki o maa se afọmọ ọpẹ fun Allah ti O ga, o wa tọ fun ẹru ki ẹda kankan ma siwaju nibi afọmọ.
Ninu atẹmọra Allah lori awọn ẹru Rẹ ni wipe kii kanju fi iya jẹ wọn lori ifọnu wọn ati biburu isẹ wọn, nitoripe ikẹ Rẹ gbawaju ibinu Rẹ.