وَٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ رِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَلَا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۗ وَمَن يَكُنِ ٱلشَّيۡطَٰنُ لَهُۥ قَرِينٗا فَسَآءَ قَرِينٗا 38
Bakanna ni a pese iya naa fun awọn ti wọn nna dukia wọn nitori ki awọn eniyan le ba ri wọn, ki wọn si maa baa yin wọn, awọn wọn ni, wọn ko ni igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ati ọjọ igbende, A pese iya idojuti naa fun wọn, ko si ohun ti o si wọn lọna ju mima tẹle esu lọ, ẹnikẹni ti esu ba jẹ alabarin, olusunmọ fun, isumọ-buru ni o jẹ.
وَمَاذَا عَلَيۡهِمۡ لَوۡ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِهِمۡ عَلِيمًا 39
Kini yoo ko inira ba awọn eniyan yii, ti wọn ba gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ ni tootọ ati ọjọ igbende, ti wọn si na gbogbo ọrọ ti Ọlọhun Ọba Allah se fun wọn ni awọn ojupọna ti O nnifẹ ti O si nyọnu si? ! , paapaa julọ nibi iyẹn ni oore wa, Ọlọhun Ọba Allah si jẹ onimimọ pẹlu wọn, isesi wọn ko pamọ fun Un, Yoo si san gbogbo wọn ni ẹsan pẹlu isẹ re.
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظۡلِمُ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖۖ وَإِن تَكُ حَسَنَةٗ يُضَٰعِفۡهَا وَيُؤۡتِ مِن لَّدُنۡهُ أَجۡرًا عَظِيمٗا 40
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti o ga julọ, ko nii se abosi si ẹru Rẹ kankan, ko si nii din odiwọn awurebe ti o kere ju ninu isẹẹ-re wọn, ko si nii se alekun nkankan kan ninu asise wọn, ti isẹẹ-re wọn ba jẹ deede horo agbado, Yoo se adipele ẹsan rẹ ni ti ọla lati ọdọ Rẹ, bakannaa yoo fun wọn ni adipele ẹsan ti o tobi lati ọdọ Rẹ.
فَكَيۡفَ إِذَا جِئۡنَا مِن كُلِّ أُمَّةِۢ بِشَهِيدٖ وَجِئۡنَا بِكَ عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ شَهِيدٗا 41
Bawo ni ọrọ yoo se ri ni ọjọ igbende Alukiyaamọ nigbati wọn ba mu Anọbi ijọ kọọkan wa, ti njẹri le wọn lori pẹlu ohun ti wọn se, ti o si tu nmu iwọ naa wa irẹ ojisẹ ti o jẹ olujẹri lori awọn ijọ rẹ? ! .
يَوۡمَئِذٖ يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَعَصَوُاْ ٱلرَّسُولَ لَوۡ تُسَوَّىٰ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضُ وَلَا يَكۡتُمُونَ ٱللَّهَ حَدِيثٗا 42
Ni ọjọ ti o tobi naa, awọn kefere si Ọlọhun Ọba Allah ti wọn si tun jẹ oluyapa si ojisẹ Rẹ yoo maa nifẹ si ki awọn di yẹpẹ, ki awọm ati ilẹ le ri bakanna, wọn ko le fi pamọ fun Ọlọhun Ọba Allah ohun ki hun ninu nkan ti wọn se nisẹ, nitori wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo di ahọn wọn, wọn ko nii le sọrọ, Yoo si yọnda fun orikerike ara wọn, ki o maa jẹri le wọn lori pẹlu isẹ ti wọn se.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡرَبُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنتُمۡ سُكَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَعۡلَمُواْ مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِي سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغۡتَسِلُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوًّا غَفُورًا 43
A pe ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹ si ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ ko gbọdọ kirun nigbati ẹ ba wa ni ipo ihunrira, titi ẹ yoo fi ni alaafia kuro nibi ihunrira yin, ti ẹ o si fi le se adayanri nakn ti ẹ nsọ, - eleyi jẹ siwaju sise ọti ni eewọ tan yan-an yan-an -, ẹ ko si gbọdọ kirun, ti ẹ ba ni ipo janaba, ẹ ko si gbọdọ wọ inu awọn Masalaasi ni isesi naa, ayaafi ti ẹ ba jẹ olurekọja, ti ẹ ko sẹku si inu rẹ; titi ti ẹ yoo fi wẹ, ti aarẹ ba se yin, ti ko rọrun lati lo omi pẹlu rẹ, tabi ẹ jẹ oluse irin-ajo, tabi ẹnikan se ẹgbin ninu yin, tabi ẹ ba awọn obinrin lopọ; ti ẹ ko ri omi, -ki ẹ gbero yerupẹ ti o mọ, ẹ ba oju yin ati awọn ọwọ yin ninu rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ alamojukuro nipa aiseeto yin, O si tun jẹ oluse aforijin fun yin.
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يَشۡتَرُونَ ٱلضَّلَٰلَةَ وَيُرِيدُونَ أَن تَضِلُّواْ ٱلسَّبِيلَ 44
Se o ko wa mọ ni - ire ojise - ọrọ yahuudi, awọn ti Ọlọhun Ọba Allah fun ni imọ taoreeta, wọn nse pasipaarọ ọna anu pẹlu ọnaamọ, wọn si ni amojuto lori sisi yin lọna, - ẹyin olugbagbọ ododo - kuro ni oju ọna ti o duro tọ, eyiti ojisẹ naa mu wa; ki ẹ le baa maa tẹle oju ọna ti wọn eyiti o wọgun? !
Ninu pipe deede Rẹ ati pipe ikẹ Rẹ, ohun ni wipe ko nii se abosi ẹru Rẹ kankan, biotiwulẹ ki o kere mọ, yoo si tun se ọla lati se adipele ẹsan wọn.
Ninu lile koko ipaya ọjọ igbende Alukiyaamọ ati titobi nkan ti nreti keferi, ohun ni ki o rankan lati di yẹẹpẹ.
Janaba wa ninu nkan ti nkọ di ni kuro nibi irun ati sisẹku si inu mọsalaasi, ko si aleebu nibi rirekọja bikose sisẹku si inu rẹ.
Idẹkun Ọlọhun Ọba Allah lori ẹru Rẹ pẹlu sise aluwala oniyẹpẹ ni ofin, nigbati a ba se afẹku omi, tabi ko si agbara lati lo omi.