هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُۥۖ قَالَ رَبِّ هَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ ذُرِّيَّةٗ طَيِّبَةًۖ إِنَّكَ سَمِيعُ ٱلدُّعَآءِ 38
Nibi nkan naa eyiti Zakariya ri ninu isejẹẹmu Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) fun Maryam ọmọbirin Imran lori eyiti ko wọpọ ninu ilana Rẹ (ti ọla Rẹ ga) , nibi isejẹẹmu, o rankan ki Ọlọhun Ọba Allah se arisiki ọmọ fun un pẹlu isesi eyiti o wa ni ori rẹ ninu sisun siwaju ọjọ ori rẹ, ati aile bimọ iyawo rẹ, ni o waa sọ wipe: irẹ Ọlọhun Ọba mi, tami lọrẹ ọmọ ti o dara, dajudaju iwọ ni olugbọ adura ẹniti o ba pe Ọ, Oludalohun.
فَنَادَتۡهُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَهُوَ قَآئِمٞ يُصَلِّي فِي ٱلۡمِحۡرَابِ أَنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحۡيَىٰ مُصَدِّقَۢا بِكَلِمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَسَيِّدٗا وَحَصُورٗا وَنَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 39
Ni awọn Malaika ba pe ni ẹniti o nda oju ọrọ kọọ, ti o si wa ni isesi iduro rẹ fun irun kiki ni aaye ijọsin rẹ, pẹlu gbolohun rẹ wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nfun ọ niro idunnu pẹlu ọmọ kan, ti wọn yoo bi fun ọ, ti orukọ rẹ njẹ Yahaya, ninu iroyin rẹ nipe yoo jẹ ẹniti yoo maa sọ ododo pẹlu gbolohun kan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, oun naa ni Isa ọmọ Maryam - toripe dajudaju oun, wọn da ni dida kan ti o jẹ ẹsa pẹlu gbolohun kan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah - ati wipe ọmọ yii yoo jẹ asiwaju lori awọn ijọ rẹ ninu imọ ati ijọsin ni ẹniti yoo maa kọ fun ẹmi rẹ, ti yoo si mu duro kuro nibi awọn yodoyindin aye, ninu rẹ naa ni sisunmọ awọn obirin, ni ẹniti yoo gbajumọ ijọsin fun Ọlọhun Ọba rẹ, yoo si jẹ - bakanna - Anọbi kan ninu awọn ẹniire.
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَقَدۡ بَلَغَنِيَ ٱلۡكِبَرُ وَٱمۡرَأَتِي عَاقِرٞۖ قَالَ كَذَٰلِكَ ٱللَّهُ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ 40
Zakariya sọ nigbati awọn Malaika fun ni iro idunnu pẹlu Yahaya wipe: irẹ Ọlọhun Ọba mi, bawo ni ọmọ yoo se wa fun mi, lẹyin igbati mo ti di agbalagba, ati wipe obirin mi si ti di ẹniti ko le bi ọmọ, ti wọn ko le se ọmọ fun! Ọlọhun Ọba Allah sọ ni ifesi lori gbolohun rẹ wipe: apẹrẹ dida Yahaya lori didagba ọjọ ori rẹ, ati aile bimọ iyawo rẹ da gẹgẹ bi dida ẹda ti Ọlọhun Ọba Allah ma nda ohun ti o ma wu U, ninu awọn nkan ti o ma nyatọ si ohun ti a ti ba saaba ni adamọ; toripe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah Alagbara ni lori gbogbo nkan, O ma nse ohun ti o ba wu U pẹlu oye Rẹ ati imọ Rẹ.
قَالَ رَبِّ ٱجۡعَل لِّيٓ ءَايَةٗۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَٰثَةَ أَيَّامٍ إِلَّا رَمۡزٗاۗ وَٱذۡكُر رَّبَّكَ كَثِيرٗا وَسَبِّحۡ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ 41
Zakariya sọ wipe: irẹ Ọlọhun Ọba mi, fun mi ni amin lori liloyun obirin mi lati ọdọ mi, Ọlọhun Ọba Allah sọ wipe, amin rẹ eyiti o fẹ ni: ki o ma paka lati le ba awọn eniyan sọrọ fun ọsan mẹta ati awọn oru rẹ ayaafi pẹlu itọkasi ati ohun ti o jọọ laini ni aleebu kan ti yoo fi ọwọ ba ọ, waa pọ ni iranti Ọlọhun Ọba Allah, ati mima se afọmọ Rẹ ni igbẹyin ọsan ati ibẹrẹ rẹ.
وَإِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰكِ وَطَهَّرَكِ وَٱصۡطَفَىٰكِ عَلَىٰ نِسَآءِ ٱلۡعَٰلَمِينَ 42
Ati wipe ranti - irẹ ojisẹ - nigbati awọn Malaika sọ fun Maryam (ki ọla maa jẹ tirẹ) wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah se ẹsa rẹ nitori awọn iroyin ti o ni ninu awọn iroyin ẹlẹyin, ati wipe O si se afọmọ rẹ kuro nibi awọn abuku, ati wipe O se ẹsa rẹ lori gbogbo obirin aye ni asiko rẹ.
يَٰمَرۡيَمُ ٱقۡنُتِي لِرَبِّكِ وَٱسۡجُدِي وَٱرۡكَعِي مَعَ ٱلرَّٰكِعِينَ 43
Irẹ Maryam, maa duro pẹ ninu irun, ki o si tun maa fi ori balẹ fun Ọlọhun Ọba rẹ, ati wipe ki o maa tẹ kọkọ fun Un pẹlu awọn olutẹ kọkọ ninu awọn ẹrusin Rẹ tii se ẹniire.
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۚ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يُلۡقُونَ أَقۡلَٰمَهُمۡ أَيُّهُمۡ يَكۡفُلُ مَرۡيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ 44
Ohun ti A sọ naa ninu iro Zakariya ati Maryam (ki ọla maa jẹ ti awọn mejeeji) nbẹ ninu awọn iro kọkọ, ti A fi nransẹ si ọ - irẹ ojisẹ -, ati wipe iwọ ko si ọdọ awọn onimimọ naa ati awọn ẹniire, ni igbati wọn ba ara wọn se itakorogan, nibi ẹniti yoo ni ẹtọ si titọju Maryam, titi ti wọn fi waa dari sibi imoje, ti wọn si sọ awọn gege wọn silẹ, ni gege Sakariya waa bori (ki ọla maa jẹ tirẹ) .
إِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٖ مِّنۡهُ ٱسۡمُهُ ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ وَجِيهٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ 45
Ranti - irẹ ojisẹ - nigbati awọn Malaika sọ pe: irẹ Maryam, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nfun ọ ni iro idunnu pẹlu ọmọ kan, ti dida rẹ yoo wa lati ibi aini baba, bikose wipe lati ibi gbolohun kan lati Ọlọhun Ọba Allah, pẹlu wipe ki o sọ wipe: maa bẹ (kun) , ti yoo si maa jẹ ọmọ pẹlu iyọnda Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe orukọ ọmọ yii ni, Al-Mọsiihu Isa ọmọ Maryam, ti ipo giga nbẹ fun un ni aye ati ọrun, ti o si wa ninu awọn alasunmọ Rẹ (ti ọla Rẹ ga) .
Nini amojuto Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) pẹlu awọn aayo Rẹ, toripe dajudaju Oun mimọ fun Un, O ma ngbe wọn jinna si aburu, O si ma ngbọ adua wọn.
Ọla ti nbẹ fun Maryam (ki ọla maa jẹ tirẹ) nibi ti Ọlọhun Ọba Allah ti saa lẹsa lori awọn obirin agbanla aye, ti o si tun se afọmọ rẹ kuro nibi awọn abuku, ti o si tun se ni onibunkun.
Gbogbo igbati idẹra Ọlọhun Ọba Allah ba tobi lori ẹru, ni ohun ti o jẹ dandan le lori yoo tobi nibi didupẹ fun le lori pẹlu mima tẹle ati mima tẹ kọkọ ati iforikanlẹ ati awọn ijọsin yoku naa.
Sise imoje ni ofin nigbati iyapa ba wa nibi ohun ti ko fi oju han, ti ko si si ohun ti o sun mọ, ti yoo tọka sii.