إِنَّمَا ٱلنَّسِيٓءُ زِيَادَةٞ فِي ٱلۡكُفۡرِۖ يُضَلُّ بِهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُحِلُّونَهُۥ عَامٗا وَيُحَرِّمُونَهُۥ عَامٗا لِّيُوَاطُِٔواْ عِدَّةَ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ فَيُحِلُّواْ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُۚ زُيِّنَ لَهُمۡ سُوٓءُ أَعۡمَٰلِهِمۡۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 37
Dajudaju ọwọ ti nbẹ ninu awọn osu ọwọ ni ifagun di awọn osu ti kii se osu wọ naa, ati sisọdi aaye rẹ - gẹgẹ bi awọn larubawa se ma nse ni asiko aimọkan - ni ilekun lori sise keferi si keferi wọn si Ọlọhun Ọba Allah; nitori wipe wọn se keferi si idajọ Ọlọhun nibi awọn osu ọwọ, ti eesu ma nfi sọ awọn to jẹ keferi si Ọlọhun Ọba nu latara ikọse ti ko dara ti o fi lelẹ fun wọn, wọn nsọ awọn osu ọwọ ti ẹtọ ni awọn ọdun kan pẹlu sise pasi paarọ osun kan pẹlu awọn osu miran ninu osu ẹtọ, wọn yoo waa maa sẹku lori sise leewọ ni awọn ọdun kan ki o le se dọgba pẹlu awọn onka osu ti Ọlọhun Ọba Allah se leewọ koda bi o yapa si ojulowo rẹ gan an, wọn ko nii se osu kan lẹtọ ayaafi ki wọn o se osu miran dipo aaye rẹ, wọn yoo waa maa ti ara sọ ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se leewọ di ẹtọ ninu awọn osu ọwọ, wọn yoo wa maa yapa idajọ rẹ, esu ni o se awọn isẹ aburu yii lọsọ fun wọn ti wọn fi nse e, o si wa ninu rẹ eyiti wọn da silẹ fun ra a wọn, Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi keferi alaijawọ kuro nibi ẹsẹ se kongẹ lori keferi wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَا لَكُمۡ إِذَا قِيلَ لَكُمُ ٱنفِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱثَّاقَلۡتُمۡ إِلَى ٱلۡأَرۡضِۚ أَرَضِيتُم بِٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا مِنَ ٱلۡأٓخِرَةِۚ فَمَا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِلَّا قَلِيلٌ 38
Ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si nse ohun ti Allah se lofin fun wọn, kilo se yin nigbati wọn ba pe yin lọ si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah lati ba awọn keferi ja, ti ẹyin yoo maa fa sẹyin, ti ẹ wa fi sibi wiwa ninu ile yin?! Se ẹ yọnu si igbadun ile aye ti yoo yẹ ati adun rẹ ti yoo tan dipo idẹkun ọrun ti yoo maa wa gbere eyiti Ọlọhun Ọba Allah pe se fun awọn olugbiyanju si oju ọna Rẹ ni?! Isẹmin aye lẹgbẹ ti ọrun ko gẹ nkan yẹpẹrẹ lọ, bawo ni ẹniti o ni laakaye yoo se wa se ẹsa ohun ti yoo tan lori ohun ti yoo sẹku tabi nkan yẹpẹrẹ lori ohun ti o tobi?!
إِلَّا تَنفِرُواْ يُعَذِّبۡكُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا وَيَسۡتَبۡدِلۡ قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ وَلَا تَضُرُّوهُ شَيۡٔٗاۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 39
Ti ẹ ko ba jade - ẹyin olugbagbọ ododo - fun igbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah lati ba awọn ọta ja, Ọlọhun Ọnba Allah yoo fi ibori ati iyẹpẹrẹ ati ohun ti o yatọ si jẹ yin niya, yoo si paarọ yin pẹlu awọn ijọ miran ti wọn yoo maa tẹle asẹ Rẹ nigbati wọn ba beere fun jijade fun ijagun, ti wọn yoo si maa jade, yiyapa asẹ Rẹ yin ko ni ko inira kankan ba, o jẹ ẹniti o rọrọ kọja yin, ẹyin ẹ jẹ alaini lọ si ọdọ Rẹ, bẹẹ ni Ọlọhun Ọba Allah lagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A, O lagbara lati se aranse fun ẹsin Rẹ, anọbi Rẹ laisi yin nibẹ.
إِلَّا تَنصُرُوهُ فَقَدۡ نَصَرَهُ ٱللَّهُ إِذۡ أَخۡرَجَهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ثَانِيَ ٱثۡنَيۡنِ إِذۡ هُمَا فِي ٱلۡغَارِ إِذۡ يَقُولُ لِصَٰحِبِهِۦ لَا تَحۡزَنۡ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَنَاۖ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَيۡهِ وَأَيَّدَهُۥ بِجُنُودٖ لَّمۡ تَرَوۡهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلسُّفۡلَىٰۗ وَكَلِمَةُ ٱللَّهِ هِيَ ٱلۡعُلۡيَاۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ 40
Ti ẹ ko ba se aranse fun - ẹyin olugbagbọ ododo - ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ti ẹ ko si jẹpe ipepe sibi ijagun si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah, paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti ran se laisi yin nibẹ nigbati awọn ọlọsẹbọ mu u jade oun ati Abu bakr ki iyọnu Ọlọhun maa bẹ fun, ti ko si ẹnikẹta pẹlu awọn mejeeji nigbati wọn wa ninu koto Thaoru, ti awọn mejeeji npaya awọn keferi ti wọn nwa wọn nigbati ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun sọ fun ẹnikeji rẹ Abu bakr olootọ, nigbati o npaya ki awọn ẹlẹbọ ma gba mu: mase paya dajudaju Ọlọhun Ọba Allah wa pẹlu wa pẹlu ikunlọwọ ati aranse Rẹ, bayi ni Ọlọhun Ọba Allah sọ ifọkanbalẹ si ori ọkan ojisẹ Rẹ, O si sọ awọn ọmọ ogun kalẹ ti ẹyin ko ri wọn, awọn naa ni awọn malaika ti nkun lọwọ, O si sọ gbolohun awọn ẹlẹbọ di irẹlẹ, bayi gbolohun Ọlọhun Ọba Allah si di ohun ti o ga julọ nigbati Islam naa ga, Ọlọhun Ọba Allah jẹ alagbara niti ipo, ibori ati ọla, ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi idari, ipebubu, isofin.
Awọn isesi ti o yapa si ofin ẹsin nibi mima tẹsiwaju laitako o yoo jẹ yiyẹ aburu rẹ kuro ni ọkan koda wọn le roo si isesi ti o dara.
Aijade ni asiko ti wọn beere fun ijade wa ninu awọn ẹsẹ nla ti yoo mu ijiya ti o le di ọranyan fun ni nitori inira buruku ti o wa nibẹ.
Ọla ti nbẹ fun ifọkanbalẹ ati wipe o wa ninu pipe idẹkun Allah ni awọn asiko ilekoko ati ipaya eyiti ẹmin ma ndaamu nibẹ, ati wipe yoo wa ni ibamun si bi ẹru ba se mọ Ọlọhun rẹ ati ni ibamun si bi o se gbare le adehun Ọlọhun Ọba ododo si, ati ni ibamun si igbagbọ rẹ ati akin rẹ.
Dajudaju ibanujẹ le sẹri si awọn ẹni ẹsa ninu ẹru Ọlọhun Ọba ti o jẹ olootọ, paapaa julọ nigba ipaya lori bibọ anfaani gbogboogbo.