رِجَالٞ لَّا تُلۡهِيهِمۡ تِجَٰرَةٞ وَلَا بَيۡعٌ عَن ذِكۡرِ ٱللَّهِ وَإِقَامِ ٱلصَّلَوٰةِ وَإِيتَآءِ ٱلزَّكَوٰةِ يَخَافُونَ يَوۡمٗا تَتَقَلَّبُ فِيهِ ٱلۡقُلُوبُ وَٱلۡأَبۡصَٰرُ 37
Awọn ọkunrin ti tita rira kii mu igbagbe ba wọn nipa iranti Allah ti mimọ nbẹ fun ati kiki irun ni ojupọnna ti o pe ati mimu saka jade si awọn aaye ti o yẹ, wọn nbẹru ọjọ igbende, ọjọ naa eyiti awọn ọkan yoo maa daamu laarin rirankan ọla kuro nibi iya ati bibẹru rẹ, awọn oju yoo si maa daamun lọ si eyikeyi abala ti o ba lọ.
لِيَجۡزِيَهُمُ ٱللَّهُ أَحۡسَنَ مَا عَمِلُواْ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضۡلِهِۦۗ وَٱللَّهُ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ 38
Wọn se eleyi ki Allah le san wọn lẹsan lori isẹ wọn eyiti o dara ju ninu ohun ti wọn se, ki o si le se alekun ninu ọla Rẹ ni ẹsan fun wọn, Allah jẹ alarnse fun ẹniti o ba wu U ni ohun ti ko ni odiwọn ni ibamun si deede isẹ wọn, koda yoo tun fun wọn ni adipele ohun ti wọn se.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَعۡمَٰلُهُمۡ كَسَرَابِۢ بِقِيعَةٖ يَحۡسَبُهُ ٱلظَّمَۡٔانُ مَآءً حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَهُۥ لَمۡ يَجِدۡهُ شَيۡٔٗا وَوَجَدَ ٱللَّهَ عِندَهُۥ فَوَفَّىٰهُ حِسَابَهُۥۗ وَٱللَّهُ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 39
Awọn ti wọn se keferi si Allah ko si ẹsan fun isẹ ti wọn se, wọn da gẹgẹ bi anpeena ni rọọlẹ ilẹ, ti olugbẹngbẹ nwo o, ti o si ro wipe omin ni, ti o wa lọ sibẹ, nigbati o debẹ ti o si duro sibẹ, ko ri omin kankan, gẹgẹ bẹẹ naa ni keferi ti o lero wipe isẹ oun yoo se oun ni anfaani titi ti o fi ku, ti wọn si gbe dide ti ko wa ri ẹsan rẹ, o wa ri Ọlọhun Ọba rẹ ni iwaju rẹ, ti o si pe isiro isẹ rẹ fun ni pipe, Allah jẹ oluyara ni isiro.
أَوۡ كَظُلُمَٰتٖ فِي بَحۡرٖ لُّجِّيّٖ يَغۡشَىٰهُ مَوۡجٞ مِّن فَوۡقِهِۦ مَوۡجٞ مِّن فَوۡقِهِۦ سَحَابٞۚ ظُلُمَٰتُۢ بَعۡضُهَا فَوۡقَ بَعۡضٍ إِذَآ أَخۡرَجَ يَدَهُۥ لَمۡ يَكَدۡ يَرَىٰهَاۗ وَمَن لَّمۡ يَجۡعَلِ ٱللَّهُ لَهُۥ نُورٗا فَمَا لَهُۥ مِن نُّورٍ 40
Abi ki a sọpe awọn isẹ wọn da gẹgẹ bi okunkun inu odo ti o jin, ti agbara miran tun wa loke rẹ, ni oke eleyi agbara miran tun wa nibẹ, ni oke rẹ ẹsujo ti o bo o eyiti eniyan le fi mọ ọna ninu irawọ wa nibẹ, awọn okunkun ti apakan wọn gbe ra wọn pọn loke ara wọn, ti ẹniti o ba bọ sinu okunkun yii ba na ọwọ rẹ jade, ko nii fẹ le ri ọwọ naa nitori ninipọn okunkun naa, bayi gẹgẹ ni keferi jẹ, paapa awọn okunkun aimọkan, iyemeji, idaamun, edidi ọkan rẹ ti gbe ara wọn pọn le lori, ẹniti Allah ko ba se aranse ọnọọmọ kuro nibi anu fun un ati ki o nimọ nipa tira rẹ, ko si imọna kankan fun un ti yoo fi mọ ọna, bẹẹni ko si iwe kankan ti yoo fun un ni imọlẹ.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُسَبِّحُ لَهُۥ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱلطَّيۡرُ صَٰٓفَّٰتٖۖ كُلّٞ قَدۡ عَلِمَ صَلَاتَهُۥ وَتَسۡبِيحَهُۥۗ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِمَا يَفۡعَلُونَ 41
Se o ko mọ ni - irẹ ojisẹ - dajudaju ohun ti nbẹ ni sanmọ nse afọmọ fun Allah, bẹẹni awọn ẹda ti o wa lori ilẹ naa nse afọmọ fun Un, awọn ẹyẹ naa nse afọmọ fun Un, pataki julọ nigbati wọn ba nto iyẹ wọn ninu atẹgun, gbogbo awọn ẹda wọnyi ni Allah fi imọ irun kiki Rẹ mọ ọ, ti yoo maa ki gẹgẹ bi eniyan ati afọmọ ti yoo maa se gẹgẹ bi ẹyẹ, Allah si jẹ onimimọ pẹlu ohun ti wọn nse, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ wọn.
وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ 42
Ikapa sanmọ ati ikapa ilẹ jẹ ti Allah nikan soso, ọdọ Rẹ nikan soso ni isẹrisi ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُزۡجِي سَحَابٗا ثُمَّ يُؤَلِّفُ بَيۡنَهُۥ ثُمَّ يَجۡعَلُهُۥ رُكَامٗا فَتَرَى ٱلۡوَدۡقَ يَخۡرُجُ مِنۡ خِلَٰلِهِۦ وَيُنَزِّلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن جِبَالٖ فِيهَا مِنۢ بَرَدٖ فَيُصِيبُ بِهِۦ مَن يَشَآءُ وَيَصۡرِفُهُۥ عَن مَّن يَشَآءُۖ يَكَادُ سَنَا بَرۡقِهِۦ يَذۡهَبُ بِٱلۡأَبۡصَٰرِ 43
Se o ko mọ ni - irẹ ojisẹ - dajudaju Allah ni O ndari ẹsu ojo, lẹyin naa ni yoo gbe awọn abala kan lori abala miran, lẹyin naa yoo sọ wọn di ohun ti yoo gbe ara wọn pọn, ti apakan yoo gun apakan, iwọ yoo waa ri ojo ti yoo jade ni ọgbungbun ẹsu ojo, yoo waa maa sọ egikan ti o ti di ninu omin gẹgẹ bi okuta kalẹ ni abala sanmọ ninu ẹsu ojo eyiti o nipọn ti o wa nibẹ, ti o jọ oke nibi titobi rẹ, yoo mu otutu ba ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ ninu eleyi, yoo wa fẹ si ẹni ti o ba wu U ninu wọn, imọlẹ mọnamọna ẹsu ojo naa nibi lilagbara kikọyanran rẹ fẹẹ le mu iriran lọ.
Sise osunwọn olugbagbọ ododo laarin idaamun ile aye ati isẹ ti ọrun jẹ alamọri ti o di dandan.
Jijẹ ibajẹ isẹ keferi nitori sise afẹku majẹmu igbagbọ.
Dajudaju keferi jẹ ẹniti o yẹ kuro ninu awọn ẹda Allah eyiti o nse afọm, ti o si ntẹle asẹ.
Gbogbo ipele ojo wa ninu ẹda Allah ati odiwọn Rẹ.