وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٖ 36
Ko si ounjẹ ti o le jẹ fun un ayaafi ẹfunfun ara awọn ẹni ina.
لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطُِٔونَ 37
Ẹni kan ko nii jẹ ounjẹ naa ayaafi awọn ẹlẹsẹ ati alasise.
فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ 38
Allah fi ohun ti ẹ nri bura.
وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ 39
O si tun fi ohun ti ẹ ko ri bura.
إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٖ كَرِيمٖ 40
Dajudaju Alukuraani jẹ ọrọ Allah, ojisẹ Rẹ alapọnle ka a fun awọn eniyan.
وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٖۚ قَلِيلٗا مَّا تُؤۡمِنُونَ 41
Kii se ọrọ olorin; toripe ko wa lori eto orin, o kere nigbati ẹ nigbagbọ.
وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٖۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ 42
Kii si se ọrọ alagbegba, ọrọ alagbegba jẹ alamọri ti o kọyin si Alukuraani yii, o kere nigbati ẹ nse iranti.
تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 43
Sugbọn o jẹ ohun ti o sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba gbogbo lapapọ.
وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ 44
Ti Muhammad ba sọ fun wa apakan awọn awawi eyiti a ko wi.
لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ 45
A ko ba gba ẹsan lara rẹ, a ko ba si gba a muni lile pẹlu agbara lati ọdọ wa.
ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ 46
Lẹyin naa a ko ba ja isan eyiti o so mọ ọkan rẹ.
فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ 47
Ko si ninu yin ẹniti o le kọ fun wa kuro nibẹ, o jinna si eyesọ fun nitori ti yin.
وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٞ لِّلۡمُتَّقِينَ 48
Atipe dajudaju Alukuraani jẹ isiti fun awọn olubẹru Ọlọhun wọn pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati ijinna si awọn ohun ti o kọ.
وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ 49
Atipe dajudaju awa ni a mọ ẹniti o npe Alukuraani yii nirọ ninu yin.
وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ 50
Atipe dajudaju pipe Alukuraani nirọ jẹ abamọ ti o tobi ni ọjọ igbende.
وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ 51
Atipe dajudaju Alukuraani jẹ ododo ti o daju, ti ko si royiroyi tabi iyemeji wipe o wa lati ọdọ Allah.
فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ 52
Ki o se afọmọ - irẹ ojisẹ - Ọlọhun rẹ kuro nibi ohun ti ko lẹtọ si I, ki o si ranti orukọ Ọlọhun rẹ ti o tobi.
سورة (MAKIYYAH)
Sisalaye isesi ati ẹsan ẹda ni ọjọ igbende.
سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ 1
Ẹlẹbọ kan ninu olupepe sepe lori ẹmin rẹ ati awọn ijọ rẹ nipa iya ti o ba jasi pe iya naa yoo sẹlẹ, o si jẹ yẹyẹ lati ọdọ rẹ, yoo sẹlẹ ni ọjọ igbende.
لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ 2
Ko si fun ijiya naa ẹniti yoo da a pada fun awọn ti wọn se keferi si Allah.
مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ 3
Lati ọdọ Allah Ẹniti o ga, ti O si ni awọn ipo ati awọn ọla ati awọn idẹkun.
تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ 4
Awọn Malaika ati Jibril ngoke si ọdọ Rẹ nibi awọn agbega yii ni ọjọ igbende; ohun si ni ọjọ ti o gun, ti odiwọn rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọta ọdun.
فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا 5
Ki o se suuru - irẹ ojisẹ - ni suuru ti ko si ikanra tabi aroye nibẹ.
إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا 6
Dajudaju wọn ri iya yii ni ohun ti o jinna, ti ko le sẹlẹ lailai.
وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا 7
Awa si nri ni ohun ti o sun mọ, ti yoo sẹlẹ, ti ko si ibuyẹ.
يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ 8
Ọjọ ti sanmọ yoo da gẹgẹ bi ẹyọ oje ati wura ati ohun ti o yatọ si mejeeji.
وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ 9
Ti oke yoo si da gẹgẹ bi owu nibi fifuyẹ.
وَلَا يَسَۡٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا 10
Ti alasunmọ kan ko nii le bi alasunmọ miran leere nipa isesi rẹ; nitoripe gbogbo ẹni kọọkan ni yoo ko airoju pẹlu ẹmin rẹ.
Mimọ Alukuraani kuro nibi orin ati agbegba.
Ewu ayesọ nipa Allah ati adapa irọ mọ Ọ ti mimọ nbẹ fun.
Suuru ti o rẹwa eyiti eniyan le ri ẹsan nibẹ ni ọdọ Allah, ti wọn kii saroye rẹ fun ẹlomiran.