وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هُمۡ أَشَدُّ مِنۡهُم بَطۡشٗا فَنَقَّبُواْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ هَلۡ مِن مَّحِيصٍ 36
Melo ni onka awọn ijọ ti a ti parun siwaju awọn ẹlẹbọ opurọ yii ninu awọn ara Mẹkkah, ti wọn le juwọn lọ niti agbara, wọn wa bẹrẹ si nii se ọfintoto nilu boya wọn yoo ri ibusalọ kuro nibi iya naa sugbọn wọn ko ri i.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكۡرَىٰ لِمَن كَانَ لَهُۥ قَلۡبٌ أَوۡ أَلۡقَى ٱلسَّمۡعَ وَهُوَ شَهِيدٞ 37
Dajudaju nibi nkan ti a sọ yii nipa pipa awọn ijọ ti o ti re kọja lọ, paapaa o jẹ iranileti ati isiti fun ẹniti o ba ni ọkan ti o nse laakaye pẹlu rẹ tabi o dakẹ pẹlu eti sugbọn ti ọkan rẹ wa ni tosi, ti kii se afọnu.
وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ وَمَا مَسَّنَا مِن لُّغُوبٖ 38
Paapaa a si ti da gbogbo sanmọ, a si tun da ilẹ, a si da gbogbo ohun ti o wa ni aarin gbogbo sanmọ ati ilẹ; ni ọjọ mẹfa pẹlu lilagbara Wa lati sẹda Rẹ ni isẹju akan, irẹwẹsi kan ko si ba wa gẹgẹ bi yahuudi se sọ.
فَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ قَبۡلَ طُلُوعِ ٱلشَّمۡسِ وَقَبۡلَ ٱلۡغُرُوبِ 39
Ki o se suuru - irẹ ojisẹ - lori ohun ti yahuudi nsọ ati ẹniti o yatọ si wọn, ki o si kirun fun Ọlọhun Ọba rẹ ni ẹniti yoo maa dupẹ fun, irun idaji siwaju yiyọ oorun, ki o si ki irun irọlẹ siwaju wiwọ rẹ.
وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡهُ وَأَدۡبَٰرَ ٱلسُّجُودِ 40
Ni oru ki o tun kirun fun Un, ki o si afọmọ Rẹ lẹyin awọn irun.
وَٱسۡتَمِعۡ يَوۡمَ يُنَادِ ٱلۡمُنَادِ مِن مَّكَانٖ قَرِيبٖ 41
Ki o si tẹti gbọ - irẹ ojisẹ - ọjọ ti malaika ti a la fifan fere si inu iwo yoo pepe ni fifan ẹlẹẹkeji ni aaye ti o sun mọ.
يَوۡمَ يَسۡمَعُونَ ٱلصَّيۡحَةَ بِٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكَ يَوۡمُ ٱلۡخُرُوجِ 42
Ni ọjọ ti awọn ẹda yoo gbọ igbe ajinde pẹlu ododo eyiti ko si iyemeji nibẹ, ọjọ ti ẹ gbọ yii ni ọjọ ti awọn oku yoo jade ninu awọn saare wọn fun isiro ati ẹsan.
إِنَّا نَحۡنُ نُحۡيِۦ وَنُمِيتُ وَإِلَيۡنَا ٱلۡمَصِيرُ 43
Dajudaju Awa ni a nji oku, ni a si npa a, ko si olujini yatọ si Wa bẹẹni ko si olupani, ọdọ wa nikan si ni isẹrisi awọn ẹru ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
يَوۡمَ تَشَقَّقُ ٱلۡأَرۡضُ عَنۡهُمۡ سِرَاعٗاۚ ذَٰلِكَ حَشۡرٌ عَلَيۡنَا يَسِيرٞ 44
Ni ọjọ ti ilẹ yoo lanu fun wọn, yoo maa jade ni yarayara, ikojọ yii jẹ ohun ti o rọrun fun wa.
نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَقُولُونَۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِجَبَّارٖۖ فَذَكِّرۡ بِٱلۡقُرۡءَانِ مَن يَخَافُ وَعِيدِ 45
Awa jẹ ẹniti o nimọ ju nipa ohun ti awọn opurọ yii nsọ, iwọ kii se - irẹ ojisẹ - ẹniti a fi jẹ gaba le wọn lori, ti o wa fi jẹ wọn nipa lori igbagbọ bikosepe iwọ jẹ olumudetigbọ ohun ti Allah pa ọ lasẹ ki o mudetigbọ rẹ, ki o si fi Alukuraani se iranti fun ẹniti o npaya adehun iya Mi fun awọn keferi ati awọn ẹlẹsẹ; nitoripe ẹniti o npaya ni yoo gba isiti, ni yoo si se iranti nigbati wọn ba ran leti.
سورة (MAKIYYAH)
Mimu awọn aljannu ati eniyan mọ wipe ipilẹ arisiki wọn lati ọdọ Allah nikan ni o ti nwa, ki wọn le ma se afomo ijosin fun Un.
وَٱلذَّٰرِيَٰتِ ذَرۡوٗا 1
Allah bura pẹlu atẹgun eyiti o ma nfẹ yerupẹ.
فَٱلۡحَٰمِلَٰتِ وِقۡرٗا 2
Ati pẹlu awọn ẹsujo eyiti o ma ngbe omin ti o pọ dani.
فَٱلۡجَٰرِيَٰتِ يُسۡرٗا 3
Ati pẹlu awọn ọkọ oju omin eyiti o nri ni inu omin pẹlu irọrun ati idẹkun.
فَٱلۡمُقَسِّمَٰتِ أَمۡرًا 4
Ati pẹlu awọn malaika eyiti o npin ohun ti Allah pa wọn lasẹ pinpin rẹ ninu alamọri awọn ẹru.
إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٞ 5
Dajudaju ohun ti Ọlọhun Ọba yin se ni adehun fun yin ni isiro ati ẹsan jẹ ododo ti ko si iyemeji nibẹ.
وَإِنَّ ٱلدِّينَ لَوَٰقِعٞ 6
Atipe dajudaju isiro ẹru yoo sẹlẹ ni ọjọ igbende ko si ibuyẹ.
Sise ariwoye pẹlu isẹlẹ awọn asiko jẹ isesi awọn ọlọkan ti o ni akiyesi.
Dida ti Allah da aye ni ọjọ mẹfa jẹ awọn ọgbọn kan ti Allah nikan mọ, o seese ki o jẹpe ninu rẹ ni sise alaye isesi igbesẹ kan lẹyin igbesẹ.
Aidara ẹkọ yahuudi nibi riroyin Allah ti o ga pẹlu rirẹ lẹyin sisẹda gbogbo sanmọ ati ilẹ Rẹ, eleyi si jẹ aimoore si Allah.