فَلَمَّا جَآءَهُم مُّوسَىٰ بَِٔايَٰتِنَا بَيِّنَٰتٖ قَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّفۡتَرٗى وَمَا سَمِعۡنَا بِهَٰذَا فِيٓ ءَابَآئِنَا ٱلۡأَوَّلِينَ 36
Nigbati Musa ẹniti ọla nbẹ fun mu awọn amin Wa wa ba wọn ni ohun ti o fi oju han, wọn sọpe: eleyi ko jẹ nkankan ju irọ adapa ti Musa hun jọ lọ, awa ko gbọ eleyi ni ọdọ awọn baba wa ti o siwaju.
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّيٓ أَعۡلَمُ بِمَن جَآءَ بِٱلۡهُدَىٰ مِنۡ عِندِهِۦ وَمَن تَكُونُ لَهُۥ عَٰقِبَةُ ٱلدَّارِۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّٰلِمُونَ 37
Musa sọ ni ẹniti o ndajukọ fir'aona: Ọlọhun Ọba mọ ẹniti o lẹtọ lati mu itọsọna wa ni ọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun, O si mọ ẹniti igbẹyin daadaa yoo jẹ ti rẹ lọrun, dajudaju awọn alabosi ko le jere pẹlu ohun ti wọn nfẹ, wọn ko si le la kuro nibi ohun ti wọn bẹru.
وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ مَا عَلِمۡتُ لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرِي فَأَوۡقِدۡ لِي يَٰهَٰمَٰنُ عَلَى ٱلطِّينِ فَٱجۡعَل لِّي صَرۡحٗا لَّعَلِّيٓ أَطَّلِعُ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 38
Fir'aona sọ ni ẹniti nba awọn ẹni iyi ninu ijọ rẹ sọrọ: ẹyin ijọ, nko mọ ẹniti ijọsin fun kan yatọ si mi fun yin, irẹ hamana, danọ mọ amọ ti yoo lagbara ki o fi kọ ile kan ti yoo ga fun mi, ki nle gboju wo ẹniti Musa nsin, ki nsi da a mọ, dajudaju emi lero wipe Musa jẹ opurọ nibi ohun ti npe apemọra rẹ wipe ohun jẹ ẹniti a nransẹ si mi ati si awọn ijọ mi.
وَٱسۡتَكۡبَرَ هُوَ وَجُنُودُهُۥ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ إِلَيۡنَا لَا يُرۡجَعُونَ 39
Igberaga fir'aona wa le si atia ijọ rẹ, wọn si nse igberaga lori ilẹ misira laini ẹtọ, wọn si tako igbende, bẹẹni wọn lero pe awọn ko ni sẹri si ọdọ wa ni ọjọ igbende fun isiro ati iya.
فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلظَّٰلِمِينَ 40
A si gba a mu, bẹẹni a gba awọn ọmọ ogun rẹ mu, a si ju wọn sinu odo ti yoo tẹ wọn ri ki wọn parun lapapọ, ki o ya ronu - irẹ ojisẹ - si bi igbẹyin awọn alabosi ati opin wọn se ri, paapaa igbẹyin wọn ati opin wọn jẹ iparun.
وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَئِمَّةٗ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلنَّارِۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا يُنصَرُونَ 41
A si se wọn ni awokọse fun awọn olukọja ẹnu aala ati awọn ẹni anu ti wọn npepe lọ si ibi ina pẹlu ohun ti wọn ntan kalẹ ni keferi ati anu, ti o ba di ọjọ igbende wọn ko nii ri alaranse ti yoo yọ wọn kuro nibi iya, bikosepe wọn yoo se adipele iya le wọn lori nitori afilelẹ ọna aburu ti wọn fi lelẹ, wọn si tun pepe si i niti anu, wọn yoo kọ ẹsẹ isẹ wọn le wọn lori ati ẹsẹ ẹniti o ba tẹle wọn ninu isẹ.
وَأَتۡبَعۡنَٰهُمۡ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ هُم مِّنَ ٱلۡمَقۡبُوحِينَ 42
A si tun se alekun lori iya wọn ni ile aye yii lori itiju ati ilenisa, ti o ba di ọjọ igbende wọn yoo wa ninu ẹni eebu ti a le jinna kuro nibi ikẹ Allah.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِ مَآ أَهۡلَكۡنَا ٱلۡقُرُونَ ٱلۡأُولَىٰ بَصَآئِرَ لِلنَّاسِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لَّعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ 43
Paapaa a ti fun Musa ni taoreeta lẹyin igba ti a ti ransẹ si awọn ijọ ti o ti siwaju, wọn si pe awọn ojisẹ wa nirọ, a pa wọn run nitori pipe wọn nirọ, o wa nibẹ ohun ti awọn eniyan le fi oju ri ninu ohun ti o le se wọn ni anfaani ti wọn si nse e tabi ohun ti o le ko inira ba wọn ti wọn si ngbe e ju silẹ, bẹẹni itọsọna lọ si ibi rere fun wọn naa wa nibẹ ati ikẹ ti oore aye ati ti ọrun naa wa nibẹ, o seese ki wọn ronu si idẹkun Allah le wọn lori ki wọn si dupẹ fun Un, ki wọn si nigbagbọ si I.
Fifi ohun ti o jọ iruju fesi pada fun ododo jẹ isesi awọn olukọja ẹnu aala.
Igberaga ma nkọ fun ni lati tẹle ododo.
Biburu igbẹyin awọn olusegberaga jẹ isesi Ọlọhun Ọba olutọju Agbanla aye.
Ibajẹ ni awọn asiwaju ati awọn olupepe si i ati aworan rẹ ati awọn amin rẹ.