فَلَمَّا جَآءَ سُلَيۡمَٰنَ قَالَ أَتُمِدُّونَنِ بِمَالٖ فَمَآ ءَاتَىٰنِۦَ ٱللَّهُ خَيۡرٞ مِّمَّآ ءَاتَىٰكُمۚ بَلۡ أَنتُم بِهَدِيَّتِكُمۡ تَفۡرَحُونَ 36
Nigbati ojisẹ wa ati awọn ti o wa pẹlu rẹ ninu awọn olukunlọwọ rẹ ti wọn gbe ẹbun fun sulyman, Sulayman korira fifi ẹbun ransẹ ni ẹniti o sọ wipe: se ẹ o maa fi awọn dukia tan mi jẹ ni, ki ẹ le tẹri mi si yin, ohun ti Ọlọhun Ọba Allah fun mi ninu jijẹ anọbi, ọla ati dukia loore ju ohun ti ẹ mu wa lọ, bikosepe ẹyin ni ẹ ma nyọ pẹlu ohun ti wọn ba bun yin ninu oore ile aye.
ٱرۡجِعۡ إِلَيۡهِمۡ فَلَنَأۡتِيَنَّهُم بِجُنُودٖ لَّا قِبَلَ لَهُم بِهَا وَلَنُخۡرِجَنَّهُم مِّنۡهَآ أَذِلَّةٗ وَهُمۡ صَٰغِرُونَ 37
Sulayman ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun ojisẹ rẹ: sẹri pada si ọdọ wọn pẹlu ohun ti o mu wa ni ẹbun ki a le lọ ba a ati awọn ijọ rẹ pẹlu awọn ọmọ ogun ti ikapani wọn ko le da oju wọn ati mki a le mu wọn jade kuro ni sabahi ni ẹni yẹpẹrẹ lẹyin igbati ti wọn ti jẹ ẹni iyi ti wọn ko ba le wa ba mi ni ẹni itẹriba.
قَالَ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَؤُاْ أَيُّكُمۡ يَأۡتِينِي بِعَرۡشِهَا قَبۡلَ أَن يَأۡتُونِي مُسۡلِمِينَ 38
Sulayman ti ọla nbẹ fun sọ ni ẹniti o dojukọ awọn asoju ọla rẹ: ẹyin ijọ naa, taani o le mu wa fun mi ibusun ọla rẹ, ki wọn o to waa ba mi ni ẹni itẹriba?
قَالَ عِفۡرِيتٞ مِّنَ ٱلۡجِنِّ أَنَا۠ ءَاتِيكَ بِهِۦ قَبۡلَ أَن تَقُومَ مِن مَّقَامِكَۖ وَإِنِّي عَلَيۡهِ لَقَوِيٌّ أَمِينٞ 39
Maridu da lohun ninu awọn alujannu ni ẹniti o sọpe: emi yoo mu ibusun rẹ wa siwaju ki o to dide ni ijoko rẹ yii ti o wa lori rẹ, dajudaju emi jẹ alagbara lati gbe e, ẹni ifọkantan lori ohun ti o wa ninu rẹ, nko ni din nkankan ku nibẹ.
قَالَ ٱلَّذِي عِندَهُۥ عِلۡمٞ مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ أَنَا۠ ءَاتِيكَ بِهِۦ قَبۡلَ أَن يَرۡتَدَّ إِلَيۡكَ طَرۡفُكَۚ فَلَمَّا رَءَاهُ مُسۡتَقِرًّا عِندَهُۥ قَالَ هَٰذَا مِن فَضۡلِ رَبِّي لِيَبۡلُوَنِيٓ ءَأَشۡكُرُ أَمۡ أَكۡفُرُۖ وَمَن شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشۡكُرُ لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّي غَنِيّٞ كَرِيمٞ 40
Ọkunrin ẹniire onimimọ lọdọ sulyman sọpe: imọ tira wa lọdọ rẹ, ninu rẹ si orukọ Allah ti o tobi eyiti wọn ba pe E pẹlu Rẹ yoo jẹpe: emi yoo mu ibusun naa wa siwaju ki o to sẹju rẹ; pẹlu ki npe Allah ki o si mu u wa, o si pe E, Allah si da a lohun lori ipepe rẹ, nigbati Sulayman ri ibusun rẹ ti o balẹ ni ọdọ rẹ, o sọpe: eleyi jẹ ọla Ọlọhun Ọba mi ti mimọ nbẹ fun; lati dan mi wo boya emi yoo dupẹ idẹkun tabi se aimoore si I? ẹniti o ba dupẹ fun Allah dajudaju anfaani ọpẹ rẹ yoo sẹri si i, Allah jẹ Abọrọ ti ọpẹ ẹru ko le le E kun, ẹniti o ba si ja idẹkun Allah niyan ti ko dupẹ fun Un, dajudaju Ọlọhun mi jẹ abọrọ, ọlọrẹ kuro nibi ọpẹ rẹ, ninu ọrẹ Rẹ ohun ti ki O ma se ọla fun ẹniti o nja A niyan.
قَالَ نَكِّرُواْ لَهَا عَرۡشَهَا نَنظُرۡ أَتَهۡتَدِيٓ أَمۡ تَكُونُ مِنَ ٱلَّذِينَ لَا يَهۡتَدُونَ 41
Sulayman - ẹniti ọla nbẹ fun - sọpe: ẹ yi ibusun ọla rẹ pada kuro ni isesi ti o wa, ti a nwo: boya yoo le mọna wipe ibusun ohun ni tabi yoo wa ninu ẹniti ko nii mọna lọ si ibi awọn nkan rẹ?
فَلَمَّا جَآءَتۡ قِيلَ أَهَٰكَذَا عَرۡشُكِۖ قَالَتۡ كَأَنَّهُۥ هُوَۚ وَأُوتِينَا ٱلۡعِلۡمَ مِن قَبۡلِهَا وَكُنَّا مُسۡلِمِينَ 42
Nigbati ọba sabahi de si ọdọ Sulayman, wọn sọ fun niti didan an wo: njẹ eleyi jẹ iru aga rẹ bi? O si dahun ni ibamun si ibeere, o da gẹgẹ bii rẹ, Sulayman waa sọpe: Ọlọhun Allah ti fun ni imọ siwaju rẹ lati lagbara lori iru alamọri yii, a si jẹ ẹniti o tẹriba fun asẹ Allah niti titẹle E.
وَصَدَّهَا مَا كَانَت تَّعۡبُدُ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ إِنَّهَا كَانَتۡ مِن قَوۡمٖ كَٰفِرِينَ 43
O si yi kuro nibi ọkan soso Allah ohun ti o nsin yatọ si Allah niti titẹle awọn ijọ rẹ ati kikọ se wọn, dajudaju o jẹ ninu ijọ ti o se keferi si Allah, oun naa si di keferi gẹgẹ bi wọn.
قِيلَ لَهَا ٱدۡخُلِي ٱلصَّرۡحَۖ فَلَمَّا رَأَتۡهُ حَسِبَتۡهُ لُجَّةٗ وَكَشَفَتۡ عَن سَاقَيۡهَاۚ قَالَ إِنَّهُۥ صَرۡحٞ مُّمَرَّدٞ مِّن قَوَارِيرَۗ قَالَتۡ رَبِّ إِنِّي ظَلَمۡتُ نَفۡسِي وَأَسۡلَمۡتُ مَعَ سُلَيۡمَٰنَ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 44
Wọn sọ fun: wọ inu aafin, o si da gẹgẹ bi ilẹ pẹrẹsẹ, nigbati o ri i, o le ro wipe omin ni, o si ojugun rẹ lati tẹ ẹsẹ bọ ọ, Sulayman ẹniti ọla nbẹ fun wa sọpe: dajudaju aafin ti a fi dingi bo nii se, o wa pe e sinu Islam, o si da a lohun nibi ohun ti o pe e si ni ẹniti o sọpe: Ọlọhun Ọba mi, dajudaju emi ti se abosi si ẹmi ara mi nibi sinsin ohun ti o yatọ si Ọ pẹlu Rẹ, mo si tẹriba pẹlu Sulayman fun Allah olutọju gbogbo ẹda lapapọ.
Iyi ti nbẹ fun igbagbọ nibi didaabobo olugbagbọ ododo lati mase lapa pẹlu ọrọ ile aye.
Yiyọ pẹlu awọn dukia aye ati gbigbara le e jẹ iroyin kan ninu iroyin awọn keferi.
Titaji ifuramọ olugbagbọ ododo si idẹkun Allah.
Didan ọpọlọ ẹniti a nbaa ja wo nibi gbigbero bibaa se pọ pẹlu ohun ti ol ba a mu.
Ihan gbigbawaju lori ẹniti a nbaa ja nitori ilapa ti o wa nibẹ.