وَدَخَلَ جَنَّتَهُۥ وَهُوَ ظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ قَالَ مَآ أَظُنُّ أَن تَبِيدَ هَٰذِهِۦٓ أَبَدٗا 35
Keferi wọ inu ọgba rẹ nibi biba olugbagbọ ododo se papọ ki o le fi han an sugbọn o jẹ ẹniti o se abosi ẹmin ara rẹ pẹlu sise keferi ati moto-moto, kekeri sọpe: nko lero wipe ọgba yii le tan eyiti o nwo yii; nitori awọn okunfa isẹku ti mo ti se.
وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّدِدتُّ إِلَىٰ رَبِّي لَأَجِدَنَّ خَيۡرٗا مِّنۡهَا مُنقَلَبٗا 36
Bẹẹni nko lero wipe igbende yoo sẹlẹ dajudaju isẹmin gbere ni o jẹ nibi didandan sisẹlẹ rẹ ti wọn ba si gbemi dide, ti wọn tun sẹri mi lọ si ọdọ Ọlọhun mi, paapaa maa ri ibi ti maa sẹri si lẹyin igbende ninu ohun ti o lọla ju ọgba mi yii lọ, ki o ya maa jẹ ọlọrọ ni ile aye, ti emi yoo si maa jẹ ọlọrọ lẹyin igbende.
قَالَ لَهُۥ صَاحِبُهُۥ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَكَفَرۡتَ بِٱلَّذِي خَلَقَكَ مِن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ سَوَّىٰكَ رَجُلٗا 37
Olugbagbọ ododo ti o jẹ ẹniirẹ sọ fun, o si nsẹri ọrọ rẹ pada si: se iwọ yoo se keferi si ẹniti o da baba rẹ Aadamọ lati ibi yẹpẹ, lẹyin naa ti o si tun iwọ naa lati ibi atọ, lẹyin igba naa ti o sọ ọ di ọmọniyan ti o jẹ akọ, o si sọ orikerike rẹ di dọgbandọgba, o si tun se ọ ni pipe, ẹniti o lagbara lori eleyi patapata jẹ ẹniti o lagbara lori gbigbe ọ dide.
لَّٰكِنَّا۠ هُوَ ٱللَّهُ رَبِّي وَلَآ أُشۡرِكُ بِرَبِّيٓ أَحَدٗا 38
Sugbọn emi ko nii sọ pẹlu gbolohun rẹ yii dajudaju ohun ti emi yoo sọ nipe: Ọlọhun Allah ti mimọ nbẹ fun ni Ọlọhun mi, Oluse ọla pẹlu idẹkun Rẹ le wa lori, emi ko nii mu ẹnikankan pẹlu Rẹ nibi ijọsin.
وَلَوۡلَآ إِذۡ دَخَلۡتَ جَنَّتَكَ قُلۡتَ مَا شَآءَ ٱللَّهُ لَا قُوَّةَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ إِن تَرَنِ أَنَا۠ أَقَلَّ مِنكَ مَالٗا وَوَلَدٗا 39
Bẹẹni nigbati o wọ inu ọgba rẹ, o sọ wipe: bi Ọlọhun Ọba se fẹ, ko si agbara ayaafi pẹlu Allah, Ohun ni ẹniti O nse bi o se wu U, Ohun si ni Alagbara, ti o ba jasi wipe o ri mi ni ẹniti ko lowo to ọ, ti ko si ni ọmọ to ọ.
فَعَسَىٰ رَبِّيٓ أَن يُؤۡتِيَنِ خَيۡرٗا مِّن جَنَّتِكَ وَيُرۡسِلَ عَلَيۡهَا حُسۡبَانٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَتُصۡبِحَ صَعِيدٗا زَلَقًا 40
Emi nrankan ki Ọlọhun Allah fun mi ni eyiti o loore ju ọgba rẹ lọ, ki O si gbe iya dide lati sanmọ si inu ọgba rẹ, ki ọgba rẹ le di ilẹ ti ko nii si irugbin nibẹ, ti awọn gigisẹ yoo maa lapa nibẹ nitori titẹlọ titẹbọ.
أَوۡ يُصۡبِحَ مَآؤُهَا غَوۡرٗا فَلَن تَسۡتَطِيعَ لَهُۥ طَلَبٗا 41
Tabi ki O mu omin rẹ kuro ti yoo gbẹ ninu ilẹ, ti ẹnikankan ko nii le de ibẹ pẹlu atẹgun, ti omi bẹ ba si ti gbẹ, ibẹ ko nii sẹku mọ.
وَأُحِيطَ بِثَمَرِهِۦ فَأَصۡبَحَ يُقَلِّبُ كَفَّيۡهِ عَلَىٰ مَآ أَنفَقَ فِيهَا وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُشۡرِكۡ بِرَبِّيٓ أَحَدٗا 42
Ounti olugbagbọ ododo naa si nfe si di ododo, bayi ni iparun bo irugbin ọgba keferi naa, bayi ni keferi waa di ẹniti o npatẹwọ nitori ofo ati abamọ ti o le koko ti o ti na lori sisẹmin ayika ati sise atunse awọn dukia rẹ, ọgba naa si subu pẹlu opo rẹ eyiti awọn ẹka igi inabi nna mọ, o wa sọpe: kilo semi ti emi ko nigbagbọ si ọkansoso Ọlọhun mi, ti emi nko si mu lọkan soso nibi ijọsin.
وَلَمۡ تَكُن لَّهُۥ فِئَةٞ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا 43
Ko si si fun keferi yii ijọ ti yoo kọ iya fun nibi ohun ti o sẹlẹ si ninu iya, oun si ni ẹniti o nse iyanran pẹlu ijọ rẹ, ko si ni ohun ti o le kọ fun nibi iparun Ọlọhun si ọgba rẹ.
هُنَالِكَ ٱلۡوَلَٰيَةُ لِلَّهِ ٱلۡحَقِّۚ هُوَ خَيۡرٞ ثَوَابٗا وَخَيۡرٌ عُقۡبٗا 44
Nibi isẹlẹ yii aranse jẹ ti Allah nikan soso, Oun nikan ti mimọ nbẹ fun ni O loore ni ẹsan fun awọn ẹniiRẹ ninu awọn olugbagbọ ododo, Oun ni yoo si se adipele ẹsan fun wọn, bẹẹni igbẹyin ti o loore ju nbẹ fun wọn.
وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَآءٍ أَنزَلۡنَٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخۡتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلۡأَرۡضِ فَأَصۡبَحَ هَشِيمٗا تَذۡرُوهُ ٱلرِّيَٰحُۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ مُّقۡتَدِرًا 45
Ki o si fi apejuwe lelẹ pẹlu awọn ti wọn ngba itanjẹ pẹlu aye, - irẹ ojisẹ - ninu rẹ ni yiyẹ rẹ ati yiyara tete tan gẹgẹ b omin ojo ti a sọkalẹ ni sanmọ, ti irugbin ile si ti ara omin yii jade, ti o si pọn, ti awọn irugbin yii di ohun ti o gbẹ, ti o run, ti atẹgun si bẹrẹ si gbe apakan rẹ lọsi abala miran, bakanna ni ile si sẹri bi o ti wa tẹlẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olupebubu lori gbogbo nkan, nkankan ko kagara ba A, O ma nmu ohun ti o ba wu U sẹmi, O si nmu titan ba ohun ti o ba wu U.
O di dandan fun olugbagbọ ododo ki o ma sọ ara rẹ di olosi ni iwaju iyi ọlọrọ keferi, ohun ti o si di dandan fun ni ki o se atunse rẹ, ki o si tọ sọna igbagbọ ninu Allah ati fifi ijọkan soso Rẹ rinlẹ, ki o si tun dupẹ idẹkun Rẹ ati ọla Rẹ le lori rẹ.
Dandan ni fun ẹniti dukia rẹ tabi ọmọ rẹ ba jọ ọ loju ti o se afiti idẹkun rẹ lo si ọdọ ẹniti o se e fun ati ẹniti o ta a lọrẹ pẹlu ki o sepe: nkan ti Ọlọhun ba fẹ o, (مَا شَآءَ ٱللَّهُ لَا قُوَّةَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ) Ko si agbara ayafi pẹlu Allah.
Ti Ọlọhu Allah ba gbero daadaa, yoo kanju fi iya jẹ laye.
Titọ adua sise lori titan dukia ẹniti dukia rẹ ba jẹ ikọja ẹnu aala rẹ ati sise keferi rẹ ati ofo rẹ.