وَقَالَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا عَبَدۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖ نَّحۡنُ وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ فَهَلۡ عَلَى ٱلرُّسُلِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ 35
Awọn ti wọn nmu nkan miran mọ Allah nibi ijọsin wọn sọpe: ti Allah ba fẹ ki a maa sin Oun nikan ni, ki a si ma sin ẹbọ pẹlu Rẹ, awa ki ba ti sin ẹnikẹni pẹlu Rẹ, awa tabi awọn baba wa ti wọn siwaju wa ki ba ti se e, ti O ba si fẹ ki a ma se ohun kohun ni eewọ awa ko ba ti se ni eewọ, pẹlu ẹri apejuwe ibajẹ yii ni awọn keferi ti o gbawaju sọ, ko jẹ dandan lori awọn ojisẹ ju imudopin ti o fi oju han lọ lori ohun ti wọn pa wọn lasẹ mimu de opin, paapaa wọn ti mu u dopin, ko si si awijare fun awọn keferi lori fifi akọsilẹ se awijare lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah ti se fifẹ ati yiyan fun wọn, ti O si tun ran awọn ojisẹ Rẹ si wọn.
وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّٰغُوتَۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ هَدَى ٱللَّهُ وَمِنۡهُم مَّنۡ حَقَّتۡ عَلَيۡهِ ٱلضَّلَٰلَةُۚ فَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ 36
Paapaa A ti gbe ojisẹ dide ninu awọn ijọ ti o siwaju, ti o npasẹ fun awọn ijọ rẹ ki wọn si Allah nikan soso, ki wọn o si gbe ijọsin fun nkan miran ninu bọ ati awọn ẹsu ati ohun ti o yatọ si wọn ju silẹ, bẹẹ ni o wa ninu wọn ẹniti Allah fi se kongẹ, ti o si gbaagbọ, ti o si tun tẹle ohun ti ojisẹ Rẹ mu wa, bakanaa ni o wa ninu wọn ẹniti o se keferi si Allah, ti o si yapa ojisẹ Rẹ, Ko fi se kongẹ, isina di dandan fun un, ki ẹ yaa rin lori ilẹ ki ẹ le fi oju yin ri bi igbẹyin olupurọ se ma nri lẹyin igbati iya ati iparun ba sẹlẹ si wọn.
إِن تَحۡرِصۡ عَلَىٰ هُدَىٰهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَن يُضِلُّۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّٰصِرِينَ 37
Ti o ba gbiyanju - ire ojise - pẹlu ohun ti o lagbara ninu ipepe rẹ fun awọn eniyan wọnyi, ti o si se oju kokoro imọna wọn, ti o si mu itẹgun eleyi; dajudaju Allah kii fi ẹniti o ba sọnu se kongẹ imọna, ko si si ẹnikankan ti o le ran wọn se lati mu ijiya kuro fun wọn yatọ si Allah.
وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَا يَبۡعَثُ ٱللَّهُ مَن يَمُوتُۚ بَلَىٰ وَعۡدًا عَلَيۡهِ حَقّٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 38
Awọn opurọ nipa ọjọ igbende yii bura ni ẹniti o dopin nibi ibura wọn, ti wọn si njiyan ni ẹniti o nkanpa mọ ọ: wipe Ọlọhun Allah ko nii gbe ẹniti o ba ku dide; laisi awijare kankan fun wọn lori rẹ, ko ri bẹẹ, Ọlọhun Allah yoo gbe gbogbo ẹniti o ba ku dide, adehun ododo wa le lori sugbọn ọpọ awọn eniyan ko mọ wipe Ọlọhun Allah yoo gbe awọn oku dide, ni wọn fi ntako igbedide.
لِيُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي يَخۡتَلِفُونَ فِيهِ وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰذِبِينَ 39
Allah yoo gbe wọn dide lapapọ ni ọjọ igbende, ki O le se alaye paapaa ohun ti wọn njiyan le lori ninu mimọ Ọlọhun Ọba lọkan ati igbedide ati jijẹ Anọbi fun wọn, ati ki awọn keferi le mọ wipe opurọ ni awọn jẹ nibi mimu nkan miran mọ Allah ati titako igbedide.
إِنَّمَا قَوۡلُنَا لِشَيۡءٍ إِذَآ أَرَدۡنَٰهُ أَن نَّقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ 40
Dajudaju ti awa ba gbero lati ji awọn oku ati gbigbe wọn dide, ko si olukọ kan ti o le kọ fun wa nibi eleyi, ohun Awa yoo sọ fun ohun ti A ba ti gbero ni wipe: (كُن) (jẹ bẹẹ), yoo si jẹ bẹẹ tiko si ibuyẹ.
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا ظُلِمُواْ لَنُبَوِّئَنَّهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ 41
Awọn ti wọn fi ile wọn ati eniyan wọn silẹ, ti wọn se irin ajo lati ilẹ keferi lọsi ilẹ Islam nitori sise oju kokoro iyọnu Allah lẹyin igbati awọn keferi ti fi iya jẹ wọn, ti wọn si fun ilẹ mọ wọn, Awa yoo sọ wọn kalẹ ni ile aye si ile kan, ti wọn yoo maa jẹ ẹni iyi nibẹ, bẹẹ ni ẹsan ọrun tobi ju tori wipe ninu rẹ ni ọgba idẹra wa, ti awọn oluyapa kuro nibi hijira ba mọ ẹsan ti n bẹ fun awọn oluse irin ajo ni, wọn ko ba ti yapa kuro nibẹ.
ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ 42
Awọn oluse irin ajo yii si oju ọna Allah ni awọn ti wọn se suuru lori suta awọn ijọ wọn ati fifi ara ile wọn silẹ ati awọn ilu wọn, wọn tun se suuru lori itẹle asẹ Allah, wọn si jẹ ẹniti o gbarale Ọlọhun wọn nikan nibi gbogbo alamọri ọrọ wọn nikan, Ọlọhun Allah waa fun wọn ni ẹsan ti o tobi yii.
Onilaakaye ni ẹniti o nwoye, ti o si gba isiti nibi ohun ti o sẹlẹ si awọn ẹni anu, olupurọ lori bi alamọri ọrọ wọn se sẹri si iparun, ofo, iya ati titan.
Ọgbọn ti o wa nibi igbedide ati ibusẹrisi ni ki Ọlọhun Ọba Allah ohun ti awọn eniyan nyapa le lori lori ọrọ ọjọ igbende ati gbogbo nkan han.
Ọla ti nbẹ fun suuru ati igbarale: ẹ ri suuru: nitori ibori ẹmin ti o wa nibẹ, ẹ ri igbarale: nitori ifi ọkan tan Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Re ga ati iso ọkan mọ.
Ẹsan ti nbẹ fun awọn oluse irin ajo ti wọn fi ile wọn ati dukia wọn silẹ, ti wọn si se suuru lori suta, ti wọn si gbarale Ọlọhun Ọba wọn, ohun ni aaye ti o lọla ju ati ipo ti o dara, ati isẹmin iyọnu ati aranse ti o rẹwa, ti o kun, ati isẹgun lori awọn ọta ati idari ilu pẹlu awọn ẹru.