۞مَّثَلُ ٱلۡجَنَّةِ ٱلَّتِي وُعِدَ ٱلۡمُتَّقُونَۖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ أُكُلُهَا دَآئِمٞ وَظِلُّهَاۚ تِلۡكَ عُقۡبَى ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْۚ وَّعُقۡبَى ٱلۡكَٰفِرِينَ ٱلنَّارُ 35
Iroyin alujannah eyiti Ọlọhun Ọba Allah se ni adehun fun awọn olupaya Ọlọhun lati ibi itẹle asẹ Ọlọhun ati jijinna si awọn nkan ti O kọ nipe awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ati igi rẹ, awọn eso rẹ yoo maa wa gbere ti ko nii tan yatọ si awọn eso ti ile aye, boji rẹ yoo maa wa gbere ti ko nii tan, ko si nii si lọ, eleyi ni igbẹyin awọn ti wọn npaya Allah lati ibi itẹle asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ, sugbọn igbẹyin awọn keferi jẹ ina ti wọn yoo wọ ibẹ gbere.
وَٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَفۡرَحُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَۖ وَمِنَ ٱلۡأَحۡزَابِ مَن يُنكِرُ بَعۡضَهُۥۚ قُلۡ إِنَّمَآ أُمِرۡتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱللَّهَ وَلَآ أُشۡرِكَ بِهِۦٓۚ إِلَيۡهِ أَدۡعُواْ وَإِلَيۡهِ مََٔابِ 36
Awọn ti a fun ni taoreeta ninu awọn yahuudi ati awọn ti a fun ni injiila ninu awọn nasaara, wọn nyọ pẹlu nkan ti a sọkalẹ fun wọn - irẹ ojisẹ - nitori sise deedee apakan ohun ti a sọkalẹ fun wọn, sugbọn ninu awọn apakan yahuudi ati nassara ohun ti o tako nkan ti a sọkalẹ fun ọ ninu ohun ti ko se kongẹ ifẹ inu wọn, tabi eyiti o royin wọn pẹlu sise pisi paarọ tabi pipa a rẹ, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah pami lasẹ ki nmaa sin nikan, emi ko gbọdọ mu ẹlomiran mọ ọ, ohun nikan ni mo npe, emi ko pe ẹlomiran, ọdọ Rẹ nikan ni ibusẹri si mi, eleyi si ni taoreeta ati injiila mu wa.
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ حُكۡمًا عَرَبِيّٗاۚ وَلَئِنِ ٱتَّبَعۡتَ أَهۡوَآءَهُم بَعۡدَ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ مَا لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا وَاقٖ 37
Bakanna apejuwe sisọ awọn tira ti wọn ti siwaju kalẹ pẹlu ahọn ijọ wọn, a sọ ọ kalẹ fun ọ -ire ojise- alukuraani ni gbolohun ifọsi wẹwẹ ti o fi oju han ni ododo ni ede larubawa, ti o ba tẹle - irẹ ojisẹ - ifẹ inu awọn ti a fun ni tira nibi mima ba ọ se ifanfa wọn nibi pipa ohun ti ko ba ifẹ inu wọn mu rẹ lẹyin igbati imọ ti waa ba ọ, ti Ọlọhun Ọba rẹ fi mọ ọ, ko si ẹlomiran fun ọ lẹyin Ọlọhun ti yoo la ọrọ rẹ bọrun, ti yoo si ran ọ se lori awọn ọta rẹ, ko si si oludaabobo kan fun ọ ti yoo kọ fun ọ kuro nibi iya rẹ.
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَذُرِّيَّةٗۚ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بَِٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ لِكُلِّ أَجَلٖ كِتَابٞ 38
A ti ran awọn ojisẹ kan siwaju tirẹ - irẹ ojisẹ - ninu abara, iwọ kọ ni ipilẹ ninu awọn ojisẹ, a fun wọn niyawo, a si se ọmọ fun wọn gẹgẹ bi abara yoku, a ko se wọn ni malaika ti ko fẹyawo, ti ko bimọ, iwọ yii naa wa ninu awọn ojisẹ ti wọn jẹ abara, ti o nfẹyawo, ti o si nbimọ, kilo wa de ti awọn ẹlẹbọ nse eemọ nibi wipe o jẹ eleyi? Ko tọ fun ojisẹ kan ki o mu amin kan wa lati ọdọ rẹ ayaafi ti Allah ba yọnda fun ki o mu wa, gbogbbo alamọri ti Ọlọhun Ọba ba kọ silẹ, ti wa ni akọsilẹ ti wọn sọ eleyi si ati asiko iku ti ko nii gbawaju, bẹẹ ni ko si ni kẹyin.
يَمۡحُواْ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ وَيُثۡبِتُۖ وَعِندَهُۥٓ أُمُّ ٱلۡكِتَٰبِ 39
Ọlọhun Allah ma nyẹ eyiti o ba wu U ninu rere tabi aburu tabi oriire tabi oriibu, ati nkan miran, O si ma nfi eyiti o ba wu U rinlẹ ninu rẹ ati wipe ọdọ Rẹ ni ọpọn ọla ti a daabobo wa, Oun ni ibusẹri si gbogbo eleyi, eyiti o ba han ninu iparẹ tabi ifirinlẹ se deede ohun ti o wa nibẹ.
وَإِن مَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُ وَعَلَيۡنَا ٱلۡحِسَابُ 40
Ti a ba fi han ọ - irẹ anọbi - apakan ohun ti a se ni adehun ninu iya siwaju ki o too ku, eleyi jẹ lati ọdọ wa tabi a ti ẹ dan ọ wo siwaju ki a to fi han ọ, nkankan ko jẹ dandan fun ọ imudopin ohun ti a pa ọ lasẹ ki o mudopin lọ, sisan wọn lẹsan ko si fun ọ, bẹẹ ni sise isiro wọn, eleyi wa fun wa.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا نَأۡتِي ٱلۡأَرۡضَ نَنقُصُهَا مِنۡ أَطۡرَافِهَاۚ وَٱللَّهُ يَحۡكُمُ لَا مُعَقِّبَ لِحُكۡمِهِۦۚ وَهُوَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 41
Se awọn keferi yii ko ri ni wipe a ma nmu ẹdinku lẹgbẹẹgbẹ ba ilẹ keferi pẹlu fifan Islam ka ati yiyọnda lọ fun awọn olugbafa lọ si ibẹ, Ọlọhun Allah ma ndajọ, O si ma nseto bi O se wu U laarin awọn ẹru Rẹ, ẹnikankan ko le fi ẹdinku lati iyipada bikose pasi paarọ kẹyin idajọ rẹ, Oun ti mimọ nbẹ fun jẹ oluyara sesiro, yoo si isiro awọn ẹni akọkọ ati awọn ẹni ikẹyin ni ọjọ kan soso.
وَقَدۡ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَلِلَّهِ ٱلۡمَكۡرُ جَمِيعٗاۖ يَعۡلَمُ مَا تَكۡسِبُ كُلُّ نَفۡسٖۗ وَسَيَعۡلَمُ ٱلۡكُفَّٰرُ لِمَنۡ عُقۡبَى ٱلدَّارِ 42
Paapaa awọn ijọ ti o ti siwaju ti dete si awọn anọbi wọn, ete si jẹ ti wọn, wọn si pe nkan ti wọn muwa nirọ, kinni nkan ti wọn se pẹlu idari eto wọn fun wọn? Ko si nkankan; toripe oludari eto ti yoo lamusẹ ohun ni idari eto ti Ọlọhun Ọba ti ko si ẹlomiran gẹgẹ bi Ọba ti mimọ nbẹ fun ni O mọ gbogbo awọn isẹ ẹda patapata, nkankan kosi pamọ fun, igbayi ni wọn yoo mọ odiwọn asise wọn nibi aini igbagbọ si Allah ati iye olugbagbọ ododo ti adanwo kan, wọn si ti ibẹ ri alujannah ko jọ ati igbẹyin daadaa.
Iseni loju kokoro si alujannah pẹlu sise alaye iroyin rẹ, bi sisan akeremọdo, wiwa gbere arisiki ati oji.
Ewu titẹle ifẹ inu ninu wiwa imọ ati wipe o wa ninu okunfa iya Allah.
Sise alaye wipe dajudaju awọn ojisẹ abara ni wọn, wọn ni awọn iyawo, wọn si ni ọmọ ati wipe dajudaju anọbi wa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun kii se akọkọ laarin wọn, oun naa ti di apejuwe wọn nibi eleyi.