وَمَا لَهُمۡ أَلَّا يُعَذِّبَهُمُ ٱللَّهُ وَهُمۡ يَصُدُّونَ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَمَا كَانُوٓاْ أَوۡلِيَآءَهُۥٓۚ إِنۡ أَوۡلِيَآؤُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡمُتَّقُونَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 34
Kinni ohun ti o le mu wọn ma jẹ iya lẹyin igbati wọn ti se ohun ti o le sọ iya di ọranyan fun wọn, nitori wipe wọn kọ fun awọn eniyan lati ma wọ inu mọsalaasi ọwọ naa, ki wọn o ma baa rọkirika rẹ tabi kirun nibẹ? Awọn ọlọsẹbọ kii se aayo Ọlọhun Ọba, ko si awọn aayo Ọlọhun Ọba ju awọn olupaya lọ, awọn ti wọn npaya Rẹ pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti o kọ, sugbọn ọpọ ninu awọn ọlọsẹbọ ko mọ nigbati wọn npe apemọra wipe awọn jẹ aayo Rẹ, bẹẹ ni wọn kii se aayo Rẹ.
وَمَا كَانَ صَلَاتُهُمۡ عِندَ ٱلۡبَيۡتِ إِلَّا مُكَآءٗ وَتَصۡدِيَةٗۚ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ 35
Adua awọn ọlọsẹbọ ninu Mọsalaasi ọwọ naa ko jẹ nkankan ju ife ati atẹwọ lọ, ẹ yara maa tọ wo - ẹyin ọlọsẹbọ - iya ipani naa ati imulẹru ni ọjọ badiri nitori keferi yin si Ọlọhun Ọba Allah ati pipe ojisẹ Rẹ ni irọ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ لِيَصُدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ فَسَيُنفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيۡهِمۡ حَسۡرَةٗ ثُمَّ يُغۡلَبُونَۗ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ يُحۡشَرُونَ 36
Dajudaju awọn ti wọn se keferi si Ọlọhun Ọba Allah nna dukia wọn lati kọ fun awọn eniyan kuro nibi ẹsin Ọlọhun Ọba Allah, wọn yoo nan, bẹẹ ni ohun ti wọn gbero ko nii di ododo, lẹyin igba naa ni igbẹyin inawo wọn yoo di abamọ; nitori bibọ owo wọn, ati bibọ ohun ti wọn tori rẹ nawo, lẹyin igba naa wọn yoo di ẹniti wọn bori pẹlu riri aranse awọn olugbagbọ ododo le wọn lori, sugbọn awọn ti wọn se aimoore si Ọlọhun Ọba Allah, wọn yoo maa da wọn ti wọn lọpọnpọn lọ si inu ina jahanamọ ni ọjọ igbende, wọn yoo wọ ibẹ ni wiwọ gbere.
لِيَمِيزَ ٱللَّهُ ٱلۡخَبِيثَ مِنَ ٱلطَّيِّبِ وَيَجۡعَلَ ٱلۡخَبِيثَ بَعۡضَهُۥ عَلَىٰ بَعۡضٖ فَيَرۡكُمَهُۥ جَمِيعٗا فَيَجۡعَلَهُۥ فِي جَهَنَّمَۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 37
Wọn yoo dari awọn keferi ti wọn nna dukia wọn lati kọdi oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah lọ si ina jahanamọ, ki Ọlọhun Ọba Allah le se onpinya laarin awọn keferi onibajẹ ati ipin awọn olugbagbọ ododo ti o dara, ki o si le sọ awọn eniyan ibajẹ ati isẹ wọn ati dukia wọn di ohun ti apakan ju apakan lọ ni nkan ti yoo ju ara wọn lọ, ti yoo si gbe ara wọn pọn, yoo si fi inu ina jahanamọ, awọn wọnyi ni ẹni ofo; toripe wọn padanu ẹmin ara wọn ati ara ile wọn ni ọjọ igbende.
قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِن يَنتَهُواْ يُغۡفَرۡ لَهُم مَّا قَدۡ سَلَفَ وَإِن يَعُودُواْ فَقَدۡ مَضَتۡ سُنَّتُ ٱلۡأَوَّلِينَ 38
Sọ - ire ojise - fun awọn ti wọn nse keferi si Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ninu ijọ rẹ: ti wọn ba jawọ kuro nibi sise keferi wọn si Ọlọhun Ọba Allah at ojisẹ Rẹ, ati gigunri kuro nibi oju ọna ti Ọlọhun Ọba, ẹniti o ba gba A gbọ; Ọlọhun Ọba Allah yoo fi ori jin wọn eyiti wọn ti sẹ kọja ninu ẹsẹ nitori wipe Islam ma npa eyiti o ti kọja ninu ẹsẹ rẹ, sugbọn ti wọn ba sẹri si inu sise keferi wọn, paapaa o ti gbawaju ninu isesi Ọlọhun Ọba si awọn ẹni akọkọ wipe ti wọn ba pe E nirọ, ti wọn si tẹsiwaju lori sise keferi wọn, Yoo kanju jẹ wọn niya.
وَقَٰتِلُوهُمۡ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتۡنَةٞ وَيَكُونَ ٱلدِّينُ كُلُّهُۥ لِلَّهِۚ فَإِنِ ٱنتَهَوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ 39
Ki ẹ maa pa - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ọta yin ninu awọn keferi, ti ko fi nii si ẹbọ tabi idina fun awọn olugbafa fun Ọlọhun ninu ẹsin, ti ẹsin ati itẹle yoo jẹ ti Allah nikan soso, ko nii si orogun fun Un nibẹ, ti awọn keferi ba jawọ kuro nibi ẹbọ ti wọn nse ati isẹri awọn eniyan kuro ni oju ọna ti Ọlọhun Ọba, ki ẹ fi wọn silẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba nri isẹ wọn, ipamọ kankan ko pamọ fun Un.
وَإِن تَوَلَّوۡاْ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَوۡلَىٰكُمۡۚ نِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ 40
Ti wọn ba sẹri kuro nibi ohun ti wọn pa wọn lasẹ gẹgẹ bi jijawọ kuro nibi sise keferi ati ikọdi kuro ni oju ọna ti Ọlọhun Ọba, ki ẹ ya mọ amọdaju - ẹyin olugbagbọ ododo - wipe Ọlọhun Ọba Allah yoo ran yin se le wọn lori, Ọlọhun Ọba Allah to ni olowo fun ẹniti o ba gbara le E, tabi fi ara ti I, O si to ni alaranse fun ẹniti o ba ran an se, ẹniti O ba ti lẹyin ti jere, bẹẹ ni ẹniti O ba ran se ti ri aranse.
Kikọdini kuro nibi Masalasi ọwọ naa jẹ ẹsẹ ti o tobi, ẹniti o see lẹtọ si iya ti ile aye siwaju iya ti ọrun.
Bibẹ ninu Mọsalaasi ọwọ naa, tabi jijẹ olowo rẹ jẹ iyi ti ẹnikẹni ko lẹtọ si ayaafi awọn ọrẹ Ọlọhun, olupaya Rẹ.
Ikilọ fun awọn keferi wipe wọn ko nii ri nkankan lori dukia wọn ti wọn ba na si ibi ibajẹ koda bi o pọ wa ninu awọn aayah naa, ofo yoo si sẹlẹ si wọn ati abamọ ti o le koko.
Ki Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga pe awọn keferi fun irunu piwada ati igbagbọ jẹ ipepe ti o si silẹ fun wọn koda bi wọn nba orikunkun lọ.
Ẹniti Allah ba jẹ olowo rẹ ati alaranse rẹ ko si ipaya fun un, bẹẹ ni ẹniti Allah ba jẹ ọta fun, ko si iyi fun un.