وَلِبُيُوتِهِمۡ أَبۡوَٰبٗا وَسُرُرًا عَلَيۡهَا يَتَّكُِٔونَ 34
A se awọn ẹnu ọna fun ile wa, a si tunh se awọn ibusun sibẹ ki wọn le maa rọgbọkun le lori niti idẹnilẹkẹ fun wọn ati adanwo.
وَزُخۡرُفٗاۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُتَّقِينَ 35
A ba se wura fun wọn gbogbo eleyi ko jẹ nkankan ju adun isẹmin aye lọ, anfaani rẹ kere nitori aini sẹku, idẹkun ti o wa ni ọrun si loore ni ọdọ Ọlọun rẹ - irẹ ojisẹ - fun awọn olupaya allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ.
وَمَن يَعۡشُ عَن ذِكۡرِ ٱلرَّحۡمَٰنِ نُقَيِّضۡ لَهُۥ شَيۡطَٰنٗا فَهُوَ لَهُۥ قَرِينٞ 36
Ẹniti o ba woye si inu Alukuraani ni iwoye ti fi ara balẹ yoo mu lọ si ibi igunri, yoo si ri iya pẹlu ijẹgaba esu, ti yoo dun ni mọ ọ, yoo si se alekun isina rẹ.
وَإِنَّهُمۡ لَيَصُدُّونَهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُم مُّهۡتَدُونَ 37
Dajudaju awọn alasunmọ ti o jẹ gaba lori awọn olugunri kuro nibi Alukuraani, paapaa wọn yoo maa dina kuro nibi ẹsin Allah; wọn ko nii mu awọn asẹ Rẹ sẹ, bẹẹni wọn ko nii jinna si awọn ohun ti o kọ, wọn yoo si maa lero wipe ẹni imọna lọ si ibi ododo ni awọn nse, nitori eleyi wọn ko nii le ronu piwada kuro nibi anu wọn.
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَنَا قَالَ يَٰلَيۡتَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَ بُعۡدَ ٱلۡمَشۡرِقَيۡنِ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرِينُ 38
Titi ti olugunri kuro nibi iranti Allah ni ọjọ igbende yoo fi wa ba wa, yoo sọrọ ni ẹniti o nrankan: o ma se ti ko si laarin emi ati iwọ - irẹ alasunmọ - gaga ti o wa laarin ibuyọ oorun ati ibuwọ, o ma buru ni alasunmọ.
وَلَن يَنفَعَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ إِذ ظَّلَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ 39
Allah sọ fun awọn keferi ni ọjọ igbende: ko le se yin ni anfaani loni - paapaa ẹ ti se abosi ẹmin ara yin pẹlu ẹbọ ati awọn ẹsẹ - biba kẹgbẹ yin nibi iya, awọn olubakẹgbẹ ko le iya kankan kuro fun yin.
أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ أَوۡ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 40
Dajudaju awọn eniyan wọnyi jẹ aditi kuro nibi gbigbọ ododo, afọju kuro nibi ririran ri i, se iwọ - irẹ ojisẹ - lagbara lati fun aditi lọrọ gbọ tabi fi afọju mọna tabi mu imọna ba ẹniti o wa ni oju ọna anu ti o han kuro ni oju ọna ti o duro tọ?!
فَإِمَّا نَذۡهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنۡهُم مُّنتَقِمُونَ 41
Ti a ba mu ọ lọ - pẹlu ki a pa ọ siwaju ki a to fi iya jẹ wọn - dajudaju awa yoo gbẹsan lara wọn pẹlu fifi iya jẹ wọn ni aye ati ọrun.
أَوۡ نُرِيَنَّكَ ٱلَّذِي وَعَدۡنَٰهُمۡ فَإِنَّا عَلَيۡهِم مُّقۡتَدِرُونَ 42
Tabi ki a fi apakan ohun ti a se ni adehun ninu iya han wọn, dajudaju awa jẹ ẹniti o lagbara lori eleyi, wọn ko nikapa lati bori wa nibi nkankan.
فَٱسۡتَمۡسِكۡ بِٱلَّذِيٓ أُوحِيَ إِلَيۡكَۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 43
Ki o ya gbamu - irẹ ojisẹ - ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ ransẹ imisi si ọ, ki o si maa sisẹ dajudaju iwọ wa ni oju ọna ododo ti ko si iruju nibẹ.
وَإِنَّهُۥ لَذِكۡرٞ لَّكَ وَلِقَوۡمِكَۖ وَسَوۡفَ تُسَۡٔلُونَ 44
Dajudaju Alukuraani yii jẹ iyi fun ọ ati fun awọn ijọ rẹ, wọn yoo si pada bi yin leere ni ọjọ igbende nipa ini igbagbọ si I ati itẹle imọna Rẹ ati ipepe si i.
وَسَۡٔلۡ مَنۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلۡنَا مِن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ءَالِهَةٗ يُعۡبَدُونَ 45
Beere - irẹ ojisẹ - awọn ti a gbe dide siwaju rẹ ninu awọn ojisẹ: se a se awọn olujọsin fun, ti wọn njọsin fun yatọ si Ọba Ajọkẹ aye ni?!
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بَِٔايَٰتِنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَقَالَ إِنِّي رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 46
Paapaa a gbe Musa dide pẹlu awọn amin Wa lọ si ọdọ fir'aona ati awọn ẹni iyi ninu ijọ rẹ, o si sọ fun wọn: dajudaju emi jẹ ojisẹ Ọlọhun gbogbo ẹda lapapọ.
فَلَمَّا جَآءَهُم بَِٔايَٰتِنَآ إِذَا هُم مِّنۡهَا يَضۡحَكُونَ 47
Nigbati o wa ba wọb pẹlu awọn amin Wa, wọn fi nrẹrin; niti yẹyẹ ati amusere.
Ewu igunri kuro nibi Alukuraani.
Alukuraani jẹ iyi fun ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati fun awọn ijọ rẹ.
Pipapọ awọn iwe lori pipa ẹbọ ti patapata.
Yẹyẹ si ododo jẹ iroyin kan ninu awọn iroyin keferi.