وَلَقَدۡ جَآءَكُمۡ يُوسُفُ مِن قَبۡلُ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا زِلۡتُمۡ فِي شَكّٖ مِّمَّا جَآءَكُم بِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا هَلَكَ قُلۡتُمۡ لَن يَبۡعَثَ ٱللَّهُ مِنۢ بَعۡدِهِۦ رَسُولٗاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَنۡ هُوَ مُسۡرِفٞ مُّرۡتَابٌ 34
Paapaa Yuusuf ti waa ba yin siwaju Musa pẹlu awọn awijare ti o fi oju han lori ijọkan soso Allah sugbọn ẹ ko yẹ ẹ ko gbo ninu iyemeji ati pipe ohun ti o mu wa fun yin nirọ titi ti o fi ku, ẹ tun lekun ni iyemeji ati royiroyi, ẹ si sọpe: Allah ko le gbe ojisẹ kankan dide lẹyin rẹ, iru isọnu yin yii kuro nibi ododo ni Allah yoo maa fi sọ gbogbo olukọja ẹnu aala nu, ti o nse iyemeji sibi ijọkan soso Rẹ.
ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡۖ كَبُرَ مَقۡتًا عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلۡبِ مُتَكَبِّرٖ جَبَّارٖ 35
Awọn ti wọn nse ifanfa nibi awọn amin Allah lati ba A jẹ laisi ẹri tabi awijare kankan ti o wa ba wọn, iyan wọn yii buru ni ibinu ni ọdọ Allah ati lọdọ awn ti o nigbagbọ si I ati si awọn ojisẹ Rẹ gẹgẹ bi Allah ti fi edidi di ọkan awọn onija nibi awọn amin Wa lati ba a jẹ, bayi naa ni Allah yoo fi edidi di ọkan gbogbo onigberaga kuro nibi ododo olufipajanu, ko le mọna sibi deedee, bẹẹni ko le ri itọsọna lọsi ibi rere.
وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَٰهَٰمَٰنُ ٱبۡنِ لِي صَرۡحٗا لَّعَلِّيٓ أَبۡلُغُ ٱلۡأَسۡبَٰبَ 36
Fir'aona sọ fun asoju rẹ Hamọna: irẹ hamọna kọ ile kan ti o ga fun mi; kin le de ogongo oju ọna.
أَسۡبَٰبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ كَٰذِبٗاۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَصُدَّ عَنِ ٱلسَّبِيلِۚ وَمَا كَيۡدُ فِرۡعَوۡنَ إِلَّا فِي تَبَابٖ 37
Kin si le de ogongo awọn oju ọna gbogbo sanmọ ti mo le fi de ibẹ, ki nle wa wo ohun ti Musa nsin, ti o si nlero wipe Oun ni ẹniti ijọsin fun tootọ, dajudaju emi lero wipe Musa jẹ opurọ nibi ohun ti nbẹ apemọra rẹ, bayi ni wọn se se buburu isẹ fir'aona lọsọ fun un, nigbati o beere fun nkan ti o beere lọdọ hamọna, wọn si yi kuro ni oju ọna ododo lọ si oju ọna isina, ete fir'aona ko jẹ nkankan –bikose lati se afihan ibajẹ rẹ ti o wa lori rẹ ati lati lati ba ododo jẹ eyiti Musa mu wa- ayaafi nibi ofo; nitoripe ibusẹri rẹ jẹ ofo ati ijakulẹ nibi igbesẹ rẹ ati oriibu ti ko le ja lailai.
وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُونِ أَهۡدِكُمۡ سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ 38
Arakunrin ti o nigbagbọ ninu awọn ara ile fir'aona sọ ni ẹniti o nse isiti fun ijọ rẹ, ti o si ntọka wọn si oju ọna ododo: ẹyin ijọ mi, ẹ tẹle mi ki nle tọka fun yin, ki nsi fi yin mọ oju ọna deedee ati ọnaamọ lọsi ibi ododo.
يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا مَتَٰعٞ وَإِنَّ ٱلۡأٓخِرَةَ هِيَ دَارُ ٱلۡقَرَارِ 39
Ẹyin ijọ mi, dajudaju isẹmin aye yii jẹ igbadun ti yoo ja kuro, ẹ ma jẹ ki awọn igbadun ti yoo yẹ yii tan yin jẹ nibẹ, dajudaju ile ọrun ati ohun ti nbẹ nibẹ ninu idẹkun lailai ko le ja, ohun ni ile isinmin si ati ibudo, ẹ maa sisẹ fun un pẹlu titẹle ti Allah, ki ẹ si sọra nibi airoju isẹmin aye lati ma sisẹ ti ọrun.
مَنۡ عَمِلَ سَيِّئَةٗ فَلَا يُجۡزَىٰٓ إِلَّا مِثۡلَهَاۖ وَمَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ يُرۡزَقُونَ فِيهَا بِغَيۡرِ حِسَابٖ 40
Ẹniti o ba se isẹ aidara kan, wọn ko nii fi iya jẹ ju deedee ohun ti o se lọ, wọn ko nii lekun iya rẹ, ẹniti o ba si se isẹẹre kan, ti o fi wa oju rere Allah, akọ ni olusisẹ yii jẹ tabi abo, ti o si jẹ onigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ -awọn wọnyi ni ẹniti a royin pẹlu awọn iroyin ẹyin naa, wọn yoo wọ ọgba idẹra ni ọjọ igbende, Allah yoo si ran wọn se ẹpẹlu ohun ti O pa lese fun wọn nibẹ gẹgẹ bi awọn eso ati idẹkun gbere ti ko nii ja lailai laisi isiro. \
Iyan lati ba ododo jẹ ati lati sọ ibajẹ di ẹtọ jẹ iya eebu, o si wa ninu awọn iroyin ẹni anu.
Igberaga ma nkọ fun ni kuro nibi imọna lọsi ibi ododo.
Jijakulẹ awọn ete keferi ati ọgbọn wọn lati ba ododo jẹ.
Jijẹ dandan mimura silẹ de ọrun ati ki aye ma dini lọwọ nipa rẹ.