وَءَاتَىٰكُم مِّن كُلِّ مَا سَأَلۡتُمُوهُۚ وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَظَلُومٞ كَفَّارٞ 34
O si fun yin ni ọpọ nkan ti ẹ nbeere fun ati nkan ti ẹ ko beere fun ti ẹ ba nka idẹra Allah, ẹ ko nikapa lati mọ odiwọn rẹ; nitori pipọ rẹ ati onka rẹ, eyiti wọn ba sọ fun yin nibẹ jẹ apejuwe ninu rẹ ni, dajudaju ọmọ ẹda eniyan jẹ alabosi fun ẹmin ara rẹ ati ọlọpọ iyan jija fun idẹkun Allah ẹniti mimọ nbẹ fun.
وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ رَبِّ ٱجۡعَلۡ هَٰذَا ٱلۡبَلَدَ ءَامِنٗا وَٱجۡنُبۡنِي وَبَنِيَّ أَن نَّعۡبُدَ ٱلۡأَصۡنَامَ 35
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Ibrahim sọ lẹyin igbati o ti mu ọmọ rẹ Ismaheel ati iya rẹ hajarah lọsi aaye kan ni mẹkkah: irẹ Ọlọhun mi, sọ ilu ti mo mu awọn ara ile mi yii di - ohun naa ni Mẹkkah - ilu ifọkanbalẹ, wọn kii ta ẹjẹ silẹ nibẹ, wọn si kii se abosi ẹnikẹni nibẹ, mu emi ati awọn ọmọ mi jinna si sinsin oosa.
رَبِّ إِنَّهُنَّ أَضۡلَلۡنَ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِۖ فَمَن تَبِعَنِي فَإِنَّهُۥ مِنِّيۖ وَمَنۡ عَصَانِي فَإِنَّكَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 36
Irẹ Ọlọhun mi, dajudaju awọn oosa ti sọ ọpọ nu ninu awọn eniyan nitoripe wọn lero wipe yoo sipẹ fun wọn, wọn si kan adanwo lati ibẹ, wọn si nsin wọn dipo Allah, ẹniti o ba tẹle mi ninu awọn eniyan nibi imọ Ọlọhun Ọba lọkan ati titẹle asẹ Rẹ, dajudaju o wa ninu ẹni mi ati olutẹle mi, ẹniti o ba yapa mi, ti ko si tẹle mi nibi imọ Ọlọhun lọkan ati titẹle asẹ Rẹ, dajudaju iwọ jẹ - irẹ Ọlọhun mi - olufori ẹsẹ jin ẹniti o ba wu Ọ lati fi ori jin, onikẹ si wọn.
رَّبَّنَآ إِنِّيٓ أَسۡكَنتُ مِن ذُرِّيَّتِي بِوَادٍ غَيۡرِ ذِي زَرۡعٍ عِندَ بَيۡتِكَ ٱلۡمُحَرَّمِ رَبَّنَا لِيُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ فَٱجۡعَلۡ أَفِۡٔدَةٗ مِّنَ ٱلنَّاسِ تَهۡوِيٓ إِلَيۡهِمۡ وَٱرۡزُقۡهُم مِّنَ ٱلثَّمَرَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَشۡكُرُونَ 37
Ọlọhun Ọba wa, mo mu apakan arọmọdọmi gbe ni, awọn ni arọmọdọmọ Ismaheel ati awọn ọmọ rẹ agbegbe ti (ohun naa ni mẹkkah), irugbin ko si nibẹ, ko si si omin ni ẹgbẹ ile Rẹ ọwọ, Ọlọhun Ọba wa, mo mu wọn gbe ni ẹgbẹ rẹ ki wọn le maa kirun nibẹ, ọkan awọn eniyan waa di - irẹ Ọlọhun Ọba mi - ohun jẹran lọ si ibẹ, ati si ilu naa, ran wọn se pẹlu nkan eleso ki wọn le dupẹ lori awọn idẹkun Rẹ le wọn lori.
رَبَّنَآ إِنَّكَ تَعۡلَمُ مَا نُخۡفِي وَمَا نُعۡلِنُۗ وَمَا يَخۡفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ 38
Iwọ Ọlọhun Ọba wa, dajudaju O mọ gbogbo ohun ti a fi pamọ ati gbogbo ohun ti a fi han, nkankan ko pamọ fun Un ni ilẹ ati ni sanmọ bikose wipe o mọ ọ, bukaata wa ati aini wa ko si pamọ fun Un.
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي وَهَبَ لِي عَلَى ٱلۡكِبَرِ إِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَۚ إِنَّ رَبِّي لَسَمِيعُ ٱلدُّعَآءِ 39
Ọpẹ ati ẹyin fun Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun, ẹniti o jẹpe mi lori titami lọrẹ ẹniire, o fun mi pẹlu didagba ọjọ orii mi ni Ismaheel lati ọdọ Haajarah ati Ishaaq lati ọdọ Saarọ, dajudaju Ọlọhun Ọba mi ti mimọ nbẹ fun jẹ olugbọ adua ẹniti o ba npe E.
رَبِّ ٱجۡعَلۡنِي مُقِيمَ ٱلصَّلَوٰةِ وَمِن ذُرِّيَّتِيۚ رَبَّنَا وَتَقَبَّلۡ دُعَآءِ 40
Irẹ Ọlọhun Ọba mi, se mi ni olukirun ni ojupọnna pipe, si se arọmọdọmọ mi ninu awọn ti yoo maa ki I bakanaa, irẹ Ọlọhun Ọba wa, jẹpe adua mi, sise ni itẹwọgba ni ọdọ Rẹ.
رَبَّنَا ٱغۡفِرۡ لِي وَلِوَٰلِدَيَّ وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ يَوۡمَ يَقُومُ ٱلۡحِسَابُ 41
Ọlọhun Ọba mi, fi ori ẹsẹ mi jin mi, fi ori ẹsẹ jin awọn obi mi mejeeji (o sọ ki o to mọ wipe baba rẹ jẹ ọta Allah sugbọn nigbati o han si wipe o jẹ ọta Allah, o jawọ kibẹ), ki o si tun fi ori ẹsẹ jin awọn olugbagbọ ododo ni ọjọ ti awọn eniyan yoo duro fun isiro wọn niwaju Ọlọhun Ọba wọn.
وَلَا تَحۡسَبَنَّ ٱللَّهَ غَٰفِلًا عَمَّا يَعۡمَلُ ٱلظَّٰلِمُونَۚ إِنَّمَا يُؤَخِّرُهُمۡ لِيَوۡمٖ تَشۡخَصُ فِيهِ ٱلۡأَبۡصَٰرُ 42
Mase lero pe - irẹ ojisẹ - dajudaju Ọlọhun Ọba fọnu nipa nkan ti awọn alabosi nse gẹgẹ bi irọ pipa ati kikọdi awọn eniyan kuro ni oju ọna ti Ọlọhun Ọba ati oun ti o yatọ si eleyi nitori wipe O nlọ iya awọn alabosi lara, bikose wipe O jẹ onimimọ nipa rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, dajudaju O nlọ iya lara di ọjọ igbende, ọjọ yii ni awọn oju yoo gbe soke nitori ipaya oun ti wọn nfi oju ri.
Sise alaye ọla ti nbẹ fun Mẹkkah eyiti anọbi Allah tii se Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun se adua si.
Dajudaju ọmọ ẹda eniyan bi o ti wulẹ ki ipo rẹ ga to ninu itẹle asẹ ati ijọ sin dandan ni fun Un ki o paya lori ẹmin ara rẹ ati arọmọdọmọ rẹ kuro nibi ẹbọ ti o tobi ati eyiti o wẹ.
Adua Ibrahim ti ọla nbẹ fun tọka si wipe bi ipo ẹru ti wulẹ ki o ga to yoo si maa wa ni alaini si Ọlọhun Ọba Allah ti o ga julọ bakanna yoo si maa ni bukaata si.
Ninu ojupọnna ikọni lẹkọ: ni sise adua fun awọn ọmọ ki wọn le se daadaa, ki wọn si le adisọkan ti o dara ati kongẹ nibi mimu awọn ofin ẹsin duro daadaa.