قُلۡ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥۚ قُلِ ٱللَّهُ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ 34
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ yii: njẹ nbẹ ninu awọn akẹgbẹ yin ẹniti ẹ nsin yatọ si Allah ti o le da ẹda laisi apejuwe kan siwaju, ki o tun waa gbe dide lẹyin iku rẹ? Sọ fun wọn: Allah nikan ni O le da ẹda laisi apejuwe rẹ siwaju, ti yoo si tun gbe dide lẹyin iku rẹ, kilode ti ẹ fi wa nsẹri - ẹyin ẹlẹbọ - kuro nibi ododo lọsi ibi ibajẹ?!
قُلۡ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّۚ قُلِ ٱللَّهُ يَهۡدِي لِلۡحَقِّۗ أَفَمَن يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّ أَحَقُّ أَن يُتَّبَعَ أَمَّن لَّا يَهِدِّيٓ إِلَّآ أَن يُهۡدَىٰۖ فَمَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ 35
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: njẹ o wa ninu awọn akẹgbẹ yin awon ẹni ti ẹ nsin yatọ si Allah ẹniti o le tọka lọsi ibi ododo bi? Sọ fun wọn: Ọlọhun Ọba Allah nikan ni o le tọka lọ si ibi ododo, njẹ ẹniti o ntọka awọn eniyan lọsi ibi ododo, ti o si npe wọn sibẹ ni o lọla ki a tẹle tabi awọn ohun ti ẹ njọsin fun ti ko le mọ ọna fun ara rẹ ayaafi ki ẹlomiran fi mọ ọna?! Bawo ni ẹ se ndajọ pẹlu ibajẹ nigbati ẹ nlero wipe awọn wọnyi jẹ akẹgbẹ Ọlọhun Ọba Allah?! Giga Ọlọhun Ọba kọja gbolohun yin niti giga ti o tobi.
وَمَا يَتَّبِعُ أَكۡثَرُهُمۡ إِلَّا ظَنًّاۚ إِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيًۡٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا يَفۡعَلُونَ 36
Ọpọ awọn ẹlẹbọ ko tẹle nkankan ju ohun ti wọn ko nimọ nipa rẹ lọ, nkan ti wọn tẹle ni ifẹ inu ati iyemeji, dajudaju iyemeji kole duro ni ipo imọ, ko si le rọni lọrọ kuro nibẹ, dajudaja Allah nimọ nipa ohun ti ẹ nse, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ wọn. Yoo si san wọn lẹsan le lori.
وَمَا كَانَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ أَن يُفۡتَرَىٰ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِن تَصۡدِيقَ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَتَفۡصِيلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا رَيۡبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 37
Ko tọ ki a sọ wipe wọn da Alukuraani yii ni tabi ki a se afiti rẹ si ọdọ ẹniti kii se Ọlọhun Ọba Allah nitori kikagara ọmọ ẹda eniyan lati mu iru rẹ wa, sugbọn o jẹ olupe ohun ti o ti sọkalẹ siwaju rẹ ninu iwe lododo, o si jẹ olusalaye awọn idajọ ti o ruju, ko si iyemeji nibi wipe o jẹ ohun ti o sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba ti o da gbogbo ẹda.
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ فَأۡتُواْ بِسُورَةٖ مِّثۡلِهِۦ وَٱدۡعُواْ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 38
Bikose wipe se awọn ẹlẹbọ yii fẹẹ maa sọ ọrọ ni: dajudaju Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ni o da Alukuraani lati ọdọ ara rẹ, ti o wa fi ti si ọdọ Allah, sọ -ire ojise- ni ifesi pada fun wọn: ti o ba ja si wipe mo mu wa lati ọdọ mi, ti mo si jẹ abara bii ti yin, ẹyin naa ẹ mu ọgba ọrọ kan wa gẹgẹ bi apejuwe rẹ, ki ẹ si pe ẹniti o ba wu yin, ti o jẹ oluranyin lọwọ le lori, ti ẹ ba jẹ ododo lori sisọ wipe Alukuraani jẹ nkan opurọ ti a da, ẹ ko lagbara eleyi, sise afẹku agbara yin - ẹ jẹ alahọn alagbekalẹ lasan ni - o ntọka lori wipe dajudaju Alukuraani jẹ ohun ti o sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni.
بَلۡ كَذَّبُواْ بِمَا لَمۡ يُحِيطُواْ بِعِلۡمِهِۦ وَلَمَّا يَأۡتِهِمۡ تَأۡوِيلُهُۥۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلظَّٰلِمِينَ 39
Wọn ko jẹ ipe bikose wipe wọn yara gaga lati pe Alukuraani nirọ siwaju ki wọn o too gbọ ye lati ronu nipa rẹ ati siwaju ki iya ti wọn nse ikilọ kuro nibẹ ko sẹlẹ, paapaa wiwa iya naa si tun sun mọ, iru irọ yii awọn ijọ ti wọn ti siwaju naa ti pa a, o si sọ iya ti o wu U kalẹ, yaa woye - irẹ ojisẹ - si bi igbẹyin awọn ijọ opurọ yoo se ri, paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti pa wọn run.
وَمِنۡهُم مَّن يُؤۡمِنُ بِهِۦ وَمِنۡهُم مَّن لَّا يُؤۡمِنُ بِهِۦۚ وَرَبُّكَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُفۡسِدِينَ 40
Nbẹ ninu awọn ẹlẹbọ ẹniti yoo nigbagbọ si Alukuraani siwaju iku rẹ, o si wa ninu wọn ẹniti ko nii nigbagbọ sii niti isorikunkun ati igberaga titi ti yoo fi ku, bẹẹ ni Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - nimọ ju si ẹniti o taku lori keferi ninu wọn, yoo si san wọn lẹsan lori keferi wọn.
وَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل لِّي عَمَلِي وَلَكُمۡ عَمَلُكُمۡۖ أَنتُم بَرِيُٓٔونَ مِمَّآ أَعۡمَلُ وَأَنَا۠ بَرِيٓءٞ مِّمَّا تَعۡمَلُونَ 41
Ti awọn ijẹ rẹ - irẹ ojisẹ - ba pe ọ nirọ, ki o sọ fun wọn: ẹsan isẹẹ mi nbẹ fun mi, maa si farada ohun ti o ba ti ẹyin rẹ yọ, bẹẹ ni ẹsan isẹẹ yin nbẹ fun yin, ẹyin ni ẹ si ni iya rẹ, ẹyin bọpa bọsẹ kuro nibi iy nkan ti mo ba se, bẹẹ ni emi naa jẹ ẹniti o mori bọ kuro nibi ijiya ohun ti ẹ ba se.
وَمِنۡهُم مَّن يَسۡتَمِعُونَ إِلَيۡكَۚ أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ وَلَوۡ كَانُواْ لَا يَعۡقِلُونَ 42
O wa ninu awọn ẹlẹbọ ẹniti ntẹti gbọ - irẹ ojisẹ - nigbati o ba nka Alukuraani niti gbigbọ aisetan lati gba tabi tẹriba, se o lagbara lati fun ẹniti a gba igbọran rẹ lọrọ gbọ bi?! Gẹgẹ bẹẹ naa ni o ko lagbara lati fi mọna ẹniti a jẹ aditi lati gbọ ododo, wọn ko le gbọ ọ ye.
Olufinimọna si ibi ododo ni ifinimọna ti kongẹ Oun ni Allah nikan soso yatọ si ẹlomiran.
Siseni loju kokoro lori wiwa awọn ẹri ati awọn awijare ati awọn itọnisọna lati debi imọna ati ododo ati gbigbe roiroi ju silẹ ati ero.
Ko si ninu agbara ẹnikẹni lati mu nkan ti ko ju aayah lọ wa gẹgẹ bi Alukuraani alapọnle titi yoo fi di ọjọ igbende.
Awọn ẹlẹbọ jẹ omugọ, wọn si jẹ olupe nkan ti wọn ko gbọye tabi ronu si ni irọ.