وَإِذَا مَسَّ ٱلنَّاسَ ضُرّٞ دَعَوۡاْ رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَآ أَذَاقَهُم مِّنۡهُ رَحۡمَةً إِذَا فَرِيقٞ مِّنۡهُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ 33
Ti inira ba kan awọn ẹlẹbọ ninu aarẹ tabi osi tabi ọda wọn yoo pe Ọlọhun Ọba wọn ti mimọ nbẹ fun nikan soso ni ẹniti yoo sẹri lọ si ọdọ Rẹ pẹlu ifararolẹ ati ilugọ, ki O le yi ohun ti o kan wọn kuro fun wọn, lẹyin naa ti o ba kẹ wọn pẹlu mimu ohun ti o kan wọn kuro lojiji ni ijọ kan ninu wọn yoo sẹri lọ si ibi imu akẹgbẹ miran pẹlu Allah nibi adua.
لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ 34
Ti wọn ba se aimoore si idẹkun Allah - ninu rẹ ni idẹkun mimu inira kuro - ti wọn si ngbadun pẹlu ohun ti nbẹ lọwọ wọn ninu isẹmin aye, wọn yoo pada fi oju wọn ri ni ọjọ igbende wipe oju ọna anu ti han ni awọn wa.
أَمۡ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٗا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُواْ بِهِۦ يُشۡرِكُونَ 35
Kinni o pe wọn lọ si ibi sisẹbọ pẹlu Allah ti ko si awijare fun wọn?! A ko sọ ẹri kalẹ ninu iwe ti wọn yoo fi wi awijare wọn lori sisẹbọ wọn pẹlu Allah, bẹẹni ko si iwe kankan pẹlu wọn ti o sọ nipa sise ẹbọ wọn ti yoo fi lilalaafia keferi ti wọn wa lori rẹ rinlẹ fun wọn.
وَإِذَآ أَذَقۡنَا ٱلنَّاسَ رَحۡمَةٗ فَرِحُواْ بِهَاۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ إِذَا هُمۡ يَقۡنَطُونَ 36
Ti A fi idẹkun tọ awọn eniyan lẹlu wo ninu awọn idẹkun Wa gẹgẹ bi alaafia ati ọrọ, wọn yoo yọ pẹlu rẹ ni ayọ pọrọ ati igberaga, ti ohun ti ko wu wọn ninu aarọ ba kan wọn tabi osi lati ara ohun ti wọn fi ọwọ ara wọn da ninu ẹsẹ lojiji ni wọn yoo jakan kuro nibi ikẹ Allah, wọn yoo si tun jakan kuro nibi yiyẹ kuro ohun ti nko aburu ba wọn yii.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 37
Se wọn ko ri ni wipe dajudaju Allah gbaye arisiki fun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ niti sise idanwo fun un boya yoo dupẹ tabi yoo se aimoore? O si ma nfun un mọ ẹniti o ba wu U niti sise adanwo fun un boya yoo se suuru tabi yoo binu?! Dajudaju nibi gbigbaye arisiki mọ apakan ati fifun mọ apakan jẹ awọn itọka fun awọn olugbagbọ ododo lori aanu Allah ati ikẹ Rẹ.
فََٔاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجۡهَ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ 38
Ki o yaa fun - irẹ Musulumi - alasunmọ ni ounti o lẹtọ si ni rere ati idapọ, ki o si fun onibeere ni oun irankan rẹ, ki o si fun ajoji ti oju ọna ti tan mọ lọwọ kuro ni ilu rẹ ni ọrẹnta naa ni ojupọnna naa, o loore fun awọn ti ngbero oju rere Allah, awọn ti wọn nti iranlọwọ ati ẹtọ yii siwaju, awọn ni yoo jere pẹlu titẹlọwọ ounti wọn nbeere fun ni ọgba idẹra, ni wọn yoo si la nibi ounti ndẹru ba wọn ninu iya.
Nigbati wọn salaye ohun ti wọn le fi sun mọ Allah ninu isẹ, O tun salaye ohun ti wọn le fi gbero ohun tii se oju rere Ọlọhun, ohun ti wọn gbalero pẹlu nrẹ ni adisọkan aye ti ko niye lori, O wa sọpe:
وَمَآ ءَاتَيۡتُم مِّن رِّبٗا لِّيَرۡبُوَاْ فِيٓ أَمۡوَٰلِ ٱلنَّاسِ فَلَا يَرۡبُواْ عِندَ ٱللَّهِۖ وَمَآ ءَاتَيۡتُم مِّن زَكَوٰةٖ تُرِيدُونَ وَجۡهَ ٱللَّهِ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُضۡعِفُونَ 39
Ohun ti ẹ ba na ninu dukia fun ẹnikẹni ninu eniyan ni erongba ki o le da pada fun yin niti ilekun, ẹsan rẹ ko le gberu ni ọdọ Allah, sugbọn ohun ti ẹ ba na ninu dukia yin fun ẹniti yoo fi se anfaani, ti ẹ si gbero oju rere Allah pẹlu rẹ, ti ẹ ko gbero ipo tabi ẹsan ni ọdọ eniyan, awọn eleyi ni awọn ti wọn yoo se adipele fun yin ni ọdọ Allah.
ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ ثُمَّ رَزَقَكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡۖ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَفۡعَلُ مِن ذَٰلِكُم مِّن شَيۡءٖۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 40
Allah nikan ni O jẹ oosa nibi isẹda yin ati isejẹ imu yin, lẹyin naa ni pipa yin ati jiji yin fun igbende, njẹ ninu awọn ẹbọ yin ti ẹ nsin yatọ si I le se ikankan ninu eleyi bi?! Mimọọ Rẹ, O si mọ kanga kuro nibi ẹlẹbọ nsọ, ti o si di sọkan.
ظَهَرَ ٱلۡفَسَادُ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ بِمَا كَسَبَتۡ أَيۡدِي ٱلنَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعۡضَ ٱلَّذِي عَمِلُواْ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 41
Ibajẹ han lori ilẹ ati ori omin, gẹgẹ bi ọda ati rirọ ojo diẹdiẹ ati ọpọlọpọ aarẹ ati ajakalẹ arun nitori ounti wọn se ninu ẹsẹ, eleyi han ki Allah le fi ẹsan apakan isẹ ti wọn se ni aida ni isẹmin aye tọ wọn lẹnu wo ni irankan ki wọn le sẹri lọ si ọdọ Rẹ ni ironu piwada.
Yiyọ ayọ pọrọ nigba idẹkun, ati jijakan kuro nibi ikẹ nigba inira; jẹ iroyin meji kan ninu awọn iroyin keferi.
Fifun awọn ti wọn lẹtọ ni ẹtọ wọn jẹ okunfa ere.
Pipa owo ele run ati sise adipele ẹsan inawo si oju ọna Allah.
Oripa ẹsẹ wa nibi fifanka ajakalẹ arun ati rirun agbegbe ti a fi oju ri.