وَلَا يَأۡتُونَكَ بِمَثَلٍ إِلَّا جِئۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ وَأَحۡسَنَ تَفۡسِيرًا 33
Awọn ẹlẹbọ ko nii mu wa fun ọ -irẹ ojisẹ- iru ohun ti wọn hun ahunjọ rẹ yii ayaafi ki wọn mu esi ododo ti o rinlẹ wa le lori tabi ki wọn mu ohun ti o da lalaye julọ wa fun ọ.
ٱلَّذِينَ يُحۡشَرُونَ عَلَىٰ وُجُوهِهِمۡ إِلَىٰ جَهَنَّمَ أُوْلَٰٓئِكَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضَلُّ سَبِيلٗا 34
Awọn ti wọn daa lọ si inu jahanamọ ni ọjọ igbende, wọn yoo fi oju wọn wọ wọn nilẹ lọsi ibẹ, awọn wọnyi ni wọn wa ni aaye aburu ju; nitoripe dajudaju aaye wọn ni jahanamọ, ohun ni ọna rẹ jinna si ododo ju; nitoripe ọna wọn ni ọna keferi ati anu.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَجَعَلۡنَا مَعَهُۥٓ أَخَاهُ هَٰرُونَ وَزِيرٗا 35
Paapa a si ti fun Musa ti Taoreeta, a si sọ ọmọ iya rẹ haruna di ojisẹ pẹlu rẹ ki o le jẹ olukunlọwọ fun un.
فَقُلۡنَا ٱذۡهَبَآ إِلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا فَدَمَّرۡنَٰهُمۡ تَدۡمِيرٗا 36
A si sọ fun awọn mejeeji: ẹ lọ si ọdọ fir'aona ati ijọ rẹ, awọn ti wọn pe awọn amin Wa ni irọ, wọn si tẹle asẹ Wa, wọn si lọ si ọdọ wọn, wọn si pe wọn lọ si ibi ijọkan soso Allah, wọn wa pe wọn nirọ, a si pa wọn run ni iparun ti o le koko.
وَقَوۡمَ نُوحٖ لَّمَّا كَذَّبُواْ ٱلرُّسُلَ أَغۡرَقۡنَٰهُمۡ وَجَعَلۡنَٰهُمۡ لِلنَّاسِ ءَايَةٗۖ وَأَعۡتَدۡنَا لِلظَّٰلِمِينَ عَذَابًا أَلِيمٗا 37
Ijọ Nuha nigbati wọn pe ojisẹ naa nirọ niti pipe Nuha nirọ eniti ọla nbẹ fun, a fi itẹri sinu odo pa wọn run, a si sọ iparun wọn di itọka lori agbara Wa nipa awọn alabosi finfin, a si pese fun awọn alabosi iya inira ni ọjọ igbende.
وَعَادٗا وَثَمُودَاْ وَأَصۡحَٰبَ ٱلرَّسِّ وَقُرُونَۢا بَيۡنَ ذَٰلِكَ كَثِيرٗا 38
A pa ‘Adu tii se ijọ Huud run ati thamuudu tii se ijọ Sọlihu, bẹẹni a pa awọn ẹni kanga run, a si tun pa awọn ijọ ti o pọ laarin awọn mẹta yii run.
وَكُلّٗا ضَرَبۡنَا لَهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَۖ وَكُلّٗا تَبَّرۡنَا تَتۡبِيرٗا 39
Gbogbo awọn ti a pa run yii, a royin iparun iru awọn ijọ ti o siwaju fun un ati awọn okunfa rẹ ki wọn le gba isiti, gbogbo wọn ni a parun ni iparun ti o le koko nitori keferi wọn ati ori kunkun wọn.
وَلَقَدۡ أَتَوۡاْ عَلَى ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِيٓ أُمۡطِرَتۡ مَطَرَ ٱلسَّوۡءِۚ أَفَلَمۡ يَكُونُواْ يَرَوۡنَهَاۚ بَلۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ نُشُورٗا 40
Paapa awọn opurọ ninu ijọ rẹ ti wa - nibi lilọ wọn si Samu - si abule ijọ Luth eyiti wọn rọ joj okuta le lori; ni ijiya fun wọn lori isẹ ibajẹ wọn, ki wọn le ri ariwoye, se wọn fọju nipa awọn abule naa ni, ti wọn ko fi fi oju ganni wọn? Rara, bikosepe wọn ko fọkan si igbende ti wọn yoo fi se isiro lẹyin rẹ.
وَإِذَا رَأَوۡكَ إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا ٱلَّذِي بَعَثَ ٱللَّهُ رَسُولًا 41
Nigbati awọn opurọ yii ba pade rẹ - irẹ ojisẹ - wọn yoo maa fi ọ se yẹyẹ ni ẹniti o sọrọ ni ojupọnna ifini se yẹyẹ ati ikorira: se eleyi ni ẹniti Allah gbe dide ni ojisẹ si wa?!
إِن كَادَ لَيُضِلُّنَا عَنۡ ءَالِهَتِنَا لَوۡلَآ أَن صَبَرۡنَا عَلَيۡهَاۚ وَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ حِينَ يَرَوۡنَ ٱلۡعَذَابَ مَنۡ أَضَلُّ سَبِيلًا 42
Paapa o ti fẹ yiwa kuro nibi ijọsin awọn ọlọhun wa, ti kii ba se wipe a se suuru lori ijọsin rẹ ki ba yi wa kuro nibẹ pẹlu awọn awijare ati awọn ẹri rẹ, wọn yoo si pada mọ nigbati wọn ba nfi ara ki iya naa ninu saare wọn ati ni ọjọ igbende, taani ẹniti o sọnu kuro ni oju ọna ju, se awọn ni abi iwọ? Wọn yoo si pada mọ ẹniti o sọnu ju.
أَرَءَيۡتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَٰهَهُۥ هَوَىٰهُ أَفَأَنتَ تَكُونُ عَلَيۡهِ وَكِيلًا 43
Se o ri - irẹ ojisẹ - ẹniti o sọ ifẹ inu rẹ di ọlọhun, ti o si ntẹle e, se iwọ ni oo jẹ olusọ fun un ti yoo da pada si ibi igbagbọ tabi kọ fun nibi keferi?!
Sise keferi si Allah ati pipe awọn amin Rẹ nirọ jẹ okunfa iparun awọn ijọ.
Sise afẹku igbagbọ si igbende jẹ okunfa aigba isiti.
Fifi awọn ẹni ododo se yẹyẹ jẹ isesi awọn keferi.
Ewu titẹle ifẹ inu.