يُرِيدُونَ أَن يُطۡفُِٔواْ نُورَ ٱللَّهِ بِأَفۡوَٰهِهِمۡ وَيَأۡبَى ٱللَّهُ إِلَّآ أَن يُتِمَّ نُورَهُۥ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡكَٰفِرُونَ 32
Awọn keferi wọnyi ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn ti wọn wa ni oju ọna awọn keferi pẹlu adapa irọ wọnyi ati pipe ohun ti Muhammad muwa ni irọ ngbero lati da oju Islam bolẹ ati lati baa jẹ, ati lati ba gbogbo ẹri ti o fi oju han ati awọn awijare eyiti o han de lori jijẹ ọkan soso Allah, ati wipe dajudaju ohun ti ojisẹ naa muwa jẹ ododo, Ọlọhun Ọba Allah si ti taku lori pipe ẹsin Rẹ ati sise afihan rẹ, ati gbigbe E lori ohun ti o yatọ si I koda bi awọn keferi kọ lori pipe ẹsin Rẹ ati sise afihan rẹ gbigbe E ga, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo pe e, Yoo si gbe e ga, ti Ọlọhun Ọba Allah ba gbero nkankan kan, erongba ẹniti o yatọ si yoo bajẹ ni.
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلۡهُدَىٰ وَدِينِ ٱلۡحَقِّ لِيُظۡهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُشۡرِكُونَ 33
Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun ni o ran ojisẹ Rẹ tii se Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun pẹlu alukuraani eyiti o jẹ imọna fun awọn eniyan, ati pẹlu ẹsin ododo eyiti o jẹ ẹsin Islam lati le gbe e ga nitori awọn awijare ati awọn ẹri ati awọn idajọ lori ohun ti o yatọ si ninu awọn ẹsẹ koda bi awọn ẹlẹbọ korira eleyi.
۞يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡأَحۡبَارِ وَٱلرُّهۡبَانِ لَيَأۡكُلُونَ أَمۡوَٰلَ ٱلنَّاسِ بِٱلۡبَٰطِلِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۗ وَٱلَّذِينَ يَكۡنِزُونَ ٱلذَّهَبَ وَٱلۡفِضَّةَ وَلَا يُنفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَبَشِّرۡهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٖ 34
Ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ, ti wọn si nse ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se lofin fun wọn, dajudaju ọpọ ninu awọn onimimọ yahuudi ati ọpọ ninu awọn ti nassara njọsin fun, wọn yoo maa mu dukia awọn eniyan ni ọna ti ko ba ofin mu, wọn nmu niti owo ẹyin, ati ohun ti o yatọ si, wọn si nkọ fun awọn eniyan lati wọ inu ẹsin. Awọn ti wọn ko wura ati fadaka jọ, ti wọn kii yọ saka ti o jẹ ọranyan fun wọn, fun wọn niro - ire ojise - ohun ti yoo ko aburu ba wọn ni ọjọ igbende ninu iya ẹlẹta ero.
يَوۡمَ يُحۡمَىٰ عَلَيۡهَا فِي نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكۡوَىٰ بِهَا جِبَاهُهُمۡ وَجُنُوبُهُمۡ وَظُهُورُهُمۡۖ هَٰذَا مَا كَنَزۡتُمۡ لِأَنفُسِكُمۡ فَذُوقُواْ مَا كُنتُمۡ تَكۡنِزُونَ 35
Ni ọjọ igbende, wọn yoo jo nkan ti wọn kojọ nina ati ohun ti wọn kọ lati fun awọn eniyan ninu ina jahanamọ nigbati igbona ibẹ ba le, wọn yoo da oju wọn kọ ati ẹgbẹ wọn ati ẹyin wọn, wọn yoo waa maa sọ fun niti ifinise yẹyẹ eleyi ni awọn dukia yin ti ẹ ko jọ, ti ẹ ko pe iwọ ti o jẹ ọranyan nibẹ, ki ẹ ya maa tọ aburu nkan ti ẹ ko jọ wo, ti ẹ ko si pe iwọ rẹ ati igbẹyin rẹ.
إِنَّ عِدَّةَ ٱلشُّهُورِ عِندَ ٱللَّهِ ٱثۡنَا عَشَرَ شَهۡرٗا فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ يَوۡمَ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ مِنۡهَآ أَرۡبَعَةٌ حُرُمٞۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُۚ فَلَا تَظۡلِمُواْ فِيهِنَّ أَنفُسَكُمۡۚ وَقَٰتِلُواْ ٱلۡمُشۡرِكِينَ كَآفَّةٗ كَمَا يُقَٰتِلُونَكُمۡ كَآفَّةٗۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ 36
Dajudaju onka awọn osu inu ọdun ninu idajọ ti Ọlọhun Ọba Allah ati eto Rẹ jẹ osu mejila nibi nkan ti Allah fi rinlẹ nibi ọpọn ti a nsọ, ti o jẹ akọkọ nkan ti Ọlọhun Ọba da ni sanmọ ati ilẹ, ninu awọn osu mejila yii, Ọlọhun Ọba se mẹrin ni eewọ jijagun nibẹ, ohun naa ni mẹta ti o tẹle ara wọn: (Dhul Qa'adah, Dhul Hijjah ati Muharọm), ti ẹyọkan si da duro, ohun naa (Rọjab). Eyiti a darukọ ninu onka osu ọdun yii nibi sise mẹrin ni eewọ o jẹ ẹsin ti o duro tọ, ẹ ko gbọdọ se abosi ẹmin ara yin ninu awọn osu ọwọ naa pẹlu ki ẹ maa ba ara yin ja nibẹ, tabi ki ẹ fa ọwọ rẹ ya, ki ẹ maa ba awọn ọlọsẹbọ logun lapapọ gẹgẹ bi awọn naa se ma nja yin logun lapapọ, ki ẹ lọọ mọ wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nbẹ pẹlu awọn ti o nbẹru Rẹ pẹlu titẹle asẹ ti O pa ati jijinna si ohun ti O kọ niti aranse ati iduro sinsin, ẹniti Allah ba wa pẹlu rẹ ẹnikankan ko le bori rẹ.
Ẹsin Allah yoo han yoo si ri aranse biotiwulẹ ki awọn ọta o sare lati gbẹsan lara rẹ niti keeta lati ọdọ wọn.
Jijẹ eewọ jijẹ dukia awọn eniyan niti ibajẹ ati kikọdi oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ti o ga julọ.
Jijẹ eewọ fifi dukia pamọ laini na si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah.
Sise loju kokoro lori ipaya Ọlọhun Ọba Allah ni kọrọ ati gbangba, pataki julọ ni igba igbogunti awọn keferi, nitori wipe dajudaju olugbagbọ ododo gbọdọ maa paya ni gbogbo asiko rẹ.