أَمۡ تَأۡمُرُهُمۡ أَحۡلَٰمُهُم بِهَٰذَآۚ أَمۡ هُمۡ قَوۡمٞ طَاغُونَ 32
Tabi laakaye wọn ni o npa wọn lasẹ pẹlu gbolohun wọn: dajudaju o jẹ alagbegba ati were?! Wọn wa ko nkan ti ko see ko papọ si ara eniyan, bikosepe wọn jẹ ijọ ti o kọja ẹnu aala, wọn ko le sẹri lọsi ibi ofin tabi laakaye.
أَمۡ يَقُولُونَ تَقَوَّلَهُۥۚ بَل لَّا يُؤۡمِنُونَ 33
Tabi wọn nsọ wipe: dajudaju Muhammad hun Alukuraani yii ni, wọn ko ransẹ imisi rẹ si?! Ko hun bikosepe awọn oluisegberaga kuro nibi igbagbọ si I, wọn yoo wa maa sọpe: o hun ni.
فَلۡيَأۡتُواْ بِحَدِيثٖ مِّثۡلِهِۦٓ إِن كَانُواْ صَٰدِقِينَ 34
ki wọn ya mu ọrọ miran wa ti o jọ ọ, ki baa jẹ nkan hihun, ti wọn ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti wọn npe apemọra rẹ wipe o hun ni.
أَمۡ خُلِقُواْ مِنۡ غَيۡرِ شَيۡءٍ أَمۡ هُمُ ٱلۡخَٰلِقُونَ 35
Tabi wọn da wọn lati ibi aisi asẹda ti o da wọn ni?! Tabi awọn ni asẹda ara wọn?! Ko rọrun ki a ri ẹniti a da laisi asẹda, ko si si ẹniti a da ti o da ẹda, kilode ti wọn ko sin ẹniti o sẹda wọn?!
أَمۡ خَلَقُواْ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۚ بَل لَّا يُوقِنُونَ 36
Tabi wọn da gbogbo sanmọ ati ilẹ ni?! Bikosepe wọn ko mọ amọdaju wipe dajudaju Allah ni asẹda wọn nitoripe ti wọn ba mọ amọdaju eleyi wọn ko ba mu U ni ọkan soso, wọn ko ba si gba ojisẹ Rẹ gbọ.
أَمۡ عِندَهُمۡ خَزَآئِنُ رَبِّكَ أَمۡ هُمُ ٱلۡمُصَۜيۡطِرُونَ 37
Tabi pẹpẹ ọrọ Ọlọhun Ọba rẹ ninu arisiki nbẹ lọdọ wọn, ti wọn wa fi nta ẹniti o wu wọn lọrẹ gẹgẹ bi ijẹ anọbi ti wọn fun, ti wọn si nkọ ọ fun ẹniti wọn ba gbero? Tabi awọn ni ẹniti ijẹgaba ti o le se bi o ti wu u ni ibamun si bi wọn ti fẹ?!
أَمۡ لَهُمۡ سُلَّمٞ يَسۡتَمِعُونَ فِيهِۖ فَلۡيَأۡتِ مُسۡتَمِعُهُم بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ 38
Tabi akaba nbẹ fun wọn le gun un lọ si sanmọ, ti wọn yoo maa tibẹ gbọ imisi Allah, ti yoo fi fi ransẹ si wọn wipe wọn wa lori ododo?! Ki wọn ya mu wa ẹniti o ba tẹti gbọ imisi pẹlu awijare ti o fi oju han eleyi ninu wọn ti yoo pe yin lootọ lori ohun ti ẹ npe apemọra rẹ wipe ori ododo ni ẹ wa.
أَمۡ لَهُ ٱلۡبَنَٰتُ وَلَكُمُ ٱلۡبَنُونَ 39
Tabi Oun ti mimọ nbẹ fun ni o ni awọn ọmọbinrin eyiti ẹyin korira, ti yin si awọn ọmọkunrin ti ẹ nifẹ si wọn?!
أَمۡ تَسَۡٔلُهُمۡ أَجۡرٗا فَهُم مِّن مَّغۡرَمٖ مُّثۡقَلُونَ 40
Tabi oun wa ni ọdọ wọn - irẹ ojisẹ - ẹsan lori ohun ti o fi nde etigbọ wọn lati ọdọ Ọlọhun rẹ?! Nitori eleyi wọn jẹ ẹniti a la ẹru ti o wuwo bọ lọrun, ti wọn ko lagbara lori gbigbe rẹ.
أَمۡ عِندَهُمُ ٱلۡغَيۡبُ فَهُمۡ يَكۡتُبُونَ 41
Tabi imọ kọkọ nbẹ lọdọ wọn, ti wọn wa nkọ ohun ti wọn bojuwo ninu kọkọ fun awọn eniyan, ti wọn wa nfun wọn niro ohun ti wọn ba fẹ ninu rẹ?!
أَمۡ يُرِيدُونَ كَيۡدٗاۖ فَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ هُمُ ٱلۡمَكِيدُونَ 42
Tabi awọn eniyan opurọ yii ngbero ete si ọ ati ẹsẹ rẹ ni?! Ki o ya gbarale Allah, awọn ti wọn se aimoore si Allah ati si ojisẹ Rẹ ni ẹniti ete yoo jẹ tirẹ, kii se iwọ.
أَمۡ لَهُمۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 43
Tabi ẹni ijọsin fun ti ododo yatọ si Allah nbẹ fun wọn ni?! Allah mọ, O si mọ kanga nipa ohun ti wọn nse afiti rẹ si ọdọ Rẹ ni akẹgbẹ, gbogbo ohun ti o re kọja ko ri bẹẹ, ko si ni isesi ti o fi le ri bẹẹ.
وَإِن يَرَوۡاْ كِسۡفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ سَاقِطٗا يَقُولُواْ سَحَابٞ مَّرۡكُومٞ 44
Ti wọn ba ri egige kan ti o jabọ lati sanmọ, wọn yoo sọ nipa rẹ wipe: eleyi ni ẹsujo ti apakan rẹ gbe apakan rẹ pọn gẹgẹ bi adamọ, wọn ko gba isiti bẹẹni wọn ko ni igbagbọ.
فَذَرۡهُمۡ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي فِيهِ يُصۡعَقُونَ 45
Gbe wọn ju silẹ - irẹ ojisẹ - nibi orikunkun wọn ati iyan wọn ti wọn yoo fi pade ọjọ wọn ti wọn yoo fi iya jẹ wọn nibẹ, ohun si ni ọjọ igbende.
يَوۡمَ لَا يُغۡنِي عَنۡهُمۡ كَيۡدُهُمۡ شَيۡٔٗا وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ 46
Ọjọ ti ete wọn ko nii rọ wọn lọrọ kankan, o kere ni tabi o pọ, wọn ko si nii ri aranse nibi lila wọn kuro nibi iya naa.
وَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ عَذَابٗا دُونَ ذَٰلِكَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 47
Dajudaju iya kan siwaju iya ti ọrun nbẹ fun awọn ti wọn abosi ẹmin ara wọn pẹlu ẹbọ sise ati awọn ẹsẹ; ni ile aye pẹlu pipa ati imu lẹru, bẹẹni iya inu saare nbẹ fun ni agedfe meji, sugbọn ọpọ wọn ko mọ eleyi, tori bẹẹ ni wọn fi duro lori keferi wọn.
Nigbati Allah salaye ijẹ ibajẹ ohun ti awọn ẹlẹbọ wa lori rẹ, O pa ojisẹ Rẹ lasẹ ki o ma ko akolekan wọn, ki o si se suuru lori irọ ti wọn npa mọ, O wa sọpe:
وَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ فَإِنَّكَ بِأَعۡيُنِنَاۖ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ حِينَ تَقُومُ 48
Se suuru - irẹ ojisẹ - fun akọsilẹ Ọlọhun rẹ ati idajọ Rẹ ti o jẹ ofin dajudaju o wa ni ipo ẹniti a nwo, ti a si nsọ, ki o si se afọmọ pẹlu ki o dupẹ fun Ọlọhun Ọba rẹ nigbati o ba dide ni oju oorun rẹ.
وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡهُ وَإِدۡبَٰرَ ٱلنُّجُومِ 49
Ti o ba si di ni oru ki o se afọmọ fun Ọlọhun Ọba rẹ, ki o si kirun fun Un, ki o si ki irun idaji nigbati irawọ ba pẹyin da pẹlu wiwọ rẹ niti mimu imọlẹ salọ.
Ikọja ẹnu aala jẹ okunfa kan ninu awọn okunfa anu.
Pataki iyan jija pẹlu laakaye nbẹ nibi fifi awọn ododo ẹsin rinlẹ.
Ririnlẹ iya agede meji.