مِنۡ أَجۡلِ ذَٰلِكَ كَتَبۡنَا عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَنَّهُۥ مَن قَتَلَ نَفۡسَۢا بِغَيۡرِ نَفۡسٍ أَوۡ فَسَادٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ ٱلنَّاسَ جَمِيعٗا وَمَنۡ أَحۡيَاهَا فَكَأَنَّمَآ أَحۡيَا ٱلنَّاسَ جَمِيعٗاۚ وَلَقَدۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡأَرۡضِ لَمُسۡرِفُونَ 32
Nitori pipa ti kọọbiila pa ọmọ iya rẹ, awa fi mọ ọmọ isirẹli pe dajudaju ẹniti o ba pa ẹmin kan laini idi niti gbigba ẹsan ntabi sise ibajẹ si ori ilẹ niti sise keferi, tabi jijagun, o da gẹgẹ bi ẹniti o pa gbogbo ẹniyan ni; toripe ko onpinya ni ọdọ Rẹ ẹniti o bọpa-bọsẹ ati ẹlẹsẹ, ẹnikẹni ti o ba kọ lati pa ẹmin kan eyiti Ọlọhun Ọba Allah se ni eewọ n iti didi adisọkan ọwọ pipaa sugbọn ti ko waa pa; o da gẹgẹ bi ẹniti o ji gbogbo eniyan; nitori wipe ohun ti o se yii jẹ ọla fun gbogbo wọn, paapaa awọn ojisẹ wa ti waa ba awọn bani israheel pẹlu ẹri ti o yanju ati awọn awijare eyiti o gban gban, sugbọn pẹlu gbogbo awọn nkan wọnyi, ọpọlọpọ ninu wọn tun kọja ẹnu aala ti Ọlọhun Ọba Allah pẹlu dida ẹsẹ, ati yiyapa awọn ojisẹ wọn.
إِنَّمَا جَزَٰٓؤُاْ ٱلَّذِينَ يُحَارِبُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَسۡعَوۡنَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَسَادًا أَن يُقَتَّلُوٓاْ أَوۡ يُصَلَّبُوٓاْ أَوۡ تُقَطَّعَ أَيۡدِيهِمۡ وَأَرۡجُلُهُم مِّنۡ خِلَٰفٍ أَوۡ يُنفَوۡاْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِۚ ذَٰلِكَ لَهُمۡ خِزۡيٞ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ 33
kinni igbẹyin awọn ti wọn nja Ọlọhun Ọba Allah logun ati ojisẹ Rẹ, wọn si nfi ijọta han ati ibalẹjẹ pẹlu pipa awọn eniyan ati gbigba dukia pẹlu didana; ayaafi ki wọn pa wọn laini kan wọn mọ agbelebu, tabi ki wọn pa wọn pẹlu kikan wọn mọ agbelebu igi ati ohun ti o jọ iru rẹ, tabi ki wọn o ge ọwọ wọn ọtun pẹlu ẹsẹ osi, lẹyin igba naa ti wọn ba tun sẹri sibẹ, ki wọn ge ọwọ osi ẹsẹ ọtun, tabi ki wọn le wọn kuro ni ilu; iya naa yoo jẹ iyẹpẹrẹ ni ile aye, bakanna ni iya ti o tobi nbẹ fun wọn ni ọrun.
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ مِن قَبۡلِ أَن تَقۡدِرُواْ عَلَيۡهِمۡۖ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 34
Ayaafi awọn ti wọn ba jawọ ninu awọn eniyan ti o njagun siwaju agbara yin - ẹyin alasẹ - le wọn lori, ki ẹ lọọ mọ wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ alaforijin fun yin lẹyin ironu piwada, O si jẹ olukọ fun wọn, ninu ikẹ Rẹ si wọn ni mimu iya kuro fun wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱبۡتَغُوٓاْ إِلَيۡهِ ٱلۡوَسِيلَةَ وَجَٰهِدُواْ فِي سَبِيلِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 35
Ẹyin olugbagbọ ododo, ẹ bẹru Ọlọhun Ọba Allah pẹlu jijnna si nkan ti O kọ, ki ẹ si ya isunmọ Rẹ pẹlu sise ohun ti o payin lasẹ, ati jijnna si nkan ti O le yin sa kuro nibẹ, ki ẹ maa ja awọn keferi logun pẹlu wiwa iyọnu Rẹ; o seese ki ọwọ yin tẹ nkan ti ẹ nwa, bẹẹni ki ẹ si jinna si nkan ti ẹ nsọra fun nigbati ẹ ba see.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ أَنَّ لَهُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا وَمِثۡلَهُۥ مَعَهُۥ لِيَفۡتَدُواْ بِهِۦ مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَا تُقُبِّلَ مِنۡهُمۡۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 36
Dajudaju awọn ti wọn se aimoore si Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, koda bi ikapa ilẹ ni apapọ ati deede rẹ ba wa pẹlu rẹ fun wọn tabi jẹ ti wọn, ti wọn wa ti siwaju gẹgẹ bi idaabobo kuro nibi iya ni ọjọ igbende, wọn ko nii gba ifidi naa lọwọ rẹ, iya itara nbẹ fun wọn.
Nini ọwọ ẹmin ọmọniyan, ati wipe dajudaju ẹniti o ba daabobo tabi o taa ji, o da gẹgẹ bi ẹniti o se eyi fun gbogbo abara, bẹẹ naa ni ẹniti o ba se ẹmin ọmọniyan ni ofo tabi o fi suta se laini ẹtọ, o da gẹgẹ bi ẹniti o se fun gbogo eniyan lapapọ.
Ijiya awọn ti wọn ja Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ logun ninu awọn ti wọn nbalẹ jẹ pẹlu ipaniyan tabi jiji dukia ati idana ni: pipawọn laikan wọn, tabi pẹlu kikan wọn, tabi gige apakan nipayọ, tabi lile wọn jinna kuro ninu ilu ni ibamun si ohun ti o ba sẹlẹ lati ọdọ wọn.
Ironu piwada awọn olubilẹjẹ ninu awọn olugbe ogun ti Ọlọhun Ọba Allah ati awọn danadana siwaju ki awọn alasẹ too gba wọn, yoo se okunfa amojukuro fun wọn.