وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلۡجَوَارِ فِي ٱلۡبَحۡرِ كَٱلۡأَعۡلَٰمِ 32
Ninu awọn amin Allah eyiti o ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ ni ọkọ oju omin eyiti o nrin ni ori omin gẹgẹ bi oke nibi giga rẹ ati yiyọ.
إِن يَشَأۡ يُسۡكِنِ ٱلرِّيحَ فَيَظۡلَلۡنَ رَوَاكِدَ عَلَىٰ ظَهۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٍ 33
Ti Allah ba gbero didakẹ atẹgun eyiti o nmu rin, ki ba da lakẹ, dajudaju nibi eyiti a sọ yii gẹgẹ bi awọn isẹda ọkọ oju omin ati rirọ awọn atẹgun jẹ awọn itọka ti o fi oju han lori agbara Allah fun gbogbo onissuru lori adanwo ati idaamun, ti o si jẹ oludupẹ fun awọn idẹkun Allah le lori.
أَوۡ يُوبِقۡهُنَّ بِمَا كَسَبُواْ وَيَعۡفُ عَن كَثِيرٖ 34
Tabi ti mimọ Rẹ ba fẹ lati pa awọn ọkọ oju omin naa run pẹlu ki o ran atẹgun igi si i, ki ba pa a run, nitori ẹsẹ ti awọn eniyan ti da, O si nse amojukuro nibi ọpọ ẹsẹ awọn ẹru Rẹ ti ko fi iya jẹ wọn le lori.
وَيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ 35
O si mọ awọn ti O nja awọn aayah Rẹ niyan lati ba a jẹ ni igbati O ba fẹ pa awọn ọkọ oju ọmin naa run pẹlu riran atẹgun igi si wọn wipe ko si ibusalọ fun wọn kuro nibi iparun naa, wọn ko le pe ẹnikankan ayaafi Allah, wọn yoo gbe ẹniti o yatọ si I ju silẹ.
فَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَيۡءٖ فَمَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ 36
Ohun ti wọn ba fun yin - ẹyin eniyan - gẹgẹ bi dukia tabi iyi tabi ọmọ, igbadun isẹmin aye ni o jẹ, yoo si yẹ ti yoo tan, sugbọn idẹkun gbere ni idẹkun ọgba idẹra eyiti Allah pese fun awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si gbarale Ọlọhun Ọba wọn nikan nibi gbogbo ọrọ wọn.
وَٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُواْ هُمۡ يَغۡفِرُونَ 37
Awọn ti wọn ntakete si awọn ẹsẹ nla ati eyiti o buru ninu rẹ, ti wọn ba binu si ẹniti o se asise si wọn pẹlu gbolohun tabi isẹ, wọn yoo se amojukuro ikọsẹ rẹ fun, wọn ko nii fi iya jẹ le lori, amojukuro yii jẹ sise ọla lati ọdọ wọn, igbati oore tabi anfaani ba wa nibẹ.
وَٱلَّذِينَ ٱسۡتَجَابُواْ لِرَبِّهِمۡ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَمۡرُهُمۡ شُورَىٰ بَيۡنَهُمۡ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ 38
Awọn ti wọn jẹpe Ọlọhun wọn; pẹlu sise ohun ti O pa lasẹ ati gbigbe ohun ti o kọ ju silẹ, ti wọn si npe irun ni ojupọnna pipe ati awọn ti o jiroro nibi awọn alamọri eyiti o kan wọn, ti wọn si nna ninu ohun ti a se fun wọn lati wa ojurere Allah.
وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَابَهُمُ ٱلۡبَغۡيُ هُمۡ يَنتَصِرُونَ 39
Ati awọn ti abosi ba kan pe wọn yoo ri aranse niti ifi apọnle fun ẹmin wọn ati imu iyi ba a, ti oluse abosi ko ba jẹ ẹni alamojukuro, ti isaranse yii jẹ ododo, paapaa ti ko ba si anfaani nibi ise amojukuro.
وَجَزَٰٓؤُاْ سَيِّئَةٖ سَيِّئَةٞ مِّثۡلُهَاۖ فَمَنۡ عَفَا وَأَصۡلَحَ فَأَجۡرُهُۥ عَلَى ٱللَّهِۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلظَّٰلِمِينَ 40
Ẹniti o ba gbero lati gba ẹtọ rẹ, eleyi wa fun un, sugbọn ni deedee rẹ ti ko nii si alekun tabi ikọja ẹnu aala, ẹniti o ba si se amojukuro fun ẹniti o ba se aburu si, ti ko si gbamu lori aburu rẹ, ti o si se atunse ti o wa laarin rẹ ati ọmọ iya rẹ, ẹsan rẹ wa ni ọdọ Allah, dajudaju ko nifẹ si alabosi ti o nse abosi awọn eniyan nibi dukia wọn tabi awọn ọmọluwabi wọn bikosepe o korira wọn.
وَلَمَنِ ٱنتَصَرَ بَعۡدَ ظُلۡمِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَا عَلَيۡهِم مِّن سَبِيلٍ 41
Ẹniti o ba se aranse fun ẹmin ara rẹ, ko si igbamun kankan fun iru wọn nitori gbigba ẹtọ wọn.
إِنَّمَا ٱلسَّبِيلُ عَلَى ٱلَّذِينَ يَظۡلِمُونَ ٱلنَّاسَ وَيَبۡغُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 42
Dajudaju igbanimu ati iya wa fun awọn ti o se abosi awọn eniyan, ti wọn si nse isẹ ni ori ilẹ pẹlu awọn ẹsẹ, iya inira nbẹ fun awọn eniyan wọnyi ni ọrun.
وَلَمَن صَبَرَ وَغَفَرَ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمِنۡ عَزۡمِ ٱلۡأُمُورِ 43
Sugbọn ẹniti o ba se suuru lori suta ẹnikẹji rẹ ti o se fun, ti o wa se amojukuro nibẹ, dajudaju suuru yii jẹ ohun ti yoo fa oore fun un ati fun awojọ; eleyi si ni alamọri ti a nifẹsi, ẹnikan ko waa nii se kongẹ rẹ ayaafi ẹniti o nipin ti o tobi.
وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن وَلِيّٖ مِّنۢ بَعۡدِهِۦۗ وَتَرَى ٱلظَّٰلِمِينَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَ يَقُولُونَ هَلۡ إِلَىٰ مَرَدّٖ مِّن سَبِيلٖ 44
Ẹniti Allah ba dagunla si kuro nibi imọna, ti O si i lọla kuro nibi ododo, ko si alatilẹyin kan lẹyin rẹ ti yoo gba ọrọ rẹ fun un, iwọ yoo ri awọn alabosi si ẹmin ara wọn nitori sise keferi ati dida awọn ẹsẹ nigbati wọn ba fi oju kan iya ni ọjọ igbende, wọn yoo maa sọ ni ẹniti o nrankan: njẹ ọna wa fun isẹripada si aye ki a le ronu piwada si ọdọ Allah?
Suuru ati ọpẹ mejeeji ma nse okunfa kongẹ lati roni si awọn amin Allah.
Ipo ijiroro ninu ẹsin alaafia tobi.
Titọ gbigba alabosi mu ni deedee abosi rẹ sugbọn amojukuro loore ju eleyi lọ.