Nigbati idinjusini jẹ okuinfa kan ninu awọn okunfa fifan kalẹ agbere, Ọlọhun ọba Allah pasẹ iranlọwọ fun awọn ti ko tii balaga, O wa sọpe:
وَأَنكِحُواْ ٱلۡأَيَٰمَىٰ مِنكُمۡ وَٱلصَّٰلِحِينَ مِنۡ عِبَادِكُمۡ وَإِمَآئِكُمۡۚ إِن يَكُونُواْ فُقَرَآءَ يُغۡنِهِمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ 32
Ẹ yaa fẹ iyawo fun - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ọkunrin ti wọn ko ni iyawo ati awọn obinrin ti ko lọkọ, ki o si tun fẹ iyawo fun awọn olugbagbọ ododo lọkunrin ninu awọn ẹru yin kunrin ati awọn ẹru yin binrin ti wọn ba jẹ alaini Allah yoo ran wọn lọrọ ninu ọla Rẹ eyiti o gbaaye, arisiki rẹ kii din ku nibi rirọ ẹnikẹni lọrọ, O si nimọ nipa isesi awọn ẹru Rẹ.
Nigbati allah pasẹ fun awọn olugbagbọ ododo wipe ki wọn so yigi fun awọn ọdọ, O tun pasẹ fun ọdọ pe ki o ni amumọra nigbati ko ba ri ẹniti yoo fẹ, O wa sọ wipe:
وَلۡيَسۡتَعۡفِفِ ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغۡنِيَهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَٱلَّذِينَ يَبۡتَغُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِمَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡ فَكَاتِبُوهُمۡ إِنۡ عَلِمۡتُمۡ فِيهِمۡ خَيۡرٗاۖ وَءَاتُوهُم مِّن مَّالِ ٱللَّهِ ٱلَّذِيٓ ءَاتَىٰكُمۡۚ وَلَا تُكۡرِهُواْ فَتَيَٰتِكُمۡ عَلَى ٱلۡبِغَآءِ إِنۡ أَرَدۡنَ تَحَصُّنٗا لِّتَبۡتَغُواْ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَن يُكۡرِههُّنَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ مِنۢ بَعۡدِ إِكۡرَٰهِهِنَّ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 33
Ki o ya ma ni amumọra kuro nibi agbere, awọn ti ko ni agbara lati fẹ iyawo nitori ainiiwọn titi Ọlọhun yoo fi rọwọn lọrọ ninu ọla Rẹ ti o gbaaye, ati awọn ti nwa sise akọsilẹ awọn ọga wọn kuro nibi ẹru lati san owo kiwọn leba ni ominira, awọn ọga wọn gbọdọ gba lọwọ wọn, ti wọn ba mọ wipe wọn ni agbara lati se bẹẹ ati lati se daada ninu ẹsin, wọn si gbọdọ fun wọn ninu dukia Ọlọhun ti O fun wọn pẹlu ki wọn fun wọn ni ipin kan ninu eyiti wọn kọ silẹ fun wọn lati san, ẹ ko si gbọdọ jẹ awọn ẹrubirin yin nipa lori zina niti wiwa owo - gẹgẹ bi Abdullaahi ọmọ Ubayy se se pẹlu ọmọ-ọdọ rẹ meji nigbati wọn beere fun amumọra ati ijina si iwa ibajẹ - lati maa beere ounti o nse pẹlu abẹẹrẹ, ẹnikẹni ti o ba jẹwọn nipa lori rẹ dajudaju Ọlọhun Ọba yoo se aforijin fun wọn lẹyin ijẹninipa, yoo si kẹ wọn; nitori ẹniti wọn jẹ nipa niwọn, ẹsẹ naa si jẹ lori ijẹninipa
وَلَقَدۡ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ ءَايَٰتٖ مُّبَيِّنَٰتٖ وَمَثَلٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِكُمۡ وَمَوۡعِظَةٗ لِّلۡمُتَّقِينَ 34
Paapa a ti sọkalẹ fun yin - ẹyin eniyan - awọn aayah ti o fi oju han ti ko si iruju nibẹ, a si tun sọ apejuwe kalẹ fun yin lati ọdọ ara awọn ti o re kọja siwaju yin ninu awọn olugbagbọ ododo lọkunrin ati awọn keferi, a si sọ isiti kalẹ fun yin ti awọn olupaya Ọlọhun Ọba yoo maa gba isiti naa pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si awọn ounti o kọ.
۞ٱللَّهُ نُورُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ مَثَلُ نُورِهِۦ كَمِشۡكَوٰةٖ فِيهَا مِصۡبَاحٌۖ ٱلۡمِصۡبَاحُ فِي زُجَاجَةٍۖ ٱلزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوۡكَبٞ دُرِّيّٞ يُوقَدُ مِن شَجَرَةٖ مُّبَٰرَكَةٖ زَيۡتُونَةٖ لَّا شَرۡقِيَّةٖ وَلَا غَرۡبِيَّةٖ يَكَادُ زَيۡتُهَا يُضِيٓءُ وَلَوۡ لَمۡ تَمۡسَسۡهُ نَارٞۚ نُّورٌ عَلَىٰ نُورٖۚ يَهۡدِي ٱللَّهُ لِنُورِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَ لِلنَّاسِۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ 35
Allah ni imọlẹ sanmọ ati ilẹ, Oun si ni olutẹni sọna ohun ti nbẹ ninu mejeeji, apejuwe imọlẹ Rẹ ti mimọ nbẹ fun ninu ọkan olugbagbọ ododo da gẹgẹ bi alapa ogiri ti ko ni ferese, ti atupa wa nibẹ, ti atupa naa si wa ninu igo, ti o da gẹgẹ bi igo ti o ngbona, ti o da gẹgẹ bi irawọ ti o ntan imọlẹ gẹgẹ bi ile, ti wọn nko atupa naa lati ibi epo igi ibukun, ohun si ni igi saytun, ti igi naa ko le bo o kuro nibi oorun kankan, ko le sẹlẹ ni aarọ bẹẹni ni irọlẹ, ti epo naa bẹrẹ si ni tan imọlẹ nitori mimọ kanga rẹ, ti inọ ko ba kan an, bawo ni yoo se waa ri nigbati o ba kan an?! Imọlẹ atupa naa lekun lori imọlẹ igo naa gẹgẹ bayi ni ọkan olugbagbọ ododo nigbati imọlẹ itọsọna ba tan si i, Ọlọhun Allah ma nfi ẹniti O ba wu ninu ẹru Rẹ se kongẹ alukuraani, bẹẹni Allah si ma nsalaye awọn nkan ti o ruju pẹlu fifi awọn apejuwe lelẹ, Ọlọhun Allah si jẹ onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un.
فِي بُيُوتٍ أَذِنَ ٱللَّهُ أَن تُرۡفَعَ وَيُذۡكَرَ فِيهَا ٱسۡمُهُۥ يُسَبِّحُ لَهُۥ فِيهَا بِٱلۡغُدُوِّ وَٱلۡأٓصَالِ 36
Wọn ko atupa yii ninu awọn mọsalaasi pẹlu asẹ Allah lori ki odiwọn rẹ le ga ati mimọ rẹ, ti wọn si nranti orukọ Rẹ nibẹ pẹlu pipe irun ati iranti ati irun kiki, ti wọn nki ninu rẹ niti sise oju kokoro si awọn iyọnu Allah ni akọkọ ọsan ati igbẹyin rẹ.
Allah ti o gbọngbọn fulẹ mọ awọn okunfa ijẹ ẹru (pẹlu ogun jija), O si gba awọn okunfa ibọkun ẹru laaye, bẹẹni O tun seni loju kokoro sibẹ.
Bibọpa bọsẹ kuro nibi ijẹru ni ojupọnnna ini akọsilẹ ati riran awọn ẹru lọwọ pẹlu owo ki wọn le bọkun lọrun titi ẹru ko fi nii maa wa ni ipo iyẹpẹrẹ, ti wọn yoo maa fi ibajẹ yẹ lẹnu.
ọkan olugbagbọ ododo niye lori lati ibi imọlẹ adamọ ati imọlẹ itọsọna Ọlọhun Olutọju.
Awọn mọsalaasi jẹ ile Allah lori ilẹ, O gbe kalẹ ki wọn le sin Ọlọhun Ọba nibẹ, o waa di dandan mimu awọn idọti ti o si kura si jinna si i ati eyiti ko see fi oju ri.
Ninu awọn orukọ ti o dara ju ni (imọlẹ), O si ko sinu iroyin imọlẹ Rẹ ti mimọ nbẹ fun.