۞يَٰبَنِيٓ ءَادَمَ خُذُواْ زِينَتَكُمۡ عِندَ كُلِّ مَسۡجِدٖ وَكُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ وَلَا تُسۡرِفُوٓاْۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ 31
Irẹ ọmọ Anọbi Aadamọ, ẹ maa wọ nkan ti yoo bo ihoho yin ati eyiti yoo ko ẹwa ba yin ninu asọ eyiti o mọ nigbati ẹ ba fẹ kirun ati igbati ẹ ba fẹ se irọkirika ile ỌLọhun, ẹ maa jẹ, ẹ maa mu ninu eyiti o mọ ti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ fun yin, ki ẹ si mase kọja ẹnu aala deedee nibi eleyi, ẹ mase kọja ẹnu aala kuro nibi ẹtọ lọsi ibi eewọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nifẹ si awọn olukọja ẹnu aala deedee.
قُلۡ مَنۡ حَرَّمَ زِينَةَ ٱللَّهِ ٱلَّتِيٓ أَخۡرَجَ لِعِبَادِهِۦ وَٱلطَّيِّبَٰتِ مِنَ ٱلرِّزۡقِۚ قُلۡ هِيَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا خَالِصَةٗ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ 32
Sọ - ire ojise - niti ifesi fun awọn ọlọsẹbọ ti wọn nse ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ di eewọ ninu asọ ni tabi nkan mimọ ninu ohun ti a njẹ, ati ohun ti o yatọ si wọn: taani ẹniti o se asọ ni eewọ eyiti o jẹ ọsọ fun yin? Taani o si se leewọ awọn nkan ti o mọ ninu ohun ti a njẹ ati ti a nmu ati ohun ti o yatọ sii ninu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se fun yin, sọ - ire ojise - dajudaju awọn nkan ti o mọ yii jẹ ẹtọ awọn olugbagbọ ododo ninu isẹmin aye, ti ẹlomiran ti otyatọ si wọn ba kun wọn ni ile aye lori rẹ, yoo tun jẹ ẹsa fun wọn ni ọjọ igbende alukiyaamọ, ti keferi ko ni le kun wọn nibẹ; tori wipe Alujannah jẹ eewọ fun awọn keferi, iro awọn alaye yii ni a nse ni wẹlẹwẹlẹ fun awọn ti wọn le gbọọ ye, toripe awọn ni wọn yoo se anfaani pẹlu rẹ.
قُلۡ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ ٱلۡفَوَٰحِشَ مَا ظَهَرَ مِنۡهَا وَمَا بَطَنَ وَٱلۡإِثۡمَ وَٱلۡبَغۡيَ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَأَن تُشۡرِكُواْ بِٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ سُلۡطَٰنٗا وَأَن تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 33
Sọ - ire ojise - fun awọn ọsẹbọ ti wọn nse ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ ni eewọ: dajudaju ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni eewọ fun awọn ẹri Rẹ ni awọn ibajẹ, ohun si ni awọn aburu ẹsẹ eyiti o han ni tabi eyiti i pamọ, O si se awọn ẹsẹ patapata ni eewọ, ikọja ẹnu aala jẹ abosi si awọn eniyan nibi ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn ati ọmọluwabi wọn, O si se leewọ ki ẹ ma mu nkan miran mọ, ohun ti ko si ẹri kankan fun yin lori rẹ, O si se leewọ fun yin ki ẹ maa sọrọ laisi imọ lori rẹ nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn isẹ Rẹ ati ofin Rẹ.
وَلِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٞۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ لَا يَسۡتَأۡخِرُونَ سَاعَةٗ وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ 34
Aala odiwọn isẹmin nbẹ fun awọn eniyan ti wọn lo ẹgbẹrun ọdun lati ọgọrun ọdun nigbati wọn ba lo asiko ti a pebubu fun wọn, wọn ko le fi igba kankan kọja rẹ bi o ti wulẹ ki o kere mọ, wọn ko si le siwaju asiko rẹ.
يَٰبَنِيٓ ءَادَمَ إِمَّا يَأۡتِيَنَّكُمۡ رُسُلٞ مِّنكُمۡ يَقُصُّونَ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِي فَمَنِ ٱتَّقَىٰ وَأَصۡلَحَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 35
Irẹ ọmọ Anọbi Aadamọ ni igba kii gba ti awọn ojisẹ mi ba wa ba yin ninu ijọ yin, ti wọn nka ohun ti mo sọkalẹ fun yin ninu iwe mi, ki ẹ yaa tẹ le wọn, ki ẹ si faramọ nkan ti wọn mu wa, nitori awọn ti wọn ba npaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si nkan ti O kọ, ti wọn si se atunse awọn isẹ wọn, ko si ipaya fun wọn ni ọjọ igbende, wọn ko si ni banujẹ lori ipin ti o bọ mọ wọn lọwọ ni ile aye.
وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَٱسۡتَكۡبَرُواْ عَنۡهَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 36
Sugbọn awọn keferi ti wọn pe awọn amin wa nirọ, ti wọn ko si gbaa gbọ, ti wọn nse igberega lori sise nkan ti awọn ojisẹ wọn mu waa ba wọn, awọn eleyi jẹ ẹni ina, ti wọn yoo ba inọ rẹ, ti wọn yoo si maa bẹ nibẹ lọ gbere.
فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بَِٔايَٰتِهِۦٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ يَنَالُهُمۡ نَصِيبُهُم مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا يَتَوَفَّوۡنَهُمۡ قَالُوٓاْ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا وَشَهِدُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰفِرِينَ 37
Ko si ẹniti o nse abosi to ẹniti o nda adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah nibi fifi orogun ti si tabi ẹdinku tabi sisọ oun ti Ko sọ, tabi ki o pe awọn amin Rẹ ti o gbọngbọ, ti ntọni sọna lọsi ibi ododo ni irọ, awọn ẹniti a royin, ipin ti a kọ silẹ ninu iwe Laohul maahafus yoo maa bẹ fun wọn ninu daada tabi aburu, titi Malaika iku yoo fi waa ba wọn, ati awon oluranlowo re ninu awon Malaaika lati gba ẹmin wọn, wọn yoo maa sọ fun won niti fifi wọn se yẹyẹ: nibo ni awọn ọlọhun ọba ti ẹ nsin yatọ si Allah wa? ! ẹ pe wọn ki wọn le se yin ni anfaani, awọn olusẹbọ yoo maa sọ fun awọn Malaika wipe: wọn ti kuro ni ọdọ wa, awọn ti a lero wipe a nsin, a ko mọ ibi ti wọn bayi, wọn yoo maa fi rinlẹ wipe keferi ni wọn jẹ, sugbọn ifirinlẹ wọn ni asiko yii yoo jẹ awijare le wọn lori, bẹẹ ni ko le se wọn ni anfaani mọ.
Olugbagbọ jẹ ẹniti a pa lasẹ ki o maa pataki awọn ofin Ọlọhun Ọba Allah nibi mimọ bo ihoho ara ati mima se ọsọ ni asiko irun pataki julọ nigbati wọn ba nlọ si masalasi.
Ẹniti o ba tumọ Alukuraani laisi imọ, tabi o se alaye ẹsin laisi imọ, tabi o se idajọ laisi imọ, o ti sọ nipa ỌLọhun Ọba Allah laisi imọ ni eleyi, o si jẹ ninu awọn nkan eewọ ti o tobi.
O wa ninu awọn aayah naa ẹri lori wipe awọn olugbagbọ ododo wọn ko ni paya, wọn ko sin nii banujẹ ni ọjọ igbende, iwariri ati ijaya ko nii bẹ fun wọn, ti o ba bẹ fun wọn, igbẹyin rẹ yoo jẹ ifọkanbalẹ.
Eniyan ti o se abosi ju ni ẹniti o mu ifasẹyin ba erongba Ọlọhun Ọba Allah ni ojupọnna meji; ojupọnna akọkọ ni mimu ibajẹ ba ohun ti o ba ntọka si erongba rẹ, ati ojupọnna mimu roiroi ba ọmọ ẹda eniyan lori wipe ỌLọhun Ọba Allah gbero nkan ti ko gbero.