۞قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ 31
Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun awọn Malaaika: kinni isẹ yin, kinni ohun ti ẹ si ngbero?
قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٖ مُّجۡرِمِينَ 32
Awọn Malaaika sọ ni ẹniti o nfesi fun un, awa jẹ ẹniti Allah gbe dide fun ijọ ẹlẹsẹ, ti wọn nse eyiti o buru ju ninu awọn ẹsẹ.
لِنُرۡسِلَ عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةٗ مِّن طِينٖ 33
Ki a le gbe okuta lati inu amọ ti o yi le wọn lori.
مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُسۡرِفِينَ 34
Ni ohun ti a kọ lọdọ Ọlọhun rẹ - irẹ Ibrahim -, ti wọn gbe dide si awọn olukọja ẹnu aala Allah, ti wọn dogongo nibi sise keferi ati awọn ẹsẹ.
فَأَخۡرَجۡنَا مَن كَانَ فِيهَا مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 35
A si mu awọn olugbagbọ ododo jade ninu awọn ti o wa ni abule ijọ Luuth, ki iya ti o sẹlẹ si awọn ẹlẹsẹ maa ba sẹlẹ si wọn,
فَمَا وَجَدۡنَا فِيهَا غَيۡرَ بَيۡتٖ مِّنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ 36
A ko ri ninu abule wọn ju ile kan ti o jẹ ti awọn olugbafa, awọn ni ara ile Luuth ti ọla nbẹ fun.
وَتَرَكۡنَا فِيهَآ ءَايَةٗ لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ 37
A si fi awọn oripa iya silẹ ni abule ijọ Luuth ti o ntọka si sisẹlẹ iya le wọn lori, ki ẹniti o npaya iya inira eyiti o kan wọn yii le ri ariwoye pẹlu rẹ ti ko fi ni se iru isẹ wọn ki o le la nibẹ.
وَفِي مُوسَىٰٓ إِذۡ أَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ 38
Amin wa ni ara Muusa nigbati agbe e dide si fir'aona pẹlu awọn awijare ti o fi oju han fun ẹniti o nbẹru iya inira.
فَتَوَلَّىٰ بِرُكۡنِهِۦ وَقَالَ سَٰحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٞ 39
Fir'aona sẹri kuro nibi ododo ni ẹniti o nkọja ẹnu aala pẹlu agbara rẹ ati ọmọ ogun rẹ, o wa sọ nipa Musa ti ọla nbẹ fun wipe: o jẹ pidanpidan ti o npidan fun awọn eniyan tabi were ti o nsọ ohun ti ko ni laakaye rẹ.
فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٞ 40
A si gba a mu oun ati awọn ogun rẹ lapapọ, awa ju wọn si inu odo, wọn tẹri wọn si parun ati fir'aona ti mu wa ohun ti o le gba eebu le lori wa gẹgẹ bi irọ ati pipe ara rẹ ni Ọlọhun.
وَفِي عَادٍ إِذۡ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلرِّيحَ ٱلۡعَقِيمَ 41
Amin si tun wa ni ara Haadi tii se ijọ Huudu fun ẹniti o nbẹru iya inira nigbati a gbe atẹgun ti ko le gbe ojo dide, ti ko si le la igi lagan, ti ko si si ibukun nibẹ.
مَا تَذَرُ مِن شَيۡءٍ أَتَتۡ عَلَيۡهِ إِلَّا جَعَلَتۡهُ كَٱلرَّمِيمِ 42
Ko de ara ẹmin tabi dukia tabi ohun ti o yatọ si i ayaafi ki o pa a run, o wa fi gbogbo rẹ silẹ ẹgẹ bi ohun ti o ti gbo, ti o si fanka.
وَفِي ثَمُودَ إِذۡ قِيلَ لَهُمۡ تَمَتَّعُواْ حَتَّىٰ حِينٖ 43
Amin tu wa ni ara samuudu tii se ijọ sọluhun ẹniti ọla nbẹ fun, fun ẹniti o nbẹru iya inira nigbati wọn sọ fun wọn pe: ẹ gbadun isẹmin aye yin siwaju ki asiko titan rẹ too to.
فَعَتَوۡاْ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَهُمۡ يَنظُرُونَ 44
Wọn si se igberaga kuro nibi asẹ Ọlọhun wọn, wọn se motomoto niti giga ara lori igbagbọ ati itẹle, ariwo iya si gba wọn mu, wọn si nwo sisọkalẹ rẹ nitoripe wọn ti jẹ ẹniti wọn se ni adehun iya ni ọjọ mẹta siwaju sisọkalẹ rẹ.
فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مِن قِيَامٖ وَمَا كَانُواْ مُنتَصِرِينَ 45
Wọn ko nikapa lati mu iya ti o sọkalẹ fun wọn kuro, wọn ko si ni agbara ti wọn le fi kọ ọ.
وَقَوۡمَ نُوحٖ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ 46
Paapaa a ti mu iparun ba ijọ Nuha pẹlu itẹri siwaju awọn ti a sọ yii, nitoripe dajudaju wọn ijọ ti o jade kuro nibi itẹle ti Allah, wọn si lẹtọ si iya Rẹ.
وَٱلسَّمَآءَ بَنَيۡنَٰهَا بِأَيۡيْدٖ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ 47
A si mọ sanmọ, a si fi agbara daabobo mimọ rẹ, dajudaju awa ni a mu u fẹ ni gbogbo abala eti rẹ.
وَٱلۡأَرۡضَ فَرَشۡنَٰهَا فَنِعۡمَ ٱلۡمَٰهِدُونَ 48
A se ilẹ ti ohun ti o tẹ pẹrẹsẹ fun awọn ti wọn ngbe ibẹ gẹgẹ bi itẹ fun wọn, awa ti a tẹ mọ pataki nigbati a tẹ fun wọn.
وَمِن كُلِّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَا زَوۡجَيۡنِ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ 49
Gbogbo nkan ni a si da ni iran meji; gẹgẹ bi akọ ati abo ati sanmọ ati ilẹ ati ori ilẹ ati ori omin; ki ẹ le ronu si ijọkan soso Allah eyiti O sẹda gbogbo nkan ni iran meji, ki ẹ si maa ranti agbara Rẹ.
فَفِرُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ مُّبِينٞ 50
Ẹ sẹri kuro nibi iya Allah lọ sibi ẹsan Rẹ pẹlu itẹle tiRẹ ati aiyapa Rẹ, dajudaju Emi jẹ - ẹyin eniyan - olukilọ fun kuro nibi iya Rẹ ni ikilọ ti o fi oju han.
وَلَا تَجۡعَلُواْ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ مُّبِينٞ 51
Ẹ ma se mu olujọsin fun miran yatọ si Allah ti ẹ o maa jọsin fun Un yatọ si, dajudaju emi jẹ olukilọ fun yin ni ikilọ ti o fi oju han kuro nibẹ.
Igbagbọ ni ipo ti o ga ju ninu ẹsin alaafia.
Ki Allah mu iparun ba awọn ijọ ti o purọ jẹ ẹkọ fun awọn eniyan lapapọ.
Ibẹru Allah ma nibukaata si sisa lọsi ọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun pẹlu isẹ rere, ki se sisa kuro ni ọdọ Rẹ.