وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ هُوَ ٱلۡحَقُّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِعِبَادِهِۦ لَخَبِيرُۢ بَصِيرٞ 31
Eyiti a fi ransẹ si ọ - irẹ ojisẹ - ninu tira ohun ni ododo ti ko si iyemeji nibẹ, eyiti Allah sọkalẹ ki o le pe awọn iwe ti o kọja ni ododo, dajudaju Allah jẹ olufun awọn ẹru Rẹ niro ati oluriran, Oun ni o ransẹ imisi si ojisẹ gbogbo ijọ, nkan ti wọn ba nfẹ ni asiko ti wọn.
ثُمَّ أَوۡرَثۡنَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلَّذِينَ ٱصۡطَفَيۡنَا مِنۡ عِبَادِنَاۖ فَمِنۡهُمۡ ظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ وَمِنۡهُم مُّقۡتَصِدٞ وَمِنۡهُمۡ سَابِقُۢ بِٱلۡخَيۡرَٰتِ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَضۡلُ ٱلۡكَبِيرُ 32
Lẹyin naa a fun ijọ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, awọn ti a sa lẹsa lori awọn ijọ naa ni Alukuraani, o wa ninu wọn ẹniti o se abosi si ẹmin ara rẹ pẹlu sise awọn nkan eewọ ati gbigbe awọn ọranyan ju silẹ, o si wa ninu wọn ẹniti o wa ni iwọntuwọnsi nibi sise awọn ọranyan ati gbigbe awọn nkan eewọ ju silẹ pẹlu gbigbe apakan ohun ti a fẹ ju si lẹ ati sise apakan nkan ti a korira, o si wa ninu wọn ẹniti o ma ngbawaju nibi rere pẹlu iyọnda Allah eleyi jẹ pẹlu sise ọranyan ati ohun ti a fẹ ati gbigbe awọn eewọ ati ohun ti a korira ju silẹ, eleyi ti a sọ yii - ninu ohun ti a sa lẹsa fun ijọ naa ati fifun wọn Alukuraani - ohun ni ọla ti o tobi eyiti ọla kankan ko sun mọ ọ.
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَلُؤۡلُؤٗاۖ وَلِبَاسُهُمۡ فِيهَا حَرِيرٞ 33
Awọn ọgba idẹra jẹ ibudurosi ti awọn eniyan ti a se afọmọ wọn yoo wọ, wọn yoo maa wọ asọ wura ati awọn nkan ọrun lati ibi goolu, bẹẹni asọ wọn ninu yoo si jẹ ariirii.
وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَذۡهَبَ عَنَّا ٱلۡحَزَنَۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٞ شَكُورٌ 34
Wọn yoo wa maa sọ lẹyin igbati wọn ba wọ inu ọgba idẹra naa: ọpẹ ni fun Allah eyiti o mu ibanujẹ kuro fun wa nitori ohun ti a npaya rẹ lati ma wọ ina, dajudaju Ọlọhun Ọba wa jẹ oluforijin awọn ẹsẹ fun ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, olumọriri ni O si jẹ fun wọn lori itẹle asẹ wọn.
ٱلَّذِيٓ أَحَلَّنَا دَارَ ٱلۡمُقَامَةِ مِن فَضۡلِهِۦ لَا يَمَسُّنَا فِيهَا نَصَبٞ وَلَا يَمَسُّنَا فِيهَا لُغُوبٞ 35
Ẹniti O sọ wa kalẹ si ile ibuduro - eyiti ko si igberapa kuro nibẹ lẹyin rẹ - ninu ọla Rẹ, kii se ete lati ọdọ Wa, bẹẹni kii se agbara, rirẹ ko nii sẹlẹ si wa nibẹ tabi inira.
Nigbati Allah sọ ẹsan awọn ẹniti afọmọ ninu awọn ẹru Rẹ, O tun sọ ẹsan awọn ẹniilẹ ninu wọn awọn naa ni keferi, O wa sọpe:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقۡضَىٰ عَلَيۡهِمۡ فَيَمُوتُواْ وَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُم مِّنۡ عَذَابِهَاۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي كُلَّ كَفُورٖ 36
Awọn ti o se keferi si Allah, ina jahannamọ nbẹ fun ti wọn yoo maa wa nibẹ gbere, wọn ko nii dajọ iku fun wọn debi wipe wọn yoo ku, ti wọn yoo fi sinmi kuro nibi iya, wọn ko si ni fuyẹ ina jahannamọ kankan fun wọn, iru ẹsan yii ni a o san ni ọjọ igbende fun gbogbo oluja idẹkun Ọlọhun Ọba rẹ niyan.
وَهُمۡ يَصۡطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا نَعۡمَلۡ صَٰلِحًا غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ أَوَ لَمۡ نُعَمِّرۡكُم مَّا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَن تَذَكَّرَ وَجَآءَكُمُ ٱلنَّذِيرُۖ فَذُوقُواْ فَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٍ 37
Wọn yoo maa pariwo nibẹ pẹlu ohun ti o ga tan yanyan, wọn yoo maa wa iranlọwọ ni ẹniti o nsọ wipe: Ọlọhun wa mu wa jade kuro ninu ina ki a sisẹ rere eyiti o yatọ si ohun ti a se ni ile aye ki a le ri iyọnu Rẹ, ki a si le la kuro nibi iya Rẹ, Allah yoo wa maa da wọn lohun: se a ko ọjọ ori ti ẹ fi le sẹmin lati ranti ninu rẹ ẹniti o ba gbero lati ranti fun yin ni, ki o le sẹri lọ si ọdọ Allah, ki o si sisẹ rere, ojisẹ naa si wa ba yin ni olukilọ fun yin kuro nibi iya Allah?! Ko si ẹri fun yin, bẹẹni ko si awijare lẹyin gbogbo eleyi, ẹ yaa ma tọ iya ina wo, ko si alaranse fun awọn ti o se abosi fun ẹmin ara wọn lati ibi keferi ati awọn ẹsẹ dida, ti yoo wa la wọn kuro nibi iya Allah tabi se ni fifuyẹ fun wọn.
إِنَّ ٱللَّهَ عَٰلِمُ غَيۡبِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 38
Dajudaju Allah jẹ onimimọ ohun ti o pamọ si gbogbo sanmọ ati ilẹ, nkankan ko bọ mọ lọwọ ninu rẹ, dajudaju o jẹ onimimọ ohun ti awọn ẹru Rẹ fi pamọ ninu igbaaya wọn ni rere tabi aburu.
Ọla ti o nbẹ fun ijọ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lori gbogbo ijọ.
Titayọ igbagbọ awọn olugbagbọ ododo tumọ si titayọ ipo wọn ni ile aye ati lọrun.
Asiko jẹ gbafipamọ ti sisọ rẹ di dandan, ẹniti o ba ra a lare, yoo kabamọ nigbati abamọ ko nii se anfaani.
Kikari imọ Allah si gbogbo nkan.