۞وَمَن يَقۡنُتۡ مِنكُنَّ لِلَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا نُّؤۡتِهَآ أَجۡرَهَا مَرَّتَيۡنِ وَأَعۡتَدۡنَا لَهَا رِزۡقٗا كَرِيمٗا 31
Ẹniti o ba kabamọ lori itẹle asẹ Allah ati ojisẹ Rẹ ninu yin, ti o si nsisẹẹre ti o le yọ Allah ninu, a o fun ni ẹsan adipele ti o yatọ si i ninu ẹgbẹlẹgbẹ awọn obinrin, A o si tun pese fun un lọrun ẹsan ti o lapọnle, ohun si ni alujanna.
يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ لَسۡتُنَّ كَأَحَدٖ مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِنِ ٱتَّقَيۡتُنَّۚ فَلَا تَخۡضَعۡنَ بِٱلۡقَوۡلِ فَيَطۡمَعَ ٱلَّذِي فِي قَلۡبِهِۦ مَرَضٞ وَقُلۡنَ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا 32
Ẹyin obinrin anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ninu ọla ati iyi ẹ kii se apejuwe awọn obinrin yoku bikosepe ẹyin jẹ ẹniti ẹnikankan ninu awọn obinrin ko le de ipo rẹ ninu ọla ati iyi ti ẹ nba ntẹle awọn asẹ Allah, ti ẹ si njinna si awọn nkan ti O kọ, ẹ ko gbọdọ lẹ ohun yin, bẹẹni ẹ ko gbọdọ se ohun yin ni wẹẹrẹ nigbati ẹ ba nsọrọ pẹlu awọn ajoji ninu awọn obinrin ki ẹniti aarẹ sọbẹ selu ati ojukokoro ti o jẹ eewọ nbẹ lọkan rẹ maba rankan si yin nitori eleyi, ki ẹ si maa sọ gbolohun ti o jinna si iyemeji, sugbọn ki o jẹ ọrọ gidi, ki o si maa jẹ awada ni ondinwọn ohun ti a fẹ.
وَقَرۡنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجۡنَ تَبَرُّجَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ ٱلۡأُولَىٰۖ وَأَقِمۡنَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتِينَ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِعۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُذۡهِبَ عَنكُمُ ٱلرِّجۡسَ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِ وَيُطَهِّرَكُمۡ تَطۡهِيرٗا 33
ki ẹ maa fidi mọ inu ile yin, ẹ ko si gbọdọ jade laini idi, ẹ ko si gbọdọ fi ibi ti ẹ dara si han eyiti ẹ ma nse siwaju Islam ninu awọn obinrin nigbati ẹ ma nse afihan rẹ lati le fa ọkan awọn ọkunrin, ki ẹ si maa ki irun ni ojupọnna pipe, bẹẹni ki ẹ maa yọ saka ninu owo yin, ki ẹ si maa tẹle Allah ati ojisẹ Rẹ, dajudaju ohun ti Allah ti mimọ nbẹ fun gbero ni ki O le mu suta ati aburu kuro fun yin, ẹyin iyawo ojisẹ Allah ati ẹyin ara ile rẹ, o si ngbero lati fọ ẹmin yin mọ; pẹlu sise lọsọ awọn iwa ọla ati bibọ kuro nibi awọn eeri rẹ niti mimọ pipe, ti ko nii si eeri kankan lẹyin rẹ.
وَٱذۡكُرۡنَ مَا يُتۡلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ وَٱلۡحِكۡمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا 34
Ki ẹ si tun maa ranti ohun ti wọn ka fun yin ninu ile yin ninu awọn amin Allah eyiti a sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ ati ikọse ojisẹ Rẹ ti o mọ, dajudaju Allah jẹ alaanu si yin nitori fifi yin si inu ile anọbi ti O fi se idẹkun fun yin, O si jẹ oniro fun yin nitori sisa yin lẹsa gẹgẹ bi awọn iyawo fun ojisẹ Rẹ, O si tun sa yin lẹsa ni iya fun awọn olugbagbọ ododo ninu awọn ijọ rẹ.
إِنَّ ٱلۡمُسۡلِمِينَ وَٱلۡمُسۡلِمَٰتِ وَٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡقَٰنِتَٰتِ وَٱلصَّٰدِقِينَ وَٱلصَّٰدِقَٰتِ وَٱلصَّٰبِرِينَ وَٱلصَّٰبِرَٰتِ وَٱلۡخَٰشِعِينَ وَٱلۡخَٰشِعَٰتِ وَٱلۡمُتَصَدِّقِينَ وَٱلۡمُتَصَدِّقَٰتِ وَٱلصَّٰٓئِمِينَ وَٱلصَّٰٓئِمَٰتِ وَٱلۡحَٰفِظِينَ فُرُوجَهُمۡ وَٱلۡحَٰفِظَٰتِ وَٱلذَّٰكِرِينَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا وَٱلذَّٰكِرَٰتِ أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمٗا 35
Dajudaju awọn ti wọn yẹpẹrẹ ara wọn fun Allah pẹlu titẹle asẹ ati awọn oluyẹpẹrẹ ara wọn lobinrin, ati olupe Allah lododo lọkunrin ati olusododo lobinrin, ati awọn olutẹle asẹ lọkunrin ati awọn olutẹle asẹ Allah lobinrin, ati awọn sootọ sootọ lọkunrin ati sootọ sootọ lobinrin nibi igbagbọ wọn ati ọrọ wọn, ati awọn onisuuru lọkunrin ati awọn onisuuru lobinrin lori awọn itẹle asẹ ati kikuro nibi awọn ẹsẹ ati lori awọn idaamun, ati awọn tọrẹ tọrẹ lọkunrin ati awọn tọrẹ tọrẹ lobinrin pẹlu awọn dukia wọn nibi ọranyan ati asegbọrẹ, ati awọn gbaawẹ gbaawẹ lọkunrin ati awọn gbaawẹ gbaawẹ lobinrin fun Allah nibi ọranyan ati asegbọrẹ, ati awọn olusọ abẹ wọn lọkunrin ati awọn olusọ abẹ wọn lobinrin pẹlu biboo lasiri ki o ma baa si niwaju ẹniti ko lẹtọ ki o wo o ati jijina si ibajẹ agbere ati awọn nkan itẹsiwaju rẹ, ati awọn oluranti Ọlọhun Ọba lọkunrin ati awọn oluranti Ọlọhun Ọba lobinrin pẹlu ọkan wọn ati ahọn wọn ni iranti ti o pọ, ni kọkọ ati gbangba - Allah pese aforijin lori ẹsẹ wọn fun wọn, O si pese ẹsan ti o tobi ni ọjọ igbende fun wọn, ohun si ni ọgba idẹra.
Ninu awọn itọsọna Alukuraani fun obinrin musulumi: kikọ funi kuro nibi dindin ohun ati pipasẹ wiwa ninu ile ayaafi pẹlu idi ati kikọ kuro nibi ijade ijakuja.
Ọla ti nbẹ fun awọn ara ile ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, bẹẹni awọn iyawo rẹ naa wa ninu awọn ara ile rẹ.
Ipilẹ didọgba laarin awọn ọkunrin ati awọn obinrin nbẹ nibi isẹ ati ẹsan ayaafi eyiti ofin ẹsin ba dayanri fun ikini keji wọn.