وَلَمَّا جَآءَتۡ رُسُلُنَآ إِبۡرَٰهِيمَ بِٱلۡبُشۡرَىٰ قَالُوٓاْ إِنَّا مُهۡلِكُوٓاْ أَهۡلِ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِۖ إِنَّ أَهۡلَهَا كَانُواْ ظَٰلِمِينَ 31
Nigbati awọn Malaika de, awọn ti a gbe dide lati fun anọbi Ibrahim ati Ishaaq lẹyin naa ni ọmọ rẹ Ya'quub ni iro idunun wọn sọ fun wipe: dajudaju awa jẹ olupa abule saduum run tii se abule ijọ Luuth; dajudaju awọn eniyan bẹ jẹ alabosi nitori isẹ ibajẹ ti wọn nse.
قَالَ إِنَّ فِيهَا لُوطٗاۚ قَالُواْ نَحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَن فِيهَاۖ لَنُنَجِّيَنَّهُۥ وَأَهۡلَهُۥٓ إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ كَانَتۡ مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ 32
Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun awọn Malaika: dajudaju Luuth wa ni abule eyiti ẹ gbero lati pa run yii; ko si si ninu awọn alabosi, awọn Malaika sọpe: awa mọ ẹniti o wa nibẹ, a o la ati ara ile rẹ kuro nibi iparun ti yoo sọkalẹ lori awọn ara abule naa ayaafi iyawo rẹ nikan ni yoo wa ninu awọn ti yoo sẹku fun iparun, a o parun mọ wọn.
وَلَمَّآ أَن جَآءَتۡ رُسُلُنَا لُوطٗا سِيٓءَ بِهِمۡ وَضَاقَ بِهِمۡ ذَرۡعٗاۖ وَقَالُواْ لَا تَخَفۡ وَلَا تَحۡزَنۡ إِنَّا مُنَجُّوكَ وَأَهۡلَكَ إِلَّا ٱمۡرَأَتَكَ كَانَتۡ مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ 33
Nigbati awọn Malaika ti a gbe dide lati pa ijọ Luuth run de ba Luuth, wiwa wọn dun un, o si ba a ninu jẹ niti ipaya lori wọn nibi ibajẹ ijọ rẹ, bayi ni awọn Malaika naa wa ni aworan awọn ọkunrin, bẹẹni awọn ijọ nba awọn ọkunrin lopọ dipo awọn obirin, awọn malaika wa sọ fun pe: ma paya, awọn ijọ rẹ ko le aburu de ọdọ rẹ, masi se banujẹ lori iro ti a fun ọ lati pa wọn run, dajudaju awa yoo la ọ ati awọn ara ile rẹ nibi iparun naa ayaafi iyawo rẹ eyiti yoo wa ninu awọn ẹni iparun, a o paarun mọ wọn.
إِنَّا مُنزِلُونَ عَلَىٰٓ أَهۡلِ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ 34
Dajudaju awa yoo sọ iya kalẹ lati sanmọ lori awọn ara abule eyiti o nse ibajẹ, ohun si ni okuta kan lati inu sijiil; niti iya fun lori kikọja asẹ Allah nipa sise ibajẹ ti o buru, ohun si ni biba ọkunrin lopọ dipo awọn obirin.
وَلَقَد تَّرَكۡنَا مِنۡهَآ ءَايَةَۢ بَيِّنَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 35
Paapaa a ti fi amin ti o fi oju han fun awọn ijọ ti o ni laakaye lelẹ lori ijọ eyiti a pa run yii; toripe awọn ni yoo woye pẹlu awọn amin naa.
وَإِلَىٰ مَدۡيَنَ أَخَاهُمۡ شُعَيۡبٗا فَقَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱرۡجُواْ ٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ 36
A si ran si awọn ara madiyana ọmọ iya wọn ninu ibi tii se Shuaibu ẹniti ọla nbẹ fun; o si sọpe: ẹyin ijọ mi, ẹ sin Allah nikan soso, ki ẹ si maa rankan ẹsan rẹ nibi ijọsin yin ni ọjọ ikẹyin, ẹ mase balẹjẹ pẹlu sise ẹsẹ ati fifan an ka.
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلرَّجۡفَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دَارِهِمۡ جَٰثِمِينَ 37
Awọn ijọ rẹ pe e nirọ, ilẹ mimi si sẹlẹ si wọn, wọn di ẹniti o nsubu niti idoju bolẹ ni ilu ile wọn, ti oju ọju wọn si lẹ mọ yerupẹ ti wọn ko le yira pada.
وَعَادٗا وَثَمُودَاْ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَٰكِنِهِمۡۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَصَدَّهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَكَانُواْ مُسۡتَبۡصِرِينَ 38
Bakanna ni a pa ijọ 'Aadu tii se ijọ Huud run ati samudawa tii se ijọ Sọlihu, paapaa o han si yin - ẹyin ara Mẹka - ni awọn ibugbe wọn pẹlu oripa ẹsẹ ati ẹnu ibode Hadọramaot ti ntọka si iparun yin, ibugbe wọn di ounti o pa lofo, ti o si njẹri lori eleyi, bẹẹ ni esu se isẹ wọn lọsọ fun wọn eyiti wọn wa lori rẹ ninu keferi ati ounti o yatọ si i ninu awọn ẹsẹ, o si mu wọn kuro ni oju ọna ti o duro tọ, wọn di ẹniti o riran pẹlu ododo ati anu ati itọsọna ati isina lati ara ounti awọn ojisẹ wọn fi mọ wọn, sugbọn wọn sa itẹle ifẹ inu lẹsa lori titẹle ọnaamọ.
Gbolohun Rẹ ti O ga julọ: ...وَقَد تَّبَيَّنَ (paapaa o ti hande...) ti o ntọka lori imọ larubawa nipa awọn ibugbe wọn ati iro nipa wọn.
Awọn ibasepọ abara ko le se anfaani ayaafi pẹlu igbagbọ.
Siseni loju kokoro lori ifọkan balẹ awọn alejo ati lila wọn kuro nibi ibawọn sọta.
Aaye awọn ẹni iparun pẹlu iya jẹ ariwoye fun awọn oluwoye.
Ninimọ nipa ododo ko le se anfaani pẹlu titẹle ifẹ inu tabi gbigbe ọla fun un lori imọna.