حُنَفَآءَ لِلَّهِ غَيۡرَ مُشۡرِكِينَ بِهِۦۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَكَأَنَّمَا خَرَّ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَتَخۡطَفُهُ ٱلطَّيۡرُ أَوۡ تَهۡوِي بِهِ ٱلرِّيحُ فِي مَكَانٖ سَحِيقٖ 31
Ẹ jinna si eleyi ni ẹniti yoo yẹ kuro nibi gbogbo ẹsin ti o yatọ si ẹsin Rẹ ti o yọnu si lọdọ Rẹ laini jẹ ẹlẹbọ pẹlu Rẹ nibi ijọsin pẹlu ẹnikẹni, ẹniti o ba sẹbọ pẹlu Allah da gẹgẹ bi ẹniti o jabọ lati sanmọ, ninu ki ẹyẹ jẹ ẹran ati eegun rẹ tabi ki atẹgun ju u si aaye ti o jinna.
ذَٰلِكَۖ وَمَن يُعَظِّمۡ شَعَٰٓئِرَ ٱللَّهِ فَإِنَّهَا مِن تَقۡوَى ٱلۡقُلُوبِ 32
Eleyi ni ohun ti Allah pasẹ rẹ ninu imunilọkan soso ati sise afọmọ fun Un ati jijinna si awọn oosa pẹlu ọrọ eke, ẹnikẹni ti o ba pataki awọn ẹkọ ẹsin - ninu rẹ ni ẹran itanran ati isẹ ijọsin hajj - dajudaju gbigbe titobi Rẹ wa ninu ipaya ọkan si Ọlọhun rẹ.
لَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى ثُمَّ مَحِلُّهَآ إِلَى ٱلۡبَيۡتِ ٱلۡعَتِيقِ 33
Anfaani nbẹ fun yin nibi ẹran itanran eyiti ẹ npa nibi ile Rẹ gẹgẹ bi nkan gigun ati owu ati ọmọ ọmọ ati wara titi di asiko kan pato ti pipa rẹ yoo to nigbati a ba sun mọ ile Allah eyiti o la a kuro nibi ijẹgaba awọn alagbara.
وَلِكُلِّ أُمَّةٖ جَعَلۡنَا مَنسَكٗا لِّيَذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلۡأَنۡعَٰمِۗ فَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَلَهُۥٓ أَسۡلِمُواْۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُخۡبِتِينَ 34
Gbogbo ijọ ti o ti re kọja lọ ni a se ijọsin fun ki o le maa ta ẹjẹ silẹ lati maa se ijọsin lati fi se isunmọ fun Allah; ni ireti ki wọn le ranti orukọ Allah lori ohun ti wọn ba npa ninu awọn nkan isunmọ naa nigbati wọn ba npa a, ki o le jẹ ọpẹ fun Allah lori fifi rakunmi, maalu ati aguntan ran wọn se, ẹni ijọsin fun yin ni tootọ - ẹyin eniyan - jẹ ẹni ijọsin fun kan soso ti ko si orogun fun Un, Oun nikan ni ki ẹ tẹriba fun pẹlu ki ẹ tẹ kọkọrọ ati itẹle asẹ Rẹ, ki o si fun niro - irẹ ojisẹ - awọn olupaya ti wọn si jẹ oluse afọmọ nkan ti yoo dun mọ wọn ninu.
ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَجِلَتۡ قُلُوبُهُمۡ وَٱلصَّٰبِرِينَ عَلَىٰ مَآ أَصَابَهُمۡ وَٱلۡمُقِيمِي ٱلصَّلَوٰةِ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ 35
Awọn ti o ja si wipe ti wọn ba darukọ Allah, wọn yoo paya iya Rẹ, wọn si ta kete lati mase yapa asẹ Rẹ, wọn si ma nse suuru ti adanwo ba kan wọn, wọn si ma nkirun ni pipe, wọn si ma nna ni ojupọnna rere ninu ounti Allah se ni aranse fun wọn.
وَٱلۡبُدۡنَ جَعَلۡنَٰهَا لَكُم مِّن شَعَٰٓئِرِ ٱللَّهِ لَكُمۡ فِيهَا خَيۡرٞۖ فَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا صَوَآفَّۖ فَإِذَا وَجَبَتۡ جُنُوبُهَا فَكُلُواْ مِنۡهَا وَأَطۡعِمُواْ ٱلۡقَانِعَ وَٱلۡمُعۡتَرَّۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرۡنَٰهَا لَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 36
Ati rakunmi ati maalu eyiti wọn fi nse itanran ni ile Allah, a se fun yin ninu awọn oripa ẹsin ati awọn amin rẹ, anfaani ẹsin ati ti ile aye nbẹ fun yin nibẹ, ki ẹ yaa maa sọ wipe: (pẹlu orukọ Allah) nigbati ẹ ba ngun un lẹyin igbati awọn eto rẹ ba ti pe, ti o si duro, ti wọn si to so ọkan ninu ẹsẹ rẹ mejeeji titi ti ko fi ni le tu, nigbati o ba ti fi ẹgbẹ lelẹ lẹyin gigun un pa, ki ẹ yaa jẹ - ẹyin olusetanran - ninu rẹ, ki ẹ si fun alaini ti ko le lamumọra lati beere ati alaini eyiti o le beere ninu rẹ, gẹgẹ bi a se rọ ọ fun yin ki ẹ le maa gbe nkan le lori, ki ẹ si maa gun un, a tun rọ ọ fun yin ni ohun ti o njupa jusẹ silẹ titi de ibi ẹ o ti gun un pa; niti isunmọ Allah, ki ẹ le ba dupẹ fun Allah lori idẹkun ri rọ ọ fun yin.
لَن يَنَالَ ٱللَّهَ لُحُومُهَا وَلَا دِمَآؤُهَا وَلَٰكِن يَنَالُهُ ٱلتَّقۡوَىٰ مِنكُمۡۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرَهَا لَكُمۡ لِتُكَبِّرُواْ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمۡۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 37
Awọn ekiri ẹran ti ẹ ba ti siwaju fun itanran tabi ẹjẹ rẹ ko le de ọdọ Allah ko da ko le goke lọ si ọdọ Rẹ sugbọn ipaya yin si Allah ni yoo goke lọ si ọdọ Rẹ; pẹlu ki ẹ se afọmọ fun Un nibi imusẹ yin ki ẹ le fi sun mọ Ọ, gẹgẹ bẹẹ na a ni Allah rọ fun yin ki ẹ le gbe Allah tobi ni ẹniti o ndupẹ fun Un lori fifi yin se kongẹ ododo, ki o si tun fun niro - irẹ ojisẹ - awọn oluse daadaa nibi ijọsin wọn fun Ọlọhun wọn ati ibalopọ wọn pẹlu ẹda Rẹ nibi ohun ti yoo dun mọ wọn ninu.
۞إِنَّ ٱللَّهَ يُدَٰفِعُ عَنِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ خَوَّانٖ كَفُورٍ 38
Dajudaju Allah ma nmu aburu awọn ọta jinna si awọn ti o nigbagbọ ninu Allah, dajudaju Allah ko nifẹ si onijanba igbafipamọ alaimoore si idẹkun Allah, ti kii dupẹ fun Allah le lori bikosepe o ma nkorira rẹ.
Fifi apejuwe lelẹ lati sun aworan ohun ti o ko le ri mọni nibi fifi we asọ ti a le fi oju ri, o jẹ erongba ikọnilẹkọ ti o tobi.
Ọla ti nbẹ fun itẹriba.
Sise daadaa jẹ okunfa oriire.
Igbagbọ jẹ okunfa fun idaabobo Ọlọhun Allah lori ẹru ati kikiyesi i.