فَلَمَّا سَمِعَتۡ بِمَكۡرِهِنَّ أَرۡسَلَتۡ إِلَيۡهِنَّ وَأَعۡتَدَتۡ لَهُنَّ مُتَّكَٔٗا وَءَاتَتۡ كُلَّ وَٰحِدَةٖ مِّنۡهُنَّ سِكِّينٗا وَقَالَتِ ٱخۡرُجۡ عَلَيۡهِنَّۖ فَلَمَّا رَأَيۡنَهُۥٓ أَكۡبَرۡنَهُۥ وَقَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّ وَقُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا هَٰذَا بَشَرًا إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا مَلَكٞ كَرِيمٞ 31
Nigbati obinrin ọba gbọ ikorira awọn obinrin si i ati ọrọ ẹyin nipa rẹ, o ransẹ si wọn lati pe wọn ki wọn le ri yusuf ki o le fi se awijare fun wọn, o si pese aaye kan fun wọn ti itẹ ati awọn irọri wa nibẹ, o si fun ẹnikọọkan wọn ti o pe ni ọbẹ ti wọn yoo fi maa gbe ounjẹ, o wa sọ fun yusuf ti ọla nbẹ fun: jade si wọn, nigbati wọn ri i, wọn gbe titobi fun un, ara wọn si sẹ giiri nitori didara, wọn si ta giiri pẹlu ẹwa rẹ, wọn fi ọgbẹ si ọwọ ara wọn nitori ijọniloju ti o le pẹlu rẹ lati ibi awọn ọbẹ ti wọn ti pese lati ge ounjẹ, wọn waa sọ wipe: Ọlọhun Ọba fọ mọ, arakunrin yii kii se eniyan, ẹwa ti o nbẹ lara rẹ kii se ohun ti a ba rẹ ni ara ọmọ eniyan, kii se nkankan ju malaika alapọnle lọ ninu awọn malaika alapọnle.
قَالَتۡ فَذَٰلِكُنَّ ٱلَّذِي لُمۡتُنَّنِي فِيهِۖ وَلَقَدۡ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ فَٱسۡتَعۡصَمَۖ وَلَئِن لَّمۡ يَفۡعَلۡ مَآ ءَامُرُهُۥ لَيُسۡجَنَنَّ وَلَيَكُونٗا مِّنَ ٱلصَّٰغِرِينَ 32
Iyawo ọba sọ fun awọn obinrin nigbati o ri ohun ti o sẹlẹ si wọn, eleyi arakunrin ti wọn bumi nitori ifẹ ti mo ni si i, paapaa emi gan ni mo nwa a, mo si da ete lati fa ọkan rẹ sugbọn o kọ, ti ko ba se nkan ti mo nwa lọdọ rẹ laipẹ pupọ yoo wọ ẹwọn, yoo si pada wa ninu awọn ẹni yẹpẹrẹ.
قَالَ رَبِّ ٱلسِّجۡنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِۖ وَإِلَّا تَصۡرِفۡ عَنِّي كَيۡدَهُنَّ أَصۡبُ إِلَيۡهِنَّ وَأَكُن مِّنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ 33
Yuusuf ti ọla nbẹ fun sọ ni ẹniti o npe Ọlọhun ba rẹ: irẹ Ọlọhun Ọba mi, ẹwọn ti o ti ndẹru ba mi yii jẹ ohun ti mo nifẹ si ju nkan ti o npe si lati se ibajẹ lọ, ti o ko ba lami kuro nibi ete awọn obinrin yii maa fi si ọdọ wọn, maa si wa ninu awọn alaimọkan nigbati mo ba fi si ọdọ wọn, bayi ni yoo dun mọ wọn ninu nkan ti wọn nfẹ lọdọ mi.
فَٱسۡتَجَابَ لَهُۥ رَبُّهُۥ فَصَرَفَ عَنۡهُ كَيۡدَهُنَّۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 34
Ọlọhun Allah si gba adua rẹ, O si mu ete obinrin ọba kuro fun un ati ete awọn obinrin yii, dajudaju Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun jẹ olugbọ adua yusuf ati adua gbogbo olupe E, onimimọ pẹlu isesi rẹ ati isesi ẹlomiran.
ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا رَأَوُاْ ٱلۡأٓيَٰتِ لَيَسۡجُنُنَّهُۥ حَتَّىٰ حِينٖ 35
Lẹyin igbayii ohun ti o jẹ irori ọba ati awọn ijọ rẹ nigbati wọn ri ẹri lori mimọ kanga yusuf ni ki wọn o fi si ẹwọn - ki idojuti naa ma ba fan ka - titi ti di asiko ti ẹnikankan ko mọ.
وَدَخَلَ مَعَهُ ٱلسِّجۡنَ فَتَيَانِۖ قَالَ أَحَدُهُمَآ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَعۡصِرُ خَمۡرٗاۖ وَقَالَ ٱلۡأٓخَرُ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَحۡمِلُ فَوۡقَ رَأۡسِي خُبۡزٗا تَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِنۡهُۖ نَبِّئۡنَا بِتَأۡوِيلِهِۦٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 36
Wọn si fi si ẹwọn, awọn okunrin meji si wọn ẹwọn pẹlu rẹ, ọkan ninu awọn okunrin meji naa si sọ fun yusuf: mori loju oorun wipe mo nfun eso inabi ki o le di ọti, ekeji si sọ wipe: emi ri wipe mo ngbe burẹdi si ori ti awọn ẹyẹ njẹ nibẹ, fun wa niro - irẹ Yuusuf - alaye nipa nkan ti a ri, dajudaju a ri ọ ninu awọn oluse daadaa.
قَالَ لَا يَأۡتِيكُمَا طَعَامٞ تُرۡزَقَانِهِۦٓ إِلَّا نَبَّأۡتُكُمَا بِتَأۡوِيلِهِۦ قَبۡلَ أَن يَأۡتِيَكُمَاۚ ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِي رَبِّيٓۚ إِنِّي تَرَكۡتُ مِلَّةَ قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ 37
Yuusuf ẹniti mimọ nbẹ fun sọ wipe: ounjẹ ko ni waa ba yin eyiti wọn mu wa lati ọdọ ọba lati ọdọ ẹlomiran ayaafi ki nse alaye paapaa ati bi o se ri ki wọn to gbe ounjẹ wa ba yin, mejeeji yii jẹ alaye ala eyiti mo mọ lati ibi imọ ti Ọlọhun Ọba fi mọ mi, kii se ti idan, bẹẹ ni kii se ti iworawọ, dajudaju mo ti gbe ẹsin awọn ti ko nigbagbọ ninu Allah ju silẹ, ati awọn ti wọn jẹ keferi si ọrun.
Sise alaye ẹwa yussuf ẹniti ọla nbẹ fun eyiti o jẹ okunfa ti awọn obinrin fi ngba adanwo pẹlu rẹ.
Gbigbe ọla fun ẹwọn Yuusuf lori sisẹ Ọlọhun Ọba Allah.
Ninu eto Ọlọhun Ọba Allah fun Yuusuf ati aanu Rẹ fun un ni fifi itumọ ala mọ ọ, o si se ni okunfa jijade rẹ kuro nibi adanwo ẹwọn.