وَلَوۡ نَشَآءُ لَأَرَيۡنَٰكَهُمۡ فَلَعَرَفۡتَهُم بِسِيمَٰهُمۡۚ وَلَتَعۡرِفَنَّهُمۡ فِي لَحۡنِ ٱلۡقَوۡلِۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ أَعۡمَٰلَكُمۡ 30
Ti a ba fẹ lati fi awọn sọbẹ selu mọ ọ - irẹ ojisẹ - a fi han ọ, iwọ ko ba si mọ wọn pẹlu amin wọn, iwọ yoo si pada mọ wọn pẹlu agbekalẹ ọrọ wọn, Allah mọ awọn isẹ yin, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَلَنَبۡلُوَنَّكُمۡ حَتَّىٰ نَعۡلَمَ ٱلۡمُجَٰهِدِينَ مِنكُمۡ وَٱلصَّٰبِرِينَ وَنَبۡلُوَاْ أَخۡبَارَكُمۡ 31
A o si dan yin wo -ẹyin olugbagbọ ododo- pẹlu igbiyanju ati iba awọn ọta ja ati ipaniyan titi a o fi mọ awọn olugbiyanju si oju ọna Alah ninu yin ati awọn oluse suuru lori iba awọn ọta ja ninu yin, a o dan yin wo ki a le mọ olootọ ninu yin ati onirọ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَشَآقُّواْ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلۡهُدَىٰ لَن يَضُرُّواْ ٱللَّهَ شَيۡٔٗا وَسَيُحۡبِطُ أَعۡمَٰلَهُمۡ 32
Dajudaju awọn ti wọn se keferi si Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si dina mọ ara wọn kuro nibi ẹsin Allah, wọn si tun dina mọ ẹlomiran kuro nibẹ, wọn si yapa ojisẹ Rẹ, wọn ba sọta lẹyin igbati o ti han si wọn wipe anọbi ni - wọn ko le ko inira ba Allah, bikosepe ara wọn ni wọn yoo ko inira ba, Allah yoo si mu ibajẹ ba awọn isẹ wọn.
۞يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُواْ ٱلرَّسُولَ وَلَا تُبۡطِلُوٓاْ أَعۡمَٰلَكُمۡ 33
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse ohun ti wọn se lofin, ẹ tẹle ti Allah ki ẹ si tẹle ti ojisẹ naa pẹlu ki ẹ mu asẹ awọn mejeeji sẹ, ki ẹ si jinna si ohun ti awọn mejeeji kọ, ẹ mase fi keferi sise ati sikarimi ba awọn isẹ yin jẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ مَاتُواْ وَهُمۡ كُفَّارٞ فَلَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡ 34
Dajudaju awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si mu ẹmin ara wọn ati awọn eniyan kuro nibi ẹsin Allah, lẹyin naa wọn si ku lori keferi wọn siwaju ironi piwada - Allah ko nii mojukuro nibi awọn ẹsẹ wọn lati bo asiri rẹ bikosepe yoo gba wọn mu le lori, yoo si fi wọn wọ ina ti wọn yoo maa gbe ibẹ gbere.
فَلَا تَهِنُواْ وَتَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱلسَّلۡمِ وَأَنتُمُ ٱلۡأَعۡلَوۡنَ وَٱللَّهُ مَعَكُمۡ وَلَن يَتِرَكُمۡ أَعۡمَٰلَكُمۡ 35
Ẹ ma sọlẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - lati da oju kọ ọta yin, ki ẹ si pe wọn sibi atunse siwaju ki wọn too pe yin sibẹ, ẹyin ẹ o wa nipo ti ẹ o bori wọn, Allah si wa pẹlu yin nibi aranse Rẹ ati ikunlọwọ Rẹ, ko si nii din ẹsan isẹ yin kankan ku bikosepe yoo lekun idẹkun Rẹ fun yin niti ise ọla.
إِنَّمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا لَعِبٞ وَلَهۡوٞۚ وَإِن تُؤۡمِنُواْ وَتَتَّقُواْ يُؤۡتِكُمۡ أُجُورَكُمۡ وَلَا يَسَۡٔلۡكُمۡ أَمۡوَٰلَكُمۡ 36
Dajudaju isẹmin aye jẹ eremọde ati ere agba, onilaakaye ko nii ri idiwọ kuro nibi isẹ ti ọrun rẹ nibẹ, ti ẹ ba nigbagbọ ninu Allah ati ojisẹ Rẹ, ti ẹ si npaya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti o kọ, yoo fun yin ni ẹsan awọn isẹ yin ni pipe ti koo ni din, ko si ni beere gbogbo dukia yin lọwọ yin bikosepe ohun ti yoo beere lọwọ yin ọranyan afọmọ owo (zaka).
إِن يَسَۡٔلۡكُمُوهَا فَيُحۡفِكُمۡ تَبۡخَلُواْ وَيُخۡرِجۡ أَضۡغَٰنَكُمۡ 37
Ti o ba beere gbogbo dukia yin lọwọ yin, ti o si wo mọ yin nibi gbigba a lọwọ yin, ẹ o se ahun si I, ikorira inawo si oju ọna rẹ ti o wa ninu ọkan yin yoo jade, o wa gbe bibeere rẹ ju silẹ lọwọ yin niti sise pẹlẹ pẹlu yin.
هَٰٓأَنتُمۡ هَٰٓؤُلَآءِ تُدۡعَوۡنَ لِتُنفِقُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَمِنكُم مَّن يَبۡخَلُۖ وَمَن يَبۡخَلۡ فَإِنَّمَا يَبۡخَلُ عَن نَّفۡسِهِۦۚ وَٱللَّهُ ٱلۡغَنِيُّ وَأَنتُمُ ٱلۡفُقَرَآءُۚ وَإِن تَتَوَلَّوۡاْ يَسۡتَبۡدِلۡ قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ ثُمَّ لَا يَكُونُوٓاْ أَمۡثَٰلَكُم 38
Se ẹyin yii ni wọn npe ki ẹ na abala kan ninu awọn dukia yin si oju ọna Allah, ti ko si beere ki ẹ ni gbogbo dukia yin lọwọ yin, o wa ninu yin ẹniti yoo kọ inawo ti wọn nbeere niti ahun lọdọ rẹ, ẹniti o ba si se ahun pẹlu nina abala kan ninu dukia rẹ si oju ọna Allah, dajudaju o se ahun niti isẹlẹ yii fun ẹmin ara rẹ ni; nitori sise leewọ ẹsan inawo fun ara rẹ, Allah si jẹ ọlọrọ ti kii ni bukaata si inawo yin, ẹyin ni alaini si ọdọ Rẹ, ti ẹ ba si sẹri kuro ninu ẹsin alaafia lọsi ibi keferi, yoo mu iparun ba yin, yoo si mu awọn ijọ miran ti o yatọ si yin wa, lẹyin naa wọn ko nii da bi apejuwe yin bikosepe wọn yoo jẹ olutẹle tirẹ.
Asiri awọn sọbẹ selu ati ibajẹ wọn yoo han nibi ti oju wọn ba pin si ati ọna gbaekalẹ ọrọ wọn.
Idanniwo jẹ isesi Ọlọhun lati se adayanri awọn olugbagbọ ododo kuro ninu awọn sọbẹ selu.
Ikunlọwọ Allah fun awọn ẹru Rẹ olugbagbọ ododo pẹlu sise aranse ati didi alafo.
Ninu isepẹlẹ Allah awọn ẹru Rẹ nipe kii wa inawo gbogbo dukia wọn si oju ọna Allah lọdọ wọn.