Nigbati Allah sọ ẹsan awọn ọta Rẹ, O tun sọ ẹsan awọn ẹni Rẹ, O si sọpe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسۡتَقَٰمُواْ تَتَنَزَّلُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَلَّا تَخَافُواْ وَلَا تَحۡزَنُواْ وَأَبۡشِرُواْ بِٱلۡجَنَّةِ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ 30
Dajudaju awọn ti wọn sọpe: Ọlọhun wa, ko si Ọba kan fun yatọ si I, ti wọn si duro sinsin lori mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, awọn Malaaika yoo maa sọkalẹ le wọn lori, wọn yoo si maa sọrọ nigbati wọn ba de fun wọn: ẹ mase bẹru iku bẹẹni ohun ti o wa lẹyin rẹ, ẹ si mase banujẹ lori ohun ti ẹ fi silẹ ni ile aye, ki ẹ maa dunnu pẹlu ọgba idẹra eyiti wọn se ni adehun fun yin ni ile aye lori igbagbọ yin si Allah ati isẹ rere yin.
نَحۡنُ أَوۡلِيَآؤُكُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۖ وَلَكُمۡ فِيهَا مَا تَشۡتَهِيٓ أَنفُسُكُمۡ وَلَكُمۡ فِيهَا مَا تَدَّعُونَ 31
Awa ni ẹni yin ni isẹmin aye, paapaa a ti ndaabobo yin, a si nsọ yin, bẹẹni awa naa ni ẹni yin ni ọrun, ibayinsọrẹ wa yoo maa tẹsiwaju, ohun ti ọkan yin nfa a si ninu awọn nkan itọwo ati awọn adun nbẹ fun yin ni ọgba idẹra naa, gbogbo ohun ti ẹ nbeere fun ninu iohun ti o wu yin si wa fun yin nibẹ.
نُزُلٗا مِّنۡ غَفُورٖ رَّحِيمٖ 32
Aranse ti a ti pese lati fi se alejo yin lati ọdọ Ọlọhun Alaforijin awọn ẹsẹ fun ẹniti o ba sẹri lọ si ọdọ Rẹ ninu awọn ẹru Rẹ, Onikẹ si wọn.
وَمَنۡ أَحۡسَنُ قَوۡلٗا مِّمَّن دَعَآ إِلَى ٱللَّهِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا وَقَالَ إِنَّنِي مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ 33
Ko si ẹnikan ti gbolohun rẹ dara to ẹniti npepe lọ si ibi ọkan soso Allah ati sise ofin Rẹ, ti o si nse isẹẹre ti o yọ Ọlọhun rẹ ninu, ti o wa sọpe: dajudaju emi wa ninu ẹniti o jupa jusẹ, ti o si tẹriba fun Allah, ẹniti o ba se gbogbo eleyi ni eniyan ti gbolohun rẹ dara ju.
وَلَا تَسۡتَوِي ٱلۡحَسَنَةُ وَلَا ٱلسَّيِّئَةُۚ ٱدۡفَعۡ بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ فَإِذَا ٱلَّذِي بَيۡنَكَ وَبَيۡنَهُۥ عَدَٰوَةٞ كَأَنَّهُۥ وَلِيٌّ حَمِيمٞ 34
Isẹ rere ati itẹle asẹ eyiti o yọ Allah ninu ko le dọgba pẹlu awọn isẹ aburu ati awọn ẹsẹ eyiti o bi I ninu, maa fi iwa eyiti o dara sẹsan aburu ẹniti o ba se aburu si ọ ninu awọn eniyan, lojiji ni iwọ yoo ri ẹniti ọta ti gbawaju larin iwọ ati ẹ -nigbati o ba fi daadaa paarọ fun aburu rẹ- gẹgẹ bi alasunmọ alaanu.
وَمَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَمَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ذُو حَظٍّ عَظِيمٖ 35
Ẹnikan ko nii se kongẹ ẹwa ẹyin yii ayaafi awọn ti wọn ba se suuru lori suta naa ati ohun ti wọn nba pade laburu lọdọ awọn eniyan, ẹnikan ko nii se kongẹ rẹ ayaafi onipin ti o tobi; nitori rere ti o pọ ti o wa nibẹ ati anfaani ti o kun.
وَإِمَّا يَنزَغَنَّكَ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ نَزۡغٞ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 36
Ti esu ba ko roiroi ba ọ ni eyikeyi asiko pẹlu aburu, wa Allah ni olusọ ki o si sagọ si ọdọ Rẹ, dajudaju O jẹ olugbọ ohun ti o nsọ, Onimimọ nipa isesi rẹ.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلَّيۡلُ وَٱلنَّهَارُ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُۚ لَا تَسۡجُدُواْ لِلشَّمۡسِ وَلَا لِلۡقَمَرِ وَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ ٱلَّذِي خَلَقَهُنَّ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ 37
Atipe ninu awọn amin Allah ti o tọka si titobi Rẹ ati ijọkan soso Rẹ ni oru ati ọsan jẹ nibi pipaarọ ara wọn ati orun ati osupa, ẹ mase fi ori balẹ fun -ẹyin eniyan- oorun, bẹẹni ẹ mase fi ori balẹ fun osupa, ki ẹ fi ori balẹ fun Allah nikan soso ti ẹ ba jẹ ẹniti o nsin In lododo.
فَإِنِ ٱسۡتَكۡبَرُواْ فَٱلَّذِينَ عِندَ رَبِّكَ يُسَبِّحُونَ لَهُۥ بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَهُمۡ لَا يَسَۡٔمُونَ۩ 38
Ti wọn ba se igberaga, ti wọn si gunri, ti wọn ko si fi ori balẹ fun Allah Asẹda, awọn Malaaika ti wọn wa ni ọdọ Allah nse afọmọ fun Un, ti wọn si ndupẹ fun mimọ Rẹ loru ati lọsan papọ, wọn ko nii kosusu nibi ijọsin Rẹ.
Ipo idurosinsin ni ọdọ Allah tobi.
Apọnle Allah fun awọn ẹru Rẹolugbagbọ ododo ati lila ọrọ wọn bọrun ati ọrọ awọn ti o fi wọn role.
Ipo ipepe si ọdọ Allah atipe dajudaju o jẹ isẹ ti o lọla ju.
Sise suuru lori suta ati fifi daadaa paarọ jẹ iwa meji ti olupepe si ọdọ Allah ko gbọdọ rọrọ kuro nibẹ.