وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّي جَاعِلٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ خَلِيفَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَجۡعَلُ فِيهَا مَن يُفۡسِدُ فِيهَا وَيَسۡفِكُ ٱلدِّمَآءَ وَنَحۡنُ نُسَبِّحُ بِحَمۡدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَۖ قَالَ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 30
Allah nfunni niro wipe Oun ẹniti mimọ nbẹ fun sọ fun awọn Malaaika: Oun yoo da abara si ori ilẹ, ti apakan yoo ma role apakan, kiwọn le ma dari rẹ lori titẹle asẹ Allah, awọn Malaaika bi Ọlọhun Ọba wọn - ibeere itọnisọna ati agbọye - nipa idi ti o fi se awọn ọmọ Adamọ ni arole lori ilẹ, ti o si jẹpe wọn yoo se ibajẹ nibẹ, wọn yoo si ma ta ẹjẹ silẹ niti abosi, ni ẹniti nsọpe: ti awa si ntẹle asẹ rẹ, a nse afọmọ rẹ ni ẹniti ndupẹ fun Ọ, ati ni ẹniti nse titobi gbigbọnngbọn rẹ ati pipe rẹ, a o ni jawọ nibẹ, Allah dawọn lohun ibeere wọn: Emi mọ nkan ti ẹyin ko mọ nipa idi pataki nibi dida wọn, ati erongba ti o tobi nibi fifiwọn role.
وَعَلَّمَ ءَادَمَ ٱلۡأَسۡمَآءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمۡ عَلَى ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ فَقَالَ أَنۢبُِٔونِي بِأَسۡمَآءِ هَٰٓؤُلَآءِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 31
lati salaye ipo Anọbi Aadam (As) , Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga) fi mo Adam orukọ gbogbo nkan patapata, bii ẹranko, nkan ọbọrọgidi, ati nkan ti o yato siyen, awọn gbolohun wọn ati awọn itumọ wọn, lẹyin igba naa, O sẹri awọn orukọ naa si awọn Malaika, ni ẹni ti nsọ pe: ẹ fun Mi ni iro awọn orukọ wọn ti o ba jẹ wipe olododo ni yin nibi ohun tiẹ nsọ wipe dajudaju ẹ ni apọnle ju ẹda yii lọ, ti ẹ si tun ni ọla ju lọ.
قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ لَا عِلۡمَ لَنَآ إِلَّا مَا عَلَّمۡتَنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ 32
Wọn sọ wipe - ni ẹni ti njẹwọ adikun wọn, ti wọn si nsẹri ọla si ọdọ Ọlọhun Allah- : A o maa fọ Ọ mọ, A o si maa gbe titobi fun wọn Irẹ olutọju wa, kuro nibi gbogbo ohun ti wọn nsẹri rẹ waa ba Ọ, nibi idajọ Rẹ ati ofin Rẹ, awa a ko mọ nkankan ayaafi ohun ti O ba rọ wa ni ọrọ imọ rẹ, dajudaju Iwọ ni onimimọ ti nkankan ko pamọ fun, Ọjọgbọn eyi ti o ma ngbe gbogbo alamọri ọrọ si aaye rẹ, lati ibi akọsilẹ Rẹ ati ofin Rẹ.
قَالَ يَٰٓـَٔادَمُ أَنۢبِئۡهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡۖ فَلَمَّآ أَنۢبَأَهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ غَيۡبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَأَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ 33
Nigbanaa ni Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga) sọ fun Adam: Fun wọn ni iro orukọ gbogbo awọn nkan ti A sọ orukọ rẹ, nigbati o wa fun wọn ni iro gẹgẹ bi Ọlọhun Allah ti fi mọ ọ, Ọlọhun Allah waa sọ fun awọn Malaaika: kii wa se wipe mo sọ fun yin: Dajudaju Emi mọ ohun ti o pamọ ninu sanmọ mejeeje ati ilẹ, mo si mọ eyi ti ẹ se afihan rẹ ninu isesi yin, ati eyiti ẹyin gangan nsọ jade.
وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ وَٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 34
Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga) salaye pe Oun pasẹ fun awọn Malaaika wipe ki wọn fi ori balẹ fun Adam, iforikanlẹ pipataki ati apọnle, wọn fi ori balẹ ni ẹni ti o yara gaga, ni itẹle asẹ Ọlọhun Allah, ayaafi ohun ti nbẹ pẹlu esu eyi ti o wa ninu Alijanu, o si taku ni ẹni ti o gunri si asẹ Ọlọhun Allah, lori iforikanlẹ ati ise igberaga si Adam, o wa tibẹ di keferi si Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga julọ) .
وَقُلۡنَا يَٰٓـَٔادَمُ ٱسۡكُنۡ أَنتَ وَزَوۡجُكَ ٱلۡجَنَّةَ وَكُلَا مِنۡهَا رَغَدًا حَيۡثُ شِئۡتُمَا وَلَا تَقۡرَبَا هَٰذِهِ ٱلشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 35
A sọ pe: Irẹ Adam, Irẹ maa gbe ati iyawo rẹ - Hawau - ninu Alijannah, ki ẹyin mejeeji si maa jẹ ninu rẹ pẹlu ifọkanbalẹ ti o gbaaye, ti ko nii si idari nibẹ ni ayekaaye ninu Alijannah sugbọn ẹ sọra fun igi yii, eyiti Mo kọ fun yin ki ẹ ma jẹ nibẹ, ki ẹ ma baa wa ninu awọn alabosi pẹlu wipe ẹ yapa asẹ ti Mo pa yin.
فَأَزَلَّهُمَا ٱلشَّيۡطَٰنُ عَنۡهَا فَأَخۡرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِۖ وَقُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ وَلَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُسۡتَقَرّٞ وَمَتَٰعٌ إِلَىٰ حِينٖ 36
Esu ko yẹ ko gbo ni ẹniti nko royiroyi ba awọn mejeeji, o si see lọsọ titi ti o fi ki awọn mejeeji bọ inu ikọsẹ ati asise pẹlu jijẹ nibi igi eyiti Ọlọhun Allah kọ fun wọn nibẹ, ẹsan wọn naa ni ki Ọlọhun Allah mu wọn kuro ninu Alijannah eyiti wọn ti wa tẹlẹ, Ọlọhun Allah waa sọ fun awọn mejeeji ati shaytan: ẹ sọkalẹ si ori ilẹ, apakan yin jẹ ọta fun apakan, idurosinsin nbẹ fun yin lori ilẹ naa ati isẹku ati igbadun pẹlu awọn daadaa ti nbẹ titi ti asiko yin yoo fi tan, ti alukiyaamọ yoo si to.
فَتَلَقَّىٰٓ ءَادَمُ مِن رَّبِّهِۦ كَلِمَٰتٖ فَتَابَ عَلَيۡهِۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ 37
Anọbi Adam waa gba ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ ju si ninu awọn gbolohun, O si fi mima bẹẹ mọ ọ pẹlu awọn gbolohun naa, ohun ni nkan ti wọn darukọ nibi gbolohun Ọlọhun Allah (ti ọla Rẹ ga julọ) : (قَالَا رَبَّنَا ظَلَمۡنَآ أَنفُسَنَا وَإِن لَّمۡ تَغۡفِرۡ لَنَا وَتَرۡحَمۡنَا لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ) “Awọn mejeeji sọpe: Ọlọhun Ọba wa, A se abosi fun ẹmi wa, ti O ko ba fi ori jin wa, ki O si kẹ wa, dajudaju ao wa ninu awọn ẹni ofo” Al-‘araf : 23. Ọlọhun Allah gba isẹripada rẹ, O si fi ori jin In, toripe Oun, Ọba mimọ ni olugba isẹripada ti o pọ fun awọn ẹru Rẹ, Oun si ni olukẹ wọn.
Ohun ti o jẹ ọranyan fun Muumini nigbati ọgbọn ti Ọlọhun Ọba fẹ fayọ nibi apakan ẹda Rẹ ati asẹ Rẹ ba pamọ, ohun ni ki wọn jupa jusẹ silẹ fun Ọlọhun Allah nibi idẹda Rẹ ati asẹ Rẹ.
Alukuraani Alapọnle se agbega fun ipo imọ, o si se ni okunfa igbọla fun ẹda ni aarin ara wọn.
Igbaraga ni olori awọn ẹsẹ, ohun si ni ipilẹ gbogbo aluba ti o ma nsọkalẹ lori ẹda, ohun si ni akọkọ ẹsẹ ti wọn kọkọ sẹ Ọlọhun Allah.