حُرِّمَتۡ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةُ وَٱلدَّمُ وَلَحۡمُ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦ وَٱلۡمُنۡخَنِقَةُ وَٱلۡمَوۡقُوذَةُ وَٱلۡمُتَرَدِّيَةُ وَٱلنَّطِيحَةُ وَمَآ أَكَلَ ٱلسَّبُعُ إِلَّا مَا ذَكَّيۡتُمۡ وَمَا ذُبِحَ عَلَى ٱلنُّصُبِ وَأَن تَسۡتَقۡسِمُواْ بِٱلۡأَزۡلَٰمِۚ ذَٰلِكُمۡ فِسۡقٌۗ ٱلۡيَوۡمَ يَئِسَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن دِينِكُمۡ فَلَا تَخۡشَوۡهُمۡ وَٱخۡشَوۡنِۚ ٱلۡيَوۡمَ أَكۡمَلۡتُ لَكُمۡ دِينَكُمۡ وَأَتۡمَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ نِعۡمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ ٱلۡإِسۡلَٰمَ دِينٗاۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ فِي مَخۡمَصَةٍ غَيۡرَ مُتَجَانِفٖ لِّإِثۡمٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 3
Ọlọhun Ọba Allah se nii eewọ fun yin eyiti o ba ku laidu lọrun, O si se ẹjẹ ti nda gẹrẹgẹrẹ ni eewọ fun yin, ati ẹran ẹlẹdẹ, ati eyiti wọn ba darukọ ohun ti kii se Ọlọhun Ọba Allah ni igba didu rẹ, ati eyiti o ku lati ara fifun lọrun pa, ati eyiti o ku ti wọn lu pa, ati eyiti o jabọ lati aaye ti o ga, ati eyiti omiran kan pa, ati eyiti ẹran abija gẹgẹ bi kinihun, ẹfọn ati ikooko dẹdẹ rẹ, ayaafi eyiti ẹ ba ba ni aaye ninu awọn eyiti a darukọ, ti ẹ du lọrun, ẹtọ ni o jẹ fun yin, bẹẹ naa ni wọn se ni eewọ fun yin, nkan ti wọn ba du fun awọn oosa, wọn se leewọ fun yin ki ẹ maa beere fun oun ti wọn ba pin fun yin ni ẹyin pẹlu apopo, oun ni okuta tabi ọfa ti wọn kọọ si ara rẹ (se) tabi (mase) , yoo waa se eyiti wọn ba fayọ fun ninu rẹ, sise awọn nkan eewọ ti a sọ yii jẹ jijade kuro ninu itẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah. Oni yii ni awọn keferi jakan kuro nibi igunri yin kuro ninu Islam, nitori agbara ti wọn ri, ẹ ko gbọdọ paya wọn, Emi nikan soso ni ki ẹ paya, oni yii ni mo pe ẹsin yin fun yin tii ẹsin Islam, Mo si pe idẹkun mi ti o han ati eyiti o pamọ leyin lori, Mo si yan Islam laayo gẹgẹ bi ẹsin fun yin, Mi o nii gba ẹsin miran ti o yatọ sii, ẹniti o ba lugọ nitori sababi ebi lọsi ibi jijẹ okunbete, ti kii se ẹniti o fẹ fi si ibi ẹsẹ, ko si ẹsẹ fun ni ibi eyi, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Oluforijin, Olukẹni.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah sọ nipa awọn nkan ti O se jijẹ rẹ ni eewọ, bẹẹ naa ni O sọ nipa awọn nkan ti O se jijẹ ni ẹtọ, O wa sope:
يَسَۡٔلُونَكَ مَاذَآ أُحِلَّ لَهُمۡۖ قُلۡ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُ وَمَا عَلَّمۡتُم مِّنَ ٱلۡجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ ٱللَّهُۖ فَكُلُواْ مِمَّآ أَمۡسَكۡنَ عَلَيۡكُمۡ وَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهِۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 4
Yoo bi ọ leere - ire ojise - awọn alasunmọ rẹ kinni ohun ti Ọlọhun Ọba wọn se jijẹ rẹ ni ẹtọ fun wọn? ! Sọpe –ire ojise-: Ọlọhun Ọba Allah se ohun ti o da ni ẹtọ ni jijẹ fun wọn, ati jijẹ nkan ti awọn nkan ti a ti kọ lẹkọ ba dẹdẹ rẹ, bi awọn ẹranko eleyin ọgan, gẹgẹ bi awọn aja, ati awọn ẹta, ati awọn ẹranko eleekanan ọgan ẹgẹ bi awọn asa, ti ẹ kọ ni idẹdẹ ninu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se idẹkun le lori ninu imọ ati awọn ẹkọ rẹ, titi ti o fi di wipe ti wọn ba pa lasẹ yoo tẹ le asẹ, ti wọn ba si jagbe mọ, yoo gbọ ijagbe, ẹ maa jẹ ninu ohun ti o ba dẹdẹ rẹ, koda ki baa pa, ki ẹ si darukọ Ọlọhun Ọba Allah nigbati ẹ ba fẹ ran nisẹ, pipaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati kikoraro kuro nibi awọn nkan ti ko fẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ ẹniti o yara ni isiro gbogbo isẹ.
ٱلۡيَوۡمَ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُۖ وَطَعَامُ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ حِلّٞ لَّكُمۡ وَطَعَامُكُمۡ حِلّٞ لَّهُمۡۖ وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ إِذَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِيٓ أَخۡدَانٖۗ وَمَن يَكۡفُرۡ بِٱلۡإِيمَٰنِ فَقَدۡ حَبِطَ عَمَلُهُۥ وَهُوَ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 5
Oni ni Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ fun yin jijẹ gbogbo nkan ti o dun, ati jijẹ awọn nkan ti awọn ti a fun ni tira du, ninu awọn yahuudi ati awọn nasaara, O si tun se ni ẹtọ nkan ti ẹyin naa dun fun wọn, O si tun se lẹtọ fun yin fifẹ awọn ọmọluwabi ti o ni amumọra ninu awọn olugbagbọ ododo lobinrin, ati awọn ọmọluwabi alamumọra ninu awọn ti a fun ni tira siwaju yin gẹgẹ bi yahuudi ati nasaara, nigbati ẹ ba ti fun ni owo ori wọn, ti ẹ si jẹ ẹniti o koraro kuro nibi sise ibajẹ, laise ẹniti o fẹẹ mu ololufẹ kọkọ lati se agbere pẹlu wọn, ẹniti o ba tako ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se lofin fun awọn ẹru Rẹ ninu awọn idajọ, paapaa isẹ rẹ ti bajẹ, nitori sise afẹku majẹmu rẹ tii se igbagbọ, ẹni naa yoo wa ni ọjọ igbende ninu awọn ẹni ofo, nitori wiwọ ina rẹ ti yoo maa bẹ nibẹ lọ lailai.
Sise leewọ nkan ti o ku laidu lọrun, ati ẹjẹ ti o nsan ati ẹran ẹlẹdẹ, ati eyiti wọn darukọ oruka nkan ti kii se Ọlọhun Ọba Allah nigba ti wọn du, ati jijẹ okunbete ti wọn fun lọrun, tabi lilu, tabi ti o jabọ ni oke, tabi kikan, tabi didẹdẹ pẹlu ẹranko igbo, wọn se ayaafi ninu eleyi, eyiti a ba ba ni aaye, ti wọn si du ni didu ti ofin.
Ẹtọ ni gbogbo nkan ti a kọ lẹkọ ba dẹdẹ, ti o ni eyin tabi eekannna.
Sise ni ẹtọ nkan awọn ti a ba fun ni tira ba du, ati sise lẹtọ fifẹ awọn ọmọluwabi ninu awọn olulamumọra obinrin.