وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗ لَّا يَخۡلُقُونَ شَيۡٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ وَلَا يَمۡلِكُونَ لِأَنفُسِهِمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا وَلَا يَمۡلِكُونَ مَوۡتٗا وَلَا حَيَوٰةٗ وَلَا نُشُورٗا 3
Awọn ẹlẹbọ mu nkan ti o yatọ si Allah ti ko le da nkankan ti o kere tabi ti o tobi, bẹẹ ni awọn jẹ ohun ti wọn da, Allah ni O da wọn lati ibi aisi, wọn ko si lagbara lati mu inira kankan kuro fun ara wọn, bẹẹni wọn ko le se ni anfaani, wọn ko si le mu iku ba alaaye tabi mu aaye ba oku, wọn ko nikapa jiji awọn oku dide ninu saare wọn.
Nigbati Allah ran wọn leti imu nkan miran mọ Ọ, O tun wa sọ ipo wọn si iwe Rẹ ati si ojisẹ Rẹ, O wa sọ wipe:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ إِفۡكٌ ٱفۡتَرَىٰهُ وَأَعَانَهُۥ عَلَيۡهِ قَوۡمٌ ءَاخَرُونَۖ فَقَدۡ جَآءُو ظُلۡمٗا وَزُورٗا 4
Awọn ti o se keferi si Allah ati ojisẹ Rẹ si sọ wipe: Alukuraani wo leyi, bikobase irọ ti Muhammad hun jọ, o wa se afiti rẹ niti irọ si ọdọ Allah, ti awọn eniyan miran si kun lọwọ lori irọ rẹ, paapa julọ awọn keferi wọnyi ti parọ gbolohun ibajẹ, Alukuraani jẹ ọrọ Allah ti ko rọrun ki abara eniyan tabi alujannu mu iru rẹ wa.
وَقَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ٱكۡتَتَبَهَا فَهِيَ تُمۡلَىٰ عَلَيۡهِ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلٗا 5
Awọn ti o npe alukuraani nirọ yii si sọ wipe: Alukuraani jẹ ọrọ awọn ẹni akọkọ ati awọn aalọ ibajẹ wọn ti Muhammad waa lọ ji yọ wa, o jẹ ohun ti wọn nka a fun un ni ibẹrẹ ọsan ati igbẹyin rẹ.
قُلۡ أَنزَلَهُ ٱلَّذِي يَعۡلَمُ ٱلسِّرَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا 6
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn opurọ wọnyii: Allah ti O mọ gbogbo ohun ti nbẹ ni sanmọ sọ Alukuraani kalẹ, kii se ahunjọ gẹgẹ bi ẹ se nlero, lẹyin naa o wa sọ ni ẹniti o nse wọn loju kokoro si ironu piwada: dajudaju Allah jẹ alaforijin fun ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ onikẹ si wọn.
وَقَالُواْ مَالِ هَٰذَا ٱلرَّسُولِ يَأۡكُلُ ٱلطَّعَامَ وَيَمۡشِي فِي ٱلۡأَسۡوَاقِ لَوۡلَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مَلَكٞ فَيَكُونَ مَعَهُۥ نَذِيرًا 7
Awọn ẹlẹbọ ti npe Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun nirọ si tun sọ wipe: Anọbi wo ni eleyi ti ẹ nlero wipe ojisẹ lati ọdọ Allah, o njẹun bi ẹniti o yatọ si ninu awọn eniyan naa se njẹun, o si nrin ninu awọn ọja lati wa ijẹ-imu, se ko waa yẹ ki Allah sọ malaika kan kalẹ fun un ti yoo jẹ ẹnikeji rẹ ti yoo maa pe ohun ti o mu wa lododo, ti yoo si maa kun lọwọ.
أَوۡ يُلۡقَىٰٓ إِلَيۡهِ كَنزٌ أَوۡ تَكُونُ لَهُۥ جَنَّةٞ يَأۡكُلُ مِنۡهَاۚ وَقَالَ ٱلظَّٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلٗا مَّسۡحُورًا 8
Abi ki O sọ pẹpẹ ọrọ kalẹ fun un lati sanmọ tabi ki ọgba kan maa bẹ fun ti yoo maa jẹ ninu eso rẹ, ti yoo fi rọrọ kuro nibi mimọ rin wọnu awọn ọja ati lati wa ijẹ-imu, awọn alabosi sọpe: ẹ ko tẹle - ẹyin olugbagbọ ododo - ojisẹ kankan, ẹ kan ntẹle ọkunrin kan ti laakaye rẹ ti bori rẹ lati ibi idan.
ٱنظُرۡ كَيۡفَ ضَرَبُواْ لَكَ ٱلۡأَمۡثَٰلَ فَضَلُّواْ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ سَبِيلٗا 9
Wo - irẹ ojisẹ - ki o le seemọ lara wọn bi wọn se royin rẹ pẹlu awọn iroyin ibajẹ, wọn si sọpe: onidan, wọn tun sọpe: ẹni idan ti mu, wọn tun sọpe: were, wọn ti sọnu lati ibi eleyi kuro nibi ododo, wọn ko nikapa lati tọ oju ọna imọna, wọn ko si nikapa oju ọna lọsi ibi titapa si ododo rẹ tabi ifọkantan rẹ.
تَبَارَكَ ٱلَّذِيٓ إِن شَآءَ جَعَلَ لَكَ خَيۡرٗا مِّن ذَٰلِكَ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ وَيَجۡعَل لَّكَ قُصُورَۢا 10
Titobi Allah ẹniti o jasi pe ti O ba fẹ yoo se daadaa fun ọ nibi ohun ti wọn npe mọ ọ pẹlu ki o se awọn ọgba ti awọn akeremọdo nsan ni awọn abẹ orule rẹ ati awọn igi rẹ, ti iwọ yoo maa jẹ ninu eso rẹ fun ni ile aye, ki o si tun se awọn orule ti iwọ yoo maa gbe inu rẹ niti igbadun fun ọ.
بَلۡ كَذَّبُواْ بِٱلسَّاعَةِۖ وَأَعۡتَدۡنَا لِمَن كَذَّبَ بِٱلسَّاعَةِ سَعِيرًا 11
Ohun ti o jade lẹnu wọn ko wa lati ọdọ wọn lati wa ododo tabi se iwadi awijare bikosepe ohun ti o sẹlẹ nipe wọn jẹ ẹniti o npe ọjọ igbende nirọ, a si pa lese fun awọn ti npe ọjọ igbende nirọ ina ti o tobi, ti jijo rẹ le koko.
Yinyin Ọlọhun Ọba ododo pẹlu isẹda ati anfaani ati ipani ati ijini ati kikagaara awọn oosa kuro nibi eleyi.
Fifi iroyin meji nni aforijin ati ikẹ rinlẹ fun Allah.
Isẹ riran ko pọn dandan ninu ijẹ abara kuro fun ojisẹ.
Itẹriba Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun gẹgẹ bi o se jẹpe o nsẹmin bi awọn eniyan se nsẹmin.