مُّحَمَّدٞ رَّسُولُ ٱللَّهِۚ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ أَشِدَّآءُ عَلَى ٱلۡكُفَّارِ رُحَمَآءُ بَيۡنَهُمۡۖ تَرَىٰهُمۡ رُكَّعٗا سُجَّدٗا يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٗاۖ سِيمَاهُمۡ فِي وُجُوهِهِم مِّنۡ أَثَرِ ٱلسُّجُودِۚ ذَٰلِكَ مَثَلُهُمۡ فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِۚ وَمَثَلُهُمۡ فِي ٱلۡإِنجِيلِ كَزَرۡعٍ أَخۡرَجَ شَطَۡٔهُۥ فََٔازَرَهُۥ فَٱسۡتَغۡلَظَ فَٱسۡتَوَىٰ عَلَىٰ سُوقِهِۦ يُعۡجِبُ ٱلزُّرَّاعَ لِيَغِيظَ بِهِمُ ٱلۡكُفَّارَۗ وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِنۡهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمَۢا 29
Muhammad jẹ ojisẹ Allah ati awọn ẹniirẹ ti wọn wa pẹlu rẹ jẹ ẹniti o le koko mọ awọn keferi olujagun, wọn jẹ onikẹ laarin ara wọn, alaani si ara wọn, onifẹ si ara wọn, iwọ yoo ri wọn irẹ oluworan ni ẹniti o tẹriba, ti o fi ori kanlẹ fun Allah ti mimọ nbẹ fun, ti wọn yoo maa beere lọdọ Allah ki O se aforijin ati ẹsan ti o lapọnle fun awọn niti sise ọla, ki O si yọni si wọn, amin wọn jẹ ohun ti o wa ni iwaju wọn nibi awọn oripa ifori kanlẹ eyiti o han gẹgẹ bi imọna ati amin ati imọlẹ irun ni iwaju wọn, eleyi ni iroyin wọn eyiti wọn fi royin wọn ni inu taoreeta tii se iwe ti O sọkalẹ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun, sugbọn apejuwe wọn ninu injiila tii se iwe ti o sọkalẹ fun Isa ti ọla nbẹ fun ni wipe wọn da gẹgẹ bi irugbin ti o jade ni kekere, ti o pada lagbara, ti o si yi, ti o wa fẹ bo ohun ti o nfun lomin mun, ti agbara rẹ se ijọju fun ẹniti o gbin in ati pipe rẹ nibi ikunlọwọ wọn ati pipe wọn; ki Allah le fi mu ibinu ba awọn keferi nigbati wọn ba ri ninu wọn pẹlu agbara ati idọgba ati pipe, Allah se adehun fun awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se awọn isẹ rere ninu awọn ẹniirẹ aforijin fin ẹsẹ wọn, ti ko nii gba wọn mu le lori ati ẹsan ti o tobi ni ọdọ Rẹ ohun si ọgba idẹra naa.
سورة (MADANIYYAH)
Sise iwosan ahọn ati sise alaye oripa rẹ lori igbagbọ ẹnikọọkan ati awọn iwa awujọ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيِ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ 1
A pe ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ninu Allah, ti wọn si tẹle ofin ti wọn se, ẹ ma gbawaju Allah ati ojisẹ Rẹ nibi ọrọ ati isẹ, ki ẹ paya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ dajudaju Allah jẹ olugbọ awọn ọrọ yin, onimimọ si awọn isẹ yin, nkankan ko bọ mọ lọwọ nibẹ, yoo si san yin lẹsan le lori.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَرۡفَعُوٓاْ أَصۡوَٰتَكُمۡ فَوۡقَ صَوۡتِ ٱلنَّبِيِّ وَلَا تَجۡهَرُواْ لَهُۥ بِٱلۡقَوۡلِ كَجَهۡرِ بَعۡضِكُمۡ لِبَعۡضٍ أَن تَحۡبَطَ أَعۡمَٰلُكُمۡ وَأَنتُمۡ لَا تَشۡعُرُونَ 2
Mo pe ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo ninu Allah, ti wọn si tẹle ohun ti wọn lofin, ẹ wuwa ẹlẹkọ pẹlu ojisẹ Rẹ, ẹ mase gbe ohun yin lori ohun anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun nigbati ẹ ba nba sọrọ, ẹ mase maa pariwo orukọ rẹ soke gẹgẹ bi apakan yin se ma npe apakan bikosepe ki ẹ maa fi ijẹ anọbi ati ijẹ ojisẹ pe e ni ibasọrọ ti o lẹ; niti ipaya ki ẹsan isẹ yin ma baa bajẹ lati ara eleyi, ti ẹ ko si nii fura mọ bibajẹ ẹsan rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَغُضُّونَ أَصۡوَٰتَهُمۡ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱمۡتَحَنَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُمۡ لِلتَّقۡوَىٰۚ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٌ عَظِيمٌ 3
Dajudaju awọn ti wọn nrẹ ohun wọn nilẹ ni ọdọ ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, awọn wọnyi ni Allah ti ro ọkan wọn pọ mọ ipaya Rẹ, o si se afọmọ wọn fun un, aforijin ẹsan wọn nbẹ fun wọn ti ko nii gba wọn mu le lori, ẹsan ti o tobi ni ọjọ igbende naa si wa fun wọn, ohun ni ki Allah fi wọn wọ ọgba idẹra.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِن وَرَآءِ ٱلۡحُجُرَٰتِ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ 4
Dajudaju awọn ti o npe ọ - irẹ ojisẹ - ninu awọn larubawa lẹyin yara awọn iyawo rẹ, ọpọ wọn ko ni laakaye.
Wọn se ikẹ lofin pẹlu olugbagbọ ododo pẹlu keferi olujagun.
Dọgba ati iranra ẹni lọwọ wa ninu awọn iwa ẹni anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Ẹniti o ba ri ikorira ninu ọkan rẹ si awọn ẹni anọbi alapọnle jẹ ẹni ipaya le lori nibi keferi.
Jijẹ dandan wiwu iwa ẹkọ pẹlu ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati pẹlu ikọse rẹ ati pẹlu awọn olujogun rẹ (awọn onimimọ).