وَإِذۡ صَرَفۡنَآ إِلَيۡكَ نَفَرٗا مِّنَ ٱلۡجِنِّ يَسۡتَمِعُونَ ٱلۡقُرۡءَانَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوٓاْ أَنصِتُواْۖ فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوۡاْ إِلَىٰ قَوۡمِهِم مُّنذِرِينَ 29
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati a ran apakan ninu awọn alujannu si ọ, ti wọn ntẹti gbọ Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ, nigbati wọn pesẹ sibi gbigbọ rẹ, apakan wọn sọ fun apakan: ẹ titi ki a le fi ara balẹ gbọ ọ, nigbati ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun pari kika rẹ, ọn sẹri lọ si ọdọ ijọ wọn, ti wọn si nse ikilọ fun wọn kuro nibi iya Allah, ti wọn ko ba nigbagbọ ninu Alukuraani yii.
قَالُواْ يَٰقَوۡمَنَآ إِنَّا سَمِعۡنَا كِتَٰبًا أُنزِلَ مِنۢ بَعۡدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقٖ مُّسۡتَقِيمٖ 30
Wọn sọ fun wọn pe: ẹyin ijọ wa, dajudaju awa gbọ iwe kan ti Allah sọkalẹ lẹyin Musa, ti o npe awọn iwe ti o ti sọkalẹ siwaju rẹ ni ododo ni ọdọ Allah, iwe yii eyiti a ngbọ ma ntọni sibi ododo, o si nfi ni mọ ọna ti o duro tọ, ohun si ni ẹsin alaafia.
يَٰقَوۡمَنَآ أَجِيبُواْ دَاعِيَ ٱللَّهِ وَءَامِنُواْ بِهِۦ يَغۡفِرۡ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُجِرۡكُم مِّنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ 31
Ẹyin ijọ wa, ẹ jẹpe Muhammad lọsi ibi ohun ti o npeyin si lododo, ki ẹ si nigbagbọ wipe ojisẹ ni lati ọdọ Ọlọhun rẹ, Allah yoo fi ori awọn ẹsẹ yin jin yin, yoo si la yin kuro nibi iya inira ti o nreti yin ti ẹ ko ba jẹpe rẹ lọsi ibi ohun ti o npe yin si lododo, ti ẹ ko si nigbagbọ wipe ojisẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ni.
وَمَن لَّا يُجِبۡ دَاعِيَ ٱللَّهِ فَلَيۡسَ بِمُعۡجِزٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَيۡسَ لَهُۥ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءُۚ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ 32
Taani ko jẹpe Muhammed lọsi ibi ohun ti o npe e si ni ododo, sisa lori ilẹ rẹ ko le jẹ ki o bọ mọ Allah lọwọ, ko si ẹlomiran yatọ si Allah ti o le ran an lọwọ kuro nibi iya naa, awọn wọnyi ni wọn wa ni ọna anu kuro nibi ododo ti o fi oju han.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَلَمۡ يَعۡيَ بِخَلۡقِهِنَّ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 33
Se awọn ẹlẹbọ opurọ nipa ọjọ igbende yii ko wa ri ni pe dajudaju Allah ni ẹniti o da gbogbo sanmọ ti O si da ilẹ pẹlu titobi mejeeji ati gbigbaaye rẹ ko mu kagara nibi dida wọn, O jẹ alagbara lati ji awọn oku fun isiro ati ẹsan?! Bẹẹni dajadaju alagbara lo jẹ lati ji wọn, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun lagbara lori gbogbo nkan, ko le kagara nipa tita awọn oku ji.
وَيَوۡمَ يُعۡرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَلَى ٱلنَّارِ أَلَيۡسَ هَٰذَا بِٱلۡحَقِّۖ قَالُواْ بَلَىٰ وَرَبِّنَاۚ قَالَ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ 34
Ọjọ ti wọn yoo sẹri awọn ti o se keferi si Allah ati si ojisẹ Rẹ si inu ina ki wọn le fi iya jẹ wọn, wọn yoo maa sọrọ nibi bibuwọn: se kii se eleyi ni ẹ fi oju yin ri ninu iya ododo?! Tabi o jẹ irọ gẹgẹ bi ẹ se nsọ ni ile aye?! Wọn sọpe: bẹẹni Ọlọhun wa, dajudaju ododo ni, wọn yoo sọ fun wọn pe, ẹ maa tọ iya naa wo nitori keferi yin si Allah.
فَٱصۡبِرۡ كَمَا صَبَرَ أُوْلُواْ ٱلۡعَزۡمِ مِنَ ٱلرُّسُلِ وَلَا تَسۡتَعۡجِل لَّهُمۡۚ كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَ مَا يُوعَدُونَ لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا سَاعَةٗ مِّن نَّهَارِۢۚ بَلَٰغٞۚ فَهَلۡ يُهۡلَكُ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 35
Se suuru - irẹ ojisẹ - lori irọ awọn ijọ rẹ si ọ, gẹgẹ bi awọn onipinnu ẹmin ninu awọn ojisẹ se se suuru: Nuha ati Ibrahim ati Musa ati Isa ki ikẹ ati ọla o maa bẹ fun gbogbo wọn, mase kanju iya fun wọn, o da bi ẹnipe awọn opurọ ninu ijọ rẹ ko pẹ ni ile aye ni ọjọ ti wọn ba ri ohun ti wọn ba se ni adehun fun wọn ninu iya ni ọrun ju wakati kan ninu ọsan lọ nitori gigun iya wọn, Alukuraani ti a sọkalẹ yii fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ imudopin ati ohun ti o to fun ọmọniyan ati alujannu, bi ọrọ se ri nipe, wọn ko nii fi iya pa ẹnikankan run ayaafi awọn ijọ ti o ba jade kuro nibi uitẹle ti Allah pẹlu sise keferi ati awọn ẹsẹ.
Ninu ẹkọ ti o dara ni itẹti si ẹniti o nsọrọ ati didakẹ fun un wa.
Yiyara jẹpe awọn olumọna ninu alujannu lọsi ibi ododo jẹ isẹ riran, iseni loju kokoro si awọn eniyan
Jijẹpe lọsi ibi ododo nibukaata si gbigbawaju ara ẹni nibi ipepe lọsi ibẹ.
Suuru sise jẹ iwa awọn anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun gbogbo wọn.