أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِيٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى وَأَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ 29
Se o ko mọ ni wipe Allah ma ndin ku ninu oru lati se alekun ọsan, O si ma ndin ku ninu oru lati se alekun ọsan, O si se ondinwọn lilọ bibọ osupa; nigbati awọn mejeeji nlọ ni aaye rẹ titi di asiko kan ti A fi aala si, atipe dajudaju Allah jẹ olufiniro ohun ti ẹ nse, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹẹ yin, Yoo si san yin lẹsan le lori.
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ 30
Idari yii ati ipebubu yii, mejeeji njẹri wipe dajudaju Allah nikan ni ododo, Oun paapaa ni ododo, ati iroyin Rẹ ati awọn isẹ Rẹ, atipe dajudaju ohun ti awọn ẹlẹbọ nsin yatọ si I jẹ ibajẹ ti ko ni ipilẹ, atipe dajudaju Allah ni ẹniti o ga ju fun ara Rẹ ati bibori Rẹ ati indiwọn Rẹ lori gbogbo awọn ẹda Rẹ, eyiti ko si ohun ti o ga julọ, eyiti o jẹ Ohun ti o tobi ju gbogbo nkan lọ.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱلۡفُلۡكَ تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِنِعۡمَتِ ٱللَّهِ لِيُرِيَكُم مِّنۡ ءَايَٰتِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ 31
Se o ko ri pe awọn ọkọ oju omin nrin ni ori omin pẹlu aanu Rẹ ati rirọ ọ; ki o le fi han yin -ẹyin eniyan- ninu awọn amin Rẹ ti ntọka si agbara Rẹ ti mimọ nbẹ fun ati aanu Rẹ, dajudaju nibi eleyi jẹ awọn itọka si agbara Rẹ fun gbogbo oluse suuru lori ohun ti o ba kan an ninu inira, oludupẹ fun ohujn ti o tẹ ẹ lọwọ ninu awọn idẹkun.
وَإِذَا غَشِيَهُم مَّوۡجٞ كَٱلظُّلَلِ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمۡ إِلَى ٱلۡبَرِّ فَمِنۡهُم مُّقۡتَصِدٞۚ وَمَا يَجۡحَدُ بَِٔايَٰتِنَآ إِلَّا كُلُّ خَتَّارٖ كَفُورٖ 32
Ti ẹkun omin ba wipo wọn ni gbogbo ẹgbẹ gẹgẹ bi oke ati ẹsujo, wọn yoo pe Allah nikan soso ni ẹniti o nse afọmọ adua ati ijọsin fun Un, ti Allah ba jẹpe wọn, ti O si la wọn de ori ilẹ, ti O si yọ wọn kuro nibi itẹri, yoo maa wa ninu wọn alasesẹku ti ko nii se ohun ti o jẹ ẹranyan fun un ninu ọpẹ dudu ni ojupọnna pipe, yoo si wa ninu wọn oluja idẹkun Allah niyan, ẹnikankan ko nii ja awọn amin Wa niyan ayaafi gbogbo dalẹdalẹ - gẹgẹ bi ẹni yii ti o se adehun pẹlu Allah, ti O ba la ohun, paapaa julọ yoo wa ninu oludupẹ fun Un - o jẹ alaimoore si idẹkun Allah, ti kii dupẹ fun Ọlọhun Ọba rẹ ti o se idẹkun fun un.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡ وَٱخۡشَوۡاْ يَوۡمٗا لَّا يَجۡزِي وَالِدٌ عَن وَلَدِهِۦ وَلَا مَوۡلُودٌ هُوَ جَازٍ عَن وَالِدِهِۦ شَيًۡٔاۚ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ 33
Ẹyin eniyan, ẹ bẹru Ọlọhun Ọba yin; pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si awọn ounti O kọ, ki ẹ si paya iya ọjọ kan ti obi kankan ko nii rọrọ ni ọdọ ọmọ rẹ, bẹẹni ọmọ kankan ko nii se anfaani fun obi rẹ kankan, dajudaju adehun Allah lori sise ẹsan ni ọjọ igbende rinlẹ, yoo si sẹlẹ ti ko si iyemeji nibẹ, ẹ ma jẹ ki isẹmin aye tan yin jẹ pẹlu ounti nbẹ nibẹ ninu awọn adun ati nkan imunigbagbe, ẹ masi jẹ ki esu tan yin jẹ pẹlu suuru Ọlọhun Ọba nse fun yin ati lilọra iya Rẹ fun yin.
إِنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِ وَيُنَزِّلُ ٱلۡغَيۡثَ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلۡأَرۡحَامِۖ وَمَا تَدۡرِي نَفۡسٞ مَّاذَا تَكۡسِبُ غَدٗاۖ وَمَا تَدۡرِي نَفۡسُۢ بِأَيِّ أَرۡضٖ تَمُوتُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرُۢ 34
Dajudaju Allah nikan ni imọ opin igba nbẹ fun Un, O mọ igbati yoo sẹlẹ ati sisọkalẹ ọjọ tigbati o ba fẹ, O si mọ ohun ti o wa ninu apo ibi boya akọ ni tabi abo?! Olori buruku ni tabi oloriire?! ẹmin kankan ko si mọ ohun ti yoo se lọla ninu daadaa tabi aburu, bẹẹni ẹmin kankan ko mọ ori ilẹ ti yoo ku si bikosepe Allah ni o mọ eleyi lapapọ, dajudaju Allah jẹ onimimọ olufunni niro gbogbo eleyi, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi.
Didinku oru ati ọsan ati lilekun mejeeji ati rirọ oorun ati osupa: awọn amin ni o jẹ ti o ntọka si agbara Allah ti mimọ nbẹ fun ati awọn idẹkun ti o lẹtọ si ọpẹ.
Suuru ati ọpẹ jẹ ọna meji lati woye si awọn amin Allah.
Pipaya ọjọ igbende ma nsọni kuro nibi igbatanjẹ aye ati titẹriba fun roiroi awọn esu.
Kikari imọ Allah debi kọkọ lapapọ.