۞فَلَمَّا قَضَىٰ مُوسَى ٱلۡأَجَلَ وَسَارَ بِأَهۡلِهِۦٓ ءَانَسَ مِن جَانِبِ ٱلطُّورِ نَارٗاۖ قَالَ لِأَهۡلِهِ ٱمۡكُثُوٓاْ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا لَّعَلِّيٓ ءَاتِيكُم مِّنۡهَا بِخَبَرٍ أَوۡ جَذۡوَةٖ مِّنَ ٱلنَّارِ لَعَلَّكُمۡ تَصۡطَلُونَ 29
Nigbati Musa pari asiko meji naa tii se ọdun mẹwa, o si lọ pẹlu ara ile rẹ lati madiyana lọsi misirọ, o wa ri ina kan ni abala oke, o wa sọ fun ara ile rẹ, ẹ duro si ibi yii, emi nwo ina, o seese ki nmu iro wa fun yin nibẹ tabi ki nmu egige ina kan wa ti ẹ o fi ko ina; o seese ki ẹ le fi dina otutu.
فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِيَ مِن شَٰطِيِٕ ٱلۡوَادِ ٱلۡأَيۡمَنِ فِي ٱلۡبُقۡعَةِ ٱلۡمُبَٰرَكَةِ مِنَ ٱلشَّجَرَةِ أَن يَٰمُوسَىٰٓ إِنِّيٓ أَنَا ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 30
Nigbati Musa de ibi ina naa eyiti o ri, Ọlọhun Ọba rẹ ti mimọ nbẹ fun pe e lati abala ọgbun ọtun ni aaye naa eyiti Allah fi ibukun si pẹlu biba Musa sọrọ nibi igi naa wipe: irẹ Musa dajudaju Emi ni Allah Ọba olutọju gbogbo ẹda lapapọ.
وَأَنۡ أَلۡقِ عَصَاكَۚ فَلَمَّا رَءَاهَا تَهۡتَزُّ كَأَنَّهَا جَآنّٞ وَلَّىٰ مُدۡبِرٗا وَلَمۡ يُعَقِّبۡۚ يَٰمُوسَىٰٓ أَقۡبِلۡ وَلَا تَخَفۡۖ إِنَّكَ مِنَ ٱلۡأٓمِنِينَ 31
Atipe ki o ju ọpa rẹ silẹ, Musa si ju u silẹ niti titẹle asẹ Ọlọhun Ọba rẹ, nigbati o ri ni ohun ti o yira pada, o si parada gẹgẹ bi ejo nibi yiyara rẹ, o pẹyin da, o nsaalọ niti ipaya rẹ, ko si pada nibi ere sisa rẹ, Ọlọhun Ọba rẹ waa pe e: irẹ Musa, wa, mase paya rẹ; dajudaju o ti wa ninu ẹni ifọkanbalẹ kuro nibẹ ati ohun ti o yatọ si i ninu ohun ti o le maa bẹru.
ٱسۡلُكۡ يَدَكَ فِي جَيۡبِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٖ وَٱضۡمُمۡ إِلَيۡكَ جَنَاحَكَ مِنَ ٱلرَّهۡبِۖ فَذَٰنِكَ بُرۡهَٰنَانِ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦٓۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ 32
Ki ọwọ rẹ ọtun bọ alafo inu asẹ rẹ nibi ti o sun ọrun, yoo jade ni fifun ni eyiti kii se ẹtẹ, Musa si kii bọọ, o wa jade gẹgẹ bi yiyin, ka ọwọ rẹ ko ki ipaya rẹ le balẹ, bayi ni Musa ka a ko, ipaya si kuro fun un, awọn nkan meji ti a darukọ yii -ọpa ati ọwọ- jẹ awijare meji ti a raẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ si fir'aona ati awọn ẹni iyi ninu ijọ rẹ, dajudaju wọn jẹ ijọ ti o ti jade kuro nibi itẹle asẹ Allah nitori sise keferi ati dida awọn ẹsẹ.
قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلۡتُ مِنۡهُمۡ نَفۡسٗا فَأَخَافُ أَن يَقۡتُلُونِ 33
Musa sọ ni ẹniti o nse itẹgun lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ: dajudaju emi ti pa ẹmi kan ninu wọn, mo wa npaya ki wọn o ma pa mi ti mo ba lọ ba wọn lati fun wọn niro ohun ti wọn fi ran mi nisẹ.
وَأَخِي هَٰرُونُ هُوَ أَفۡصَحُ مِنِّي لِسَانٗا فَأَرۡسِلۡهُ مَعِيَ رِدۡءٗا يُصَدِّقُنِيٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ 34
Ọmọ iya mi haruna si dantọ ju mi lọ lọrọ, gbe dide pẹlu mi ni oluranlọwọ, ki o maa kun mi lọwọ nibi ọrọ mi, ti fir'aona ati awọn ijọ rẹ ba pe mi nirọ, emi npaya ki wọn o ma pe mi nirọ gẹgẹ bi o se jẹ isesi awọn ijọ ti wọn ba gbe ojisẹ dide si siwaju temi, ti wọn si pe wọn nirọ.
قَالَ سَنَشُدُّ عَضُدَكَ بِأَخِيكَ وَنَجۡعَلُ لَكُمَا سُلۡطَٰنٗا فَلَا يَصِلُونَ إِلَيۡكُمَا بَِٔايَٰتِنَآۚ أَنتُمَا وَمَنِ ٱتَّبَعَكُمَا ٱلۡغَٰلِبُونَ 35
Ọlọhun Allah fesi niti dida ipepe Musa lohun: a o ro ọ lagbara - irẹ Musa - pẹlu gbigbe ọmọ iya rẹ dide pẹlu rẹ ni ojisẹ olukunlọwọ, a o si se awijare fun yin ati ikunlọwọ, aburu ti ẹ korira kankan ko nii ba yin nitori awọn amin wa eyiti a fi ran yin nisẹ, ẹyin mejeeji ati awọn ti o ba tẹle e ninu awọn olugbagbọ ododo ni ẹniti a o ran se.
Pipe adehun jẹ isesi awọn olugbagbọ ododo.
Biba ti Ọlọhun Ọba ba Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọrọ rinlẹ lori ododo.
Nini bukaata olupepe si ọdọ Ọlọhun Ọba nibi olukun un lọwọ.
Pataki didantọ fun awọn olupepe.